Akure Kidnap: Wo àwòràn ohun tó ṣẹlẹ̀ nílé ìjọsìn Sotitọbiire tí wọ́n sun ní àná

Aworan ohun ti o seku niyii nile ijosin Sotitobirẹ niluu Akurẹ lẹyin ti awọn ọdọ kan yabo ile ijọsin naa l'Ọjọru látàrí ìròyìn pé wọn ri òkú Gold tó dàwátì níbẹ̀.

akure
Àkọlé àwòrán, Wo ọkan lara awọn ọkọ ti wọn dana sun lana ni Akurẹ
akure
Àkọlé àwòrán, Ariwo aje o, ni awọn kan n pa lataari awọn ọkọ to jona ni Oṣhinle
akure
Àkọlé àwòrán, Googoo go ni awọn ara adugbo ti ijọ Sotito bi ire wa lati ana ti iṣẹlẹ yii ti ṣẹlẹ
akure
Àkọlé àwòrán, Onikaluku lo n kọ Ha lori bi iṣẹlẹ naa ṣe yiwọ ni ana
akure
Àkọlé àwòrán, Gbogbo nkan ini adugbo pọ to fara gba ninu iṣẹlẹ yii, koda o kan opo ina
akure
Àkọlé àwòrán, Awọn ile keekeeke ti wọn kọ lẹgbẹ rẹ gan an ni ina ko yọ silẹ, nitori ko kuku mọ oju ẹni to da ina funra rẹ
akure
Àkọlé àwòrán, Ori pẹpẹ ti ahesọ naa ti wa pe wọn ti ri oku ọmọkunrin Gold Kolawole naa ni yi
akure
Àkọlé àwòrán, Bi tẹnikan kò bajẹ, tẹnikan ko le daa ni ọrọ iṣẹlẹ ina naa ja si lana ni Akurẹ
akure
Àkọlé àwòrán, Ko sẹni to le so boya awọn ọmọ ijọ niyii tabi ero iworan ti akọroyin BBC ba ninu ijọ Ṣotitọbiirẹ ni Akurẹ laarọ oni
akure
Àkọlé àwòrán, Ori pẹpẹ ti wọn sọ pe wọn ti ri oku Gold Kolawole ni yii ninu ijọ Sotitobiire Miracle Center ni Akurẹ, Bẹẹ ọga ọlọpaa ni irọ nla ni
akure
Àkọlé àwòrán, Opọ eniyan ni ẹnu ya lori bi ọrọ ṣe de bayii nitori pe wọn ti wa lẹnu ọrọ Gold Kolawole to dawati ni ijọ yii lati oṣu kọkanla.
akure
Àkọlé àwòrán, Tonile talejo lo wa fun oju lounjẹ lẹyin iṣẹlẹ ana ti Oga ọlọpaa Joseph Femi ti ni ẹmi ọlọpaa kan lọ sii fun BBC ti awọn miran ni ara ilu meji ba iṣẹlẹ naa rin
akure
Àkọlé àwòrán, Awọn ero ti ko sẹni to da ọmọ ijọ yatọ naa wa n wo ajoku ijọ Ṣotitọ biirẹ niluu Akure to jẹ olu ilu Ondo
akure
Àkọlé àwòrán, Ọkọ awọn ọlopaa kan ree lara awọn ọkọ ti wọn dana sun lanaa nitosi ijọ Sotito bii re ni Akurẹ
akure
Àkọlé àwòrán, Nibi ti gbogbo iṣẹlẹ yii ti bẹrẹ nipa pe ọmọde naa di awati ree ninu ijọ Sotitobiirẹ ni eyi ti awọn aṣọna mẹrinla ati oluranlọwọ pasitọ nilati lọ bura laafin Deji ti Akurẹ
akure
Àkọlé àwòrán, Awọn ọkọ ẹlomii ti wọn gbe sita ile atawọn miran ti wọn rin sasiko lasiko naa fara gba iṣẹlẹ naa ti ọpọ owo jona sii nipasẹ ohun ini
akure
Àkọlé àwòrán, Ẹnu ọna ijọ Sotitọbiire ree ti wọn tun n gba wọle lọ jọsin tabi lọ fi ọmọ si ile ẹkọ awọn ọmọde lasiko ijọsin.
akure
Àkọlé àwòrán, Ọpọ ero ree to wa woran lẹyin ti wọn ni wọn sọ ina sibi nipasẹ iroyin to ja ranyinranyin wi pe wọn ri oku ọmọ ọdun kan ti o sọnu ni abẹ pẹpẹ ile ijọsin naa.