Coronavirus: Àwọn alárùn coronavirus ṣe ìwọ́de ní Gombe, wọ́n ní ìjọba n febi pa wọ́n

Awọn olufẹhonu han

Oríṣun àwòrán, Twitter

Nṣe ni awọn alarun coronavirus tu si ita ọkan lara awọn ibudo ti wọn ti n tọju aarun naa nipinlẹ Gombe lati fi ẹhonu han lọjọ Iṣẹgun.

Wọn fi ẹsun kan awọn alaṣẹ pe wọn kofun awọn ni oogun tabi itọju, ati pe ounjẹ paapa ko si ka'nu.

Sugbọn sa, kọmisana eto ilera nipinlẹ naa, Ahmed Gana sọ fun BBC pe awọn eeyan naa ko fi apẹẹrẹ aarun naa han ni wọn ko ṣe nilo oogun.

Bakan naa ni awọn alaṣẹ sọ pe ko si nkan to jọ pe awọn ko fun wọn ni ounjẹ daada.

Wọn pada bẹ awọn eeyan naa lati pada si ibudo naa, ṣugbọn wọn sọ pe ẹru n ba wọn nitori bi awọn alarun naa ṣe darapọ mọ awọn ara abule to jade wa a woran ohun to n ṣẹlẹ.

Awọn olufẹhonu han

Oríṣun àwòrán, Twitter

Ijọba Gombe sọ pe aimọkan lo mu ki awọn eeyan naa ṣe iwọde. Wọn si rọawọn to ba jade wa a woran iwọde naa lati ya ara wọn si ọtọ fun ọjọ

mẹrinla.

Àkọlé fídíò, Àǹfàní ńlá ni àṣẹ ìgbélé jẹ́ fún àyíká ọmọnìyàn pàápàá nílùú Eko

Eeyan bi ọgọrun lo ni aarun naa lọwọlọwọ ni Gombe.

Ọwọ́ tẹ báàlẹ̀, Ṣinkó mẹ́tàdínlógún tó ń jí kùsà wà ní ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun

Awọ awọn agbofinro ti tẹ awọn ọmọ orilẹede China mẹtadinlogun kan ti wọn n ji kusa wa ni ipinlẹ Ọṣun

Ikọ alaabo ajumọṣe ti ijọba ipinlẹ Osun ṣẹṣẹ da silẹ lo he awọn eeyan naa lagbegbe Ileṣa ati Ifẹ ni ipinlẹ Ọṣun.

Bakan naa lọwọ awọn agbofin ikọ naa tun tẹ awọn mẹwaa miran pẹluu wọn ti wọn jẹ ọmọ agbegbe naa.ati baalẹ agbegbe ọhun.

Ọgbẹni Abdullahi Binuyọ to jẹ igbakeji adari awọn oṣiṣẹ lọfiisi gomina ipinlẹ Ọṣun ṣalaye pe ko si ijọba ti yoo kawọgbera maa woran nigba ti awọn eeyan kan yoo maa ba ọrs ajumọni rẹ jẹ tabi jii ko.

O fi kun pe awọn ajikusa wa naa ti ba odo ọṣun jẹ pẹlu oniruru awọn eroja to jẹ majele fun agọ ara.

Awọn afunrasi naa lasiko ti awọn agbofinro n fi oju wọn han

Oríṣun àwòrán, osun state government

O ni yat s si pe wọn yoo foju wina ofin, awọn ti wọn mu naa yoo tun san owo gba maa binu fun ijọba.

Ọkan lara awọn ọmọ orilẹede China naa to le sọ ede Oyinbo ṣalaye pe nitoun, oun ko mọ pe wọn n ji kusa wa ni nitori pe ireti oun ni pe wọn ni iwe aṣẹ iwakusa latọdọ ijọba.

Osun Coronavirus: Coronavirus ti gbẹ̀mí èèyàn mìí ní ìpínlẹ̀ Osun

Adegboyega oyetola

Oríṣun àwòrán, Adegboyega oyetola

Eeyan kan ti jẹ Ọlọrun nipe nitori arun Coronavirus ni ipinlẹ Osun, nigba ti ẹni to kọkọ ni arun ọhun ati awọn oṣiṣẹ eto ilera mẹta mii ri iwosan gba.

Kọmiṣọnna eto ilera ni ipinlẹ naa, Rafiu Isamotu sọ pe oloogbe ọhun to jẹ ọmọ aadọrin ọdun din diẹ gbẹmi mi ni ile iwosan ijọba Asubiaro, ni ilu Osogbo.

Isamotu ni ijọba gba esi ayẹwo ẹni akọkọ naa ati awọn oṣiṣẹ eto ilera to ri iwosan lalẹ ọjọ Ẹti.

O ni ilu London ni ẹni akọkọ to ni arun ọhun ni Osun ti wa, ṣugbọn ara rẹ ti da ṣaka bayii lẹyin to lo ọjọ mejidinlogoji nibi to ti gba itọju.

Lọwọ yi, eeyan mẹjọ ni àrùn Covid-19 n ba fínra ni Osun.

Àkọlé fídíò, Ẹ máà fi Eko wé Ghana lórí dídẹ okùn ìgbélé, ìyàtọ̀ wà níbẹ̀-Hamzat, igbákejì gómìnà Eko

Ìjọba Osun dẹkùn lọrun àṣẹ konile ó gbélé

Koko ohun mẹ́wàá tí Gomina Oyetola báwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ Osun sọ

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Osun tí dẹkùn àṣẹ konile ó gbé lé ọlọsẹ méjì ni ọrùn àwọn èèyàn jákèjádò Ìpínlẹ̀ náà.

Ìjọba Ìpínlẹ̀ Osun ṣàlàyé pé, àwọn aráàlú yóò ní anfaani lati rin yíká ìpínlẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́fà àárọ̀ si marun irọlẹ, láti ọjọ́ Ajé sì Ọjọ́bọ ọsọọsẹ.

Nígbà tó ń ṣàlàyé ìdí tí ìjọba Ìpínlẹ̀ Osun fi gbé ìgbésẹ náà, gomina Adegboyega Oyetola, nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ náà sọ ṣàlàyé pé, didẹ okun lọrun àṣẹ konile ó gbélé náà yóò mú kó rọrùn fáwọn

aráàlú láti máa ṣíṣẹ oojọ wọn.

Oyetola fikùn pé àṣẹ ọhun, tí yóò bẹ̀rẹ̀ lọ́jọ́ Ajé ọjọ́ kẹrin oṣù karùn-ún, ní yóò tún mú kó rọrùn fún ìjọba láti darí Ìpínlẹ̀ náà bọ ṣe yẹ.

Àmọ́ ó ní kó ni sì lílọ bibọ ọkọ àti èrò láti ìpínlẹ̀ kan si òmíràn lásìkò yii, tí wọn yóò sì gbé àwọn ẹnu bode ìpínlẹ̀ Osun tí pá.

Gomina Ìpínlẹ̀ Osun, Adegboyega Oyetola bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ náà sọ̀rọ̀ ni irọlẹ Ọjọ́bọ.

Àkànṣe eto naa si lọ dá lórí igbele àrùn Covid-19 àti akoso Ìpínlẹ̀ Osun.

Kókó mẹ́wàá tó sì jẹyọ rèé nínú ọ̀rọ̀ tó bá àwọn èèyàn Ìpínlẹ̀ ọ̀hún sọ.

  • Alẹ́ ọjọ́ Aiku ni òfin konile ó gbélé to wá nilẹ yóò wa sopin
  • Láti ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹrin oṣù karùn-ún, ìjọba yóò dẹkùn lọrun àṣẹ konile ó gbélé, tí àwọn aráàlú yóò sì ní anfaani lati rin láàárín ìlú bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́fà àárọ̀ si márùn-ún irọlẹ.
  • Láàárín ọjọ́ Ajé sì Ọjọ́bọ si ni àwọn èèyàn ní anfaani lati lọ si ẹnu isẹ Ajé wọn, tí ìjọba náà yóò sì leè ṣíṣẹ ìlú.
  • Òfin to de ìpéjọpọ̀ sì wá síbẹ̀. Kò sí gbọdọ si ìpéjọpọ̀ ọpọ èrò ni àwọn ilé ìjọsìn gbogbo, tàbí nílé ìwé, agbo òṣèlú àti níbi kibi.
  • Bákan náà, Oyetola ni gbogbo àwọn ọjà si lọ gbọ́dọ̀ wà ní títì pa.
  • Àwọn ibùdó itaja si lo gbọ́dọ̀ pèsè ọ̀sẹ̀ ifọwọ àti omi fáwọn onibara wọn
  • Ibùdó itaja ìgbàlódé taa mọ si Supermarket, kò gbọ́dọ̀ ni ju èèyàn mẹ́wàá lọ ní ẹẹkannaa
  • Gbogbo ààlà ibodè Ìpínlẹ̀ Osun pẹlu awọn Ìpínlẹ̀ tó mule tíì ní yóò sì wà ní títì pá, tí kò sì ní si lílọ bibọ ọkọ àti èrò àyàfi àwọn ọkọ akẹru tó ń kó oogun, oúnjẹ, èròjà epo rọbi àti ohun ọ̀gbìn nìkan ni yóò rí
  • Àwọn ọlọkọ èrò yóò leè ṣíṣẹ ni aarin ìgboro láti ọjọ́ Ajé si Ọjọ́bọ ni ọsọọṣẹ, bẹ̀rẹ̀ láti aago mẹ́fà àárọ̀ si márùn-ún irọlẹ, tí wọ́n ko si gbọdọ gbé ju èrò méjì si ìlà ijoko kọ̀ọ̀kan lọ nínú ọkọ wọn.
  • Gomina Oyetola wa kadi ọ̀rọ̀ rẹ nilẹ pé ọlọkada kan kò gbọ́dọ̀ gbé ju èrò kan ṣoṣo lọ, tí àwọn onikẹkẹ Maruwa kò sì gbọ́dọ̀ gbé ju èrò méjì lọ sí ẹyin ọkọ wọn nígbà tí kò gbọ́dọ̀ sì èrò kankan ní ijoko iwájú.
Coronavirus
Coronavirus

NCDC covid 19 updates (Breakout): Ìjọba àpapọ̀ ní kò tíì sí ọjọ́ fún ìwọlé àwọn akẹ́kọ̀ọ́

Awọn akẹkọọ fasiti kan

Oríṣun àwòrán, Unilag

A o le sọ igba ti awọn ileeẹkọ yoo wọle pada ni Naijiria-Ijọba

A ko ti le sọ igba tawọn ileeẹkọ yoo wọle.

Minisista abẹle feto ẹkọ ni Naijiria, Emeka Nwajiuba, lo sọ ọrọ yi lasiko to n bawọn akọroyin sọrọ nibi ti igbimọ aarẹ to n dari eto gbogbo nipa Covid-19 n jabọ farailu.

O ni toun ti pe aarẹ ni wọn yoo dẹwọ ofin konile o gbele ni Abuja,Eko ati ipiinlẹ Ogun,ileesẹ eto Eko ko ti le sọ ọjọ ti awọn ileeẹkọ yoo bẹrẹ pada jakejado Naijiria.

Ninu ọrọ rẹ, o ni ''aarẹ kuku sọ nipa dida eto ọrọ aje pada diẹ diẹ.Bi a ko ba yanju eyiun naa, a ko le sọ pato ọjọ ti eto ẹkọ yoo gberasọ pada.O gbọdọ wa ni ibamu pẹlu eto to wa nilẹ yi ni.A ko fẹ fi awọn ọmọ wa sinu ewu''

O fi kun pe ''ko si ile ẹkọ kankan to le da isẹ se laifi ti oun sẹlẹ lawujọ se''

Aworan atọnisọna

Iye awọn to ti ni arun naa lagbaye

Group 4

Jọwọ ṣe atunṣe ilana ikansi ayelujara rẹ lati ri ẹkunrẹrẹ rẹ

Orisun: Johns Hopkins University atawọn ajọ eto ilera ilu

Igba ti wọn kede iṣiro awọn to nii kẹyin 5 Oṣù Agẹmọ 2022 10:59 WAT+3

Ẹkunrẹrẹ data

Sun atẹ wa silẹ tabi oke lati ri ẹkunrẹrẹ akọsilẹ

*Iye awọn to tọwọ aisan ku ni isọri eeyan ẹgbẹrun lọna ọgọrun

Orilẹede Amẹrika 1012833 308.6 87030788
Orilẹ́ede Brazil 672033 318.4 32535923
Orilẹede India 525242 38.4 43531650
Orilẹede Russia 373595 258.8 18173480
Orilẹede Mexico 325793 255.4 6093835
Orilẹede Peru 213579 657.0 3640061
Ilu Ọba 177890 266.2 22232377
Orilẹede Italy 168604 279.6 18805756
Orilẹede Indonesia 156758 57.9 6095351
Orilẹede France 146406 218.3 30584880
Orilẹede Iran 141404 170.5 7240564
Orilẹede Germany 141397 170.1 28542484
Orilẹede Colombia 140070 278.3 6175181
Orilẹede Argentina 129109 287.3 9394326
Orilẹede Poland 116435 306.6 6016526
Orilẹede Ukraine 112459 253.4 5040518
Orilẹede Spain 108111 229.6 12818184
Orilẹede South Africa 101812 173.9 3995291
Orilẹede Turkey 99057 118.7 15180444
Orilẹede Romania 65755 339.7 2927187
Orilẹede Phillippines 60602 56.1 3709386
Orilẹede Chile 58617 309.3 4030267
Orilẹede Hungary 46647 477.5 1928125
Orilẹede Vietnam 43088 44.7 10749324
Orilẹede Canada 42001 111.7 3958155
Orilẹede Chech 40324 377.9 3936870
Orilẹede Bugaria 37260 534.1 1174216
Orilẹede Malaysia 35784 112.0 4575809
Orilẹede Ecuador 35745 205.7 913798
Orilẹede Belgium 31952 278.2 4265296
Orilẹede Japan 31328 24.8 9405007
Orilẹede Thailand 30736 44.1 4534017
Orilẹede Pakistan 30403 14.0 1539275
Orilẹede Greece 30327 283.0 3729199
Orilẹede Bangladesh 29174 17.9 1980974
Orilẹede Tunisia 28691 245.3 1052180
Orilẹede Iran 25247 64.2 2359755
Orilẹede Egypt 24723 24.6 515645
Orilẹede South Korea 24576 47.5 18413997
Orilẹede Portugal 24149 235.2 5171236
Orilẹede Netherlands 22383 129.1 8203898
Orilẹede Bolivia 21958 190.7 931955
Orilẹede Slovakia 20147 369.4 2551116
Orilẹede Austria 20068 226.1 4499570
Orilẹede Myanmar 19434 36.0 613659
Orilẹede Sweden 19124 185.9 2519199
Orilẹede Kazakhstan 19018 102.7 1396584
Orilẹede Paraguay 18994 269.6 660841
Orilẹede Guatemala 18616 112.1 921146
Orilẹede Georgia 16841 452.7 1660429
Orilẹede Sri Lanka 16522 75.8 664181
Orilẹede Serbia 16132 232.3 2033180
Orilẹede Morrocco 16120 44.2 1226246
Orilẹede Croatia 16082 395.4 1151523
Orilẹede Bosnia ati Herzegovnia 15807 478.9 379041
Orilẹede China 14633 1.0 2144566
Orilẹede Jordan 14068 139.3 1700526
Orilẹede Switzerland 13833 161.3 3759730
Orilẹede Nepal 11952 41.8 979835
Orilẹede Moldova 11567 435.2 520321
Orilẹede Israel 10984 121.3 4391275
Orilẹede Honduras 10906 111.9 427718
Orilẹede Lebanon 10469 152.7 1116798
Ilẹ Australia 10085 39.8 8291399
Orilẹede Azerbaijan 9717 96.9 793388
North Macedonia 9327 447.7 314501
Orilẹede Saudi Arabia 9211 26.9 797374
Orilẹede Lithuania 9175 329.2 1162184
Orilẹede Armenia 8629 291.7 423417
Orilẹede Cuba 8529 75.3 1106167
Orilẹede Costa Rica 8525 168.9 904934
Orilẹede Panama 8373 197.2 925254
Orilẹede Afganistan 7725 20.3 182793
Orilẹede Ethiopia 7542 6.7 489502
Orilẹede Ireland 7499 151.8 1600614
Orilẹede Uruguay 7331 211.8 957629
Orilẹede Taiwan 7025 29.5 3893643
Orilẹede Belarus 6978 73.7 982867
Orilẹede Algeria 6875 16.0 266173
Orilẹede Slovenia 6655 318.7 1041426
Orilẹede Denmark 6487 111.5 3177491
Orilẹede Libya 6430 94.9 502189
Orilẹede Latvia 5860 306.4 837182
Orilẹede Venezuela 5735 20.1 527074
Agbegbe Palestine 5662 120.8 662490
Orilẹede Kenya 5656 10.8 334551
Orilẹede Zimbabwe 5558 38.0 255726
Orilẹede Sudan 4952 11.6 62696
Orilẹede Finland 4875 88.3 1145610
Orilẹede Oman 4628 93.0 390244
Orilẹede Dominican Republic 4383 40.8 611581
Orilẹede El Salvador 4150 64.3 169646
Orilẹede Namibia 4065 163.0 169247
Orilẹede Trinida and Tobago 4013 287.7 167495
Orilẹede Zambia 4007 22.4 326259
Orilẹede Uganda 3621 8.2 167979
Orilẹede Albania 3502 122.7 282690
Orilẹede Norway 3337 62.4 1448679
Orilẹede Syria 3150 18.5 55934
Orilẹede Naijiria 3144 1.6 257637
Orilẹede Jamaica 3144 106.6 143347
Orilẹede Kosovo 3140 175.0 229841
Orilẹede Cambodia 3056 18.5 136296
Orilẹede Kyrgyzstan 2991 46.3 201101
Orilẹ́ẹede Boswana 2750 119.4 322769
Orilẹede montenegro 2729 438.6 241190
Orilẹede Malawi 2646 14.2 86600
Orilẹede Estonia 2591 195.3 580114
Orilẹede Kuwait 2555 60.7 644451
Orilẹede United Arab Emirates 2319 23.7 952960
Orilẹede Mozambique 2212 7.3 228226
Orilẹede Mongolia 2179 67.6 928981
Orilẹede Yemen 2149 7.4 11832
Orilẹede Senegal 1968 12.1 86382
Orilẹede Cameroon 1931 7.5 120068
Orilẹede Angola 1900 6.0 101320
Orilẹede Uzbekistan 1637 4.9 241196
Orilẹede New Zealand 1534 31.2 1374535
Orilẹede Bahrain 1495 91.1 631562
Orilẹede Rwanda 1460 11.6 131270
Orilẹede Ghana 1452 4.8 166546
Orilẹede Singapore 1419 24.9 1473180
Orilẹede Swaziland 1416 123.3 73148
Orilẹede Madagascar 1401 5.2 65787
Orilẹede Congo 1375 1.6 91393
Orilẹede Suriname 1369 235.5 80864
Orilẹede Somalia 1361 8.8 26803
Orilẹede Guyana 1256 160.5 67657
Orilẹede Luxembourg 1094 176.5 265323
Orilẹede Cyprus 1075 89.7 515596
Orilẹede Mauritius 1004 79.3 231036
Orilẹede Mauritania 984 21.7 60368
Orilẹede Martinique 965 257.0 195912
Orilẹede Guadeloupe 955 238.7 168714
Orilẹede Fiji 866 97.3 65889
Orilẹede Tanzania 841 1.4 35768
Orilẹede Haiti 837 7.4 31677
Erekusu Bahamas 820 210.5 36101
Erekusu Reunion Island 812 91.3 422769
Orilẹede Cote d‘ivoire 805 3.1 83679
Orilẹede Laos 757 10.6 210313
Orilẹede Malta 748 148.8 105407
Orilẹede Mali 737 3.7 31176
Orilẹede Lesotho 699 32.9 33938
Orilẹede Belize 680 174.2 64371
Orilẹede Quatar 679 24.0 385163
Orilẹede Papua New Guinea 662 7.5 44728
Agbegbe French Polynesia 649 232.4 73386
Erekusu Barbados 477 166.2 84919
Orilẹede Guinea 443 3.5 37123
Erekusu Cape Verde 405 73.6 61105
Agbegbe French Guiana 401 137.9 86911
Orilẹede Burkina Faso 387 1.9 21044
Orilẹede Olominira Congo 385 7.2 24128
Erekusu Saint Lucia 383 209.5 27094
Orilẹede Gambia 365 15.5 12002
Orilẹede New Caledonia 313 108.8 64337
Orilẹede Niger 310 1.3 9031
Orilẹede Maldives 306 57.6 182720
Orilẹede Gabon 305 14.0 47939
Orilẹede Liberia 294 6.0 7497
Curaçao 278 176.5 44545
Orilẹede Togo 275 3.4 37482
Orilẹede Nicaragua 242 3.7 14690
Orilẹede Grenada 232 207.1 18376
Orilẹede Brunei 225 51.9 167669
Orilẹede Aruba 222 208.8 41000
Orilẹede Chad 193 1.2 7426
Orilẹede Djibouti 189 19.4 15690
Orilẹede Mayotte 187 70.3 37958
Orilẹede Equatorial Guinea 183 13.5 16114
Orilẹede Iceland 179 49.5 195259
Erekusu Channel 179 103.9 80990
Orilẹede Guinea Bissau 171 8.9 8369
Orilẹede Seychelles 167 171.1 44847
Orilẹede Benin 163 1.4 27216
Orilẹede Comoros 160 18.8 8161
Orilẹede Andorra 153 198.3 44177
Erekusu Solomon Islands 153 22.8 21544
Orilẹede Antigua ati Barmuda 141 145.2 8665
Erekusu Bermuda 140 219.0 16162
Orilẹede South Sudan 138 1.2 17722
Orilẹede Timor-Laste 133 10.3 22959
Orilẹede ajikistan 125 1.3 17786
Orilẹede Sierra Leone 125 1.6 7704
Orilẹede San Marino 115 339.6 18236
Agbegbe St Vincent and the Grenadines 114 103.1 9058
Orilẹede Central African Republic 113 2.4 14649
Isle of Man 108 127.7 36463
Orilẹede Gilbraltar 104 308.6 19633
Orilẹede Eritrea 103 2.9 9805
Erekusu Saint Martin 87 213.6 10601
Orilẹede Liechtenstein 85 223.6 17935
Orilẹede Sao Tomẹ́ and Principe 74 34.4 6064
Orilẹede Dominican 68 94.7 14852
Erekusu Saint Martin ( Agbegbe ti France) 63 165.8 10952
Erekusu Virgin Island tilẹ Gẹẹsi 63 209.8 6941
Orilẹede Monaco 59 151.4 13100
Erekusu Kitts and Nevis 43 81.4 6157
Orilẹede Burundi 38 0.3 42731
Bonaire, Sint Eustatius and Saba 37 142.4 10405
Erekusu Turks and Caicos Island 36 94.3 6219
Erekusu Cayman Island 29 44.7 27594
Orilẹede Samoa 29 14.7 14995
Erekusu Faroe Island 28 57.5 34658
Orilẹede Bhutan 21 2.8 59824
Orilẹede Geenlande 21 37.3 11971
Orilẹede Vanuatu 14 4.7 11389
Orilẹede Kiribati 13 11.1 3236
Ọkọ oju omi Diamond Cruise 13 712
Orilẹede Tonga 12 11.5 12301
Orilẹede Anguilla 9 60.5 3476
Orilẹede Montserrat 8 160.3 1020
Wallis and Futuna Islands 7 61.2 454
Orilẹede Palau 6 33.3 5237
Saint Barthélemy 6 60.9 4697
Ọkọ oju omi Zaandam 2 9
Erekusu Cooks Island 1 5.7 5774
Saint Pierre and Miquelon 1 17.2 2779
Erekusu Falkland Island 0 0.0 1815
Orilẹede Micronesia 0 0.0 38
Ilu Vatican 0 0.0 29
Erekusu Marshall islands 0 0.0 18
Ilẹ antarctica 0 11
Oke Saint Helena 0 0.0 4

Jọwọ ṣe atunṣe ilana ikansi ayelujara rẹ lati ri ẹkunrẹrẹ rẹ

Akọsile imọ yii, da lori akojọpọ iṣẹ iwadi ni Fasisti Johns Hopkins, o si le ma ṣe afihan awọn akọsilẹ iroyin to ba igba mu lati orilẹede kankan.

** Àwọn iyé akọsilẹ̀ to ti wà fún àwọn ti o ṣẹ́ṣẹ̀ ni ààrun náà jẹ́ àkójọpọ̀ ọjọ́ mẹ́ta. Nítori àwọn àtúgbẹ́yẹ̀wò, o níra láti ṣe àkójọpọ fún àwọn ọkọ́ naa

Orisun: Johns Hopkins University atawọn ajọ eto ilera ilu

Iye akọsilẹ to waye gbẹyin 5 Oṣù Agẹmọ 2022 10:59 WAT+3

Nigba ti wọn fi ibeere sọwọ si nipa bi awọn akẹkọ yoo se bọ si ipele mi,o ni ''idanwo ti yoo gbe wọn lọ kilasi mii yoo waye lẹyin tawọn ba ti ri aridaju pe wọn ti kẹkọ to yẹ''

"Fawọn to wa ni kilasi ti wọn yoo ti bọ si abala miran o fi kun pe awọn n se igbaradi fun wọn.

''Lọwọlọwọ bayi, ajọ Waec to n seto idanwo fawọn to fẹ jade ileewe girama kan sun ọjọ idanwo siwaju ni,wọn ko wọgile.Ki a ba le mu ọjọ ni wọn fi ni awọn sun siwaju titi di igba miran.

Awọn akẹkọọ fasiti kan

Oríṣun àwòrán, unilag

Awọn akẹkọ yoo se idanwọ nigba ti a ab ati ri pe a le mojuto wọn daada''

Orileede Naijiria nikan kọ ni awọn ijọba ti gbe igbesẹ ki awọn ileewe wa ni titi pa lasiko arun Coronavirus yi.

Botilejẹpe awọn orileede kan ti wọn ti n jajabọ lọwọ arun naa ti ni ki awọn ipele eto ẹkọ kan bẹrẹ isẹ pada diẹdiẹ.

Awọn akẹkọọ fasiti kan

Oríṣun àwòrán, unilag

Ẹwẹ, ajọ eto ẹkọ ni Abuja ti kilọ fawọn ileeẹkọ lati ma se bẹrẹ isẹ pada nitori pe awọn ko ti pasẹ eyi to faye gba iru igbesẹ bẹ.

Adele akọwe ajọ naa Umaru Marafa ninu atẹjade kan to fi sita lọjọ Isẹgun ni digbi ni asẹ pe ki awọn ileeẹkọ wa ni titi pa si wa ti yoo si ri bẹ titi di igba ti asẹ mi yoo fi waye.

When would schools reopen in Nigeria?: Èyí làwọn ohun tí ọ̀pọ̀ ọmọ Nàìjíríà ń retí ṣùgbọ́n tí ààrẹ Buhari dákẹ́ sí

Aarẹ Muhammadu Buhari n ka ọrọ apilẹkọ rẹ

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad

Aarẹ Muhammadu Buhari gbe ọrọ rẹ kalẹ lori ibi to fẹ gbe ọrọ gba lori eto gbigbogun ti arun Coronavirus lorilẹede Naijiria.

Ọpọlọpọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni wọn fi ojusọna fun ohun ti aarẹ yoo sọ ninu ọrọ rẹ, ti o si ṣe okunfa bi ọpọ ọmọ Naijiria nile ati loko ṣe sun ti awọn ohun elo gbogbo ti wọn lee fi ṣe alabapade aarẹ lori ohun to fẹ ka.

Amọṣa, lẹyin-o-rẹyin awọn nnkan kan wa eleyi ti aarẹ ko mẹnule, eyi ti ọpọ si ti n reti boya yoo sọrọ lori rẹ.

Lara awọn nnkan yii ni ọrọ iku ọwọọwọ to n waye ni ilu Kano. Ko fẹẹ wọpọ ninu awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti ko maa ṣe haahin lori bi iku naa ṣe n waye.

Ọpọ n woo pe boya Aarẹ Buhari yoo lo anfani ọrọ rẹ lati fi ọkan araalu balẹ lori ohun to n ṣẹlẹ gan an ni ipinlẹ Kano, ṣugbọn ninu ohun ti aarẹ ka, yatọ si pe o ni aṣẹ konile-o-gbele ọlọjọyipo yoo wa nikalẹ nibẹ, ko daju pe aarẹ gan an funrarẹ tii mọ ohunkohun nipa okunfa iku ọwọọwọ ni ilu Kano.

Muhammadu Buhari n ba minisita feto ilera sọrọ

Oríṣun àwòrán, Bashir ahmad

Eyi ni awọn ohun miran ti Buhari ko mẹnuba ninu ọr rẹ.

1.Nigba wo lawọn akẹkọ yoo pada si ileewe?

2.Eeyan melo ni yoo maa wa ninu ọkọ Danfo atawọn bọọsi akero nigboro lasiko ti wọn ba dẹ ọwọ aṣẹ naa diẹ bẹrẹ lati ọjọ kẹrin oṣu karun un ọdun 2020.

3.Pẹlu bi oniruuru eeyan yoo ṣe maa gbe ibomu tiwọn ran bayii, bawo la ṣe ayederu mọ ati pe ṣe gbogbo awọn ibomu wọnyii ni yoo le ṣiṣẹ idaabobo lọwọ arun yii?

4.Bawọn lawọn ipinlẹ ti ko lee se ẹnubode wọn lasiko ti konile-o-gble- ọlọjọyipo le koko yoo ṣe wa lee se wọn bayii ti konile-o-gbele ti rọlẹ sii?

5.Ṣe titi ipinlẹ Kano pa yoo jẹ ki a lee mọ ohun gan an to n ṣekupa ọgọọrọ awọn eeyan ni ipinlẹ naa?

Awọn ibeere yii ati omilẹgbẹ miran lawọn ọmọ orilẹede Naijiria n beere bayii lori ikanni ayelujara gbogbo lati igba ti aarẹ ti gbe ọrs apilẹkọ rẹ jade.

Kókó mẹ́jọ tó jẹyọ nínú ọ̀rọ̀ Ààrẹ Buhari fáwọn ọmọ Nàìjíríà

Aarẹ Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Bashir Ahmad

Aarẹ Muhammadu Buhari ti buwọlu wiwa ọwọ ofin konile-o-gbele walẹ diẹ ni ipinlẹ Eko, Ogun ati Abuja bẹrẹ lati Ọjọ Aje, ọjọ kẹrin, oṣu karun ọdun 2020.

Aarẹ Orilẹede Naijiria, ni awọn gbe igbesẹ naa lẹyin ti igbimọ amuṣẹya ti ijọba apapọ gbe kalẹ lori ọrs Coronavirus mu aba naa wa ni ifẹgbẹkẹgbẹ pẹluu awọn gomina atawọn igbimọ miran gbogbo ti ijọba gbe kalẹ.

Ninu ọrọ to ba awọn ọmọ Naijiria sọ lalẹ ọjọ Aje ni Arẹ Buhari ti sọ eyi di mimọ.

O ni adinku yoo de ba ọwọ ofin konile-o-gbele ṣugbọn eto ayẹwo ati ṣisawari awọn to ṣeeṣe ko ni arun naa yoo tubọ gbopọn sii.

Eyi ni awọn ohun meje miran ti aarẹ Buhari sọrọ le lori ninu ọrọ rẹ.

  • Awọn ileeṣẹ kan yoo bẹrẹ si ni ṣiṣẹ pada laarin agogo mẹsan owurọ si agogo mẹfa irọlẹ.
  • Ofin konile-o-gbele yoo maa wa laarin agogo mẹjọ alẹ si agogo mẹfa irọlẹ.
  • Ko ni si eto irinna lati ipinlẹ si ipinlẹ, afawọn ti iṣẹ wọn ba kan dandan.
  • Irinna ipinlẹ yoo wa fun awọn to ba n ko ẹru ti araalu nilo nikan.
  • Wiwọ ibomu(face mask) ti di ọranyan bayii ni ita gbangba, ko si gbọdọ si ipejọpọ ọlọpọ ero nibikibi.
  • Ofin konile-o-gbele yoo ṣi wa nikalẹ ni ipinlẹ Eko, Ogun ati Abuja
  • Ofin konile-o-gbele kogberegbe yoo tẹsiwaju ni ipinlẹ Kano fun ọsẹ meji gbako, gẹgẹ bi ijọba ipinlẹ naa ti ṣe gbe e kalẹ
  • Awọn gomina ipinlẹ kọọkan lee wa ṣe eto bi awọn aṣẹ wọnyii yoo ṣe ba awọn eeyan wọn lara mu ati aṣẹ miran ti ko gbọdọ tako eyi ti aarẹ la kalẹ wọnyii.
Coronavirus
Coronavirus

Corornavirus: Òfin kónílé-ógbélé yoo dínku láti ọjọ kẹrin ọsù tó n bọ̀

Buhari

Oríṣun àwòrán, others

Àkọlé àwòrán, Ààrẹ Buhari ti fawọ kónile -ogbéle wálẹ díẹ̀ ní Eko, Ogun ati Abuja

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kede pé láti ọjọ keji oṣu kaarun ọdun yii adinku yoo ba ofin konileogbele diẹ ni ipinlẹ Eko, Ogun àti Abuja.

Aarẹ ni ìgbesẹ yìí ko ṣẹyin ọna láti ri dáju pé àwọn agbẹ àti awọn oníṣẹ oojọ ko padanu ọna ati jẹ wọn, bákan náà ni ijọba ti ṣepade pọ pẹlu awon to n ri si eto ọ̀rọ̀ aje naijiria ti wọn si ti pese awọn imọran yìí.

Ẹwẹ, aarẹ ni gbigbe ofin yii wálẹ ko tunmọ si pe ki awọn eniyan pa ofin ọwọ fifọ ti, pàápàá jùlọ láti tẹle gbogbo ofin ti àjọ to n gbogun ti àjakalẹ ààrun lórílẹ̀-èdè Naijiria.

Láti aago mẹsan ọjọ keji osù kaarun, àwọn ọmọ le pada si ilé iwe nígba ti awọn ọlọkọ eero naa le pada si oju popo.

Ààrẹ Muhammadu Buhari ni àwọn alasilẹ ti ijọba yoo gunle ree lasiko yii

a. Ààgo mẹjọ alẹ si si aago mẹfa aarọ, eyi tumọ si pe ko ni si igbokegbodo eniyan ati ọkọ laaarin asiko yii.

b. Ko ni si aaye fun ọkọ ti ko ba ko àwọn ǹkan bii oogun tabi ounjẹ láti kọja ni ilú kan si omiran

kò ni si aaye irin aajo láti ipinlẹ kan si omiran, bakan naa ni gbogbo eniyan gbọdọ maa lo ibomu-bẹnu ni ìgbà gbogbo.

Bakan naa ni aarẹ fi kun pe ìjọba yoo fi alaalẹ sita lori igbesẹ ti awon ile iṣẹ yoo gbe ni asiko yii.

Ẹwẹ, aarẹ ni gbogbo awon alaalẹ yii ko kan ipinlẹ Kano

Aarẹ Muhammadu Buhari rọ àwọn ọmọ Naijiria lati tubọ ni maa fọwọsowọpọ pẹlu ijọba àti àwọn eleto abo láti tubọ tẹsiwaju ninu gbigbogun ti aarun coronavirus

O dupẹ lọwọ awọn osiṣẹ ilera, ajọ NCDC gbogbo ile iṣẹ ati aladani ti wọn nawọ iranwọ si ijọba àti awọn Naijiria

Ààrẹ Buhari yóò bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ lónìí

Buhari to address the nation: Kí ni Ààrẹ Buhari yóò bá àwọn ọmọ Nàìjíríà sọ̀rọ̀ lónìí?

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Garba Shehu

Aarẹ Muhammadu Buhari yoo ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria sọrọ ni agogo mẹjọ ọjọ Aje.

Atẹjade kan eyi ti olubdamọran agba lori ọrọ iroyin, Fẹmi Adeṣina fi sita leyi ti jẹyọ.

Atẹjade ọhun fi kun un pe gbogbo awọn ileeṣẹ iroyin, edio, tẹlifiṣan and awọn ileeṣẹ iroyin miran to ba nifẹ sii lee darapọ mọ aarẹ.

Ni ọsẹ meji sẹyin ni aarẹ ba awọn ọmọ orilẹede Naijiria sọ irufẹ ọrọ bayii kẹyin nigba to kede afikun iye ọjọ igbele lati dena arun Coronavirus ni ipinlẹ Ogun, Eko ati Abuja tii ṣe olu ilu orilẹede Naijiria.

Ireti awọn eeyan ni pe aarẹ yoo ṣi aṣọ loju eegun fun araalu lati ms igbesẹ to kan lori aṣẹ konile-o-gbele jakejado orilẹede Naijiria.

Coronavirus extension in Nigeria: Ààrẹ Buhari leè pàṣẹ kónílé-ó'gbélé jákèjádò Nàìjíríà lọ́jọ́ Ajé-Kọmíṣọ́nà fétò ìlera ní ìpínlẹ̀ Ondo

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Muhammadu Buhari

O ṣeeṣe ki aarẹ orilẹede Naijiria o kede itẹsiwaju aṣẹ konileogbele to wa nilẹ ni awọn ipinlẹ bii Ogun, Eko ati Abuja.

Amọṣa iyatọ ti o ṣeeṣe ko de baa ni pe aarẹ Buhari lee fẹ aṣẹ naa loju ko ka gbogbo orilẹede Naijiria lai da ipinlẹ kọkan si.

Kọmiṣọna fun eto ilera ni ipinlẹ Ondo, Dokita Wahab Adegbenro lo sọ eyi di mimọ fun BBC News Yoruba.

Dokita Adegbenro ni awọn gomina ipinlẹ gbogbo lorilẹede Naijiria ti fi ero wọn han fun Aarẹ pe ohun ti wọn fẹ ni ki ijọba apapọ o ti gbogbo ipinlẹ pa lorilẹede Naijiria.

Bakan naa lo ni awọn kọmiṣọna ipinlẹ naa ti fi ọrọ to aarẹ leti gẹgẹ bi awọn onimọ pe ohun ti orilẹede Naijiria nilo bayii lati koju itankalẹ Coronavirus.

Ni aṣalẹ oni ni ireti wa pe Aarẹ Muhammadu Buhari yoo bun awọn ọmọ orilẹede Naijiria sori lori ohun to kan gẹgẹ bi igbesẹ lori aṣẹ konileogbele.

Kí lawn ọmọ Naijiria n reti lẹnu Aarẹ?

Lọwọ yii, iye awọn eeyan to laarun Coronavirus lorilẹede Naijiria ti le ni ẹgbẹrun bayii ti ijọba apapọ ti kede.

Titi di aṣalẹ ọjọ Aiku tii ṣe ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2020, ipinlẹ mejilelọgbọn lo ti ni aarun Coronavirus lorilẹede Naijira pẹlu olu ilu ilẹẹwa, Abuja.

Bi iye awọn eeyan to n ko aarun yii ṣe n fojojumọ goke sii, paapaajulọ ni awọn ipinlẹ bii Eko, Kano ati Abuja, Aarẹ Buhari kede ofin konile-o-gbele ọlọjọ mẹrinla lawọn ipinlẹ bii Eko, Ogun ati Abuja. Nigba ti eyi pari ni aarẹ ba tun kede konile-o-gbele ọlọjọ mẹrinla miran eleyi tii yoo pari ni agogo mọkanla ọjọ Aje, ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹrin ọdun 2020 lati dena itankalẹ arun yii.

Coronavirus
Coronavirus

Lawọn ipinlẹ bii Ogun, Eko ati Abuja, igbele oṣu kan gbako lawọn araalu ti wa bayii, eleyii to n mu ki ọpọ maa beere nigba wo ni igbele awọn yoo pari?

Ni bi a ṣe n sọrọ yii, ariwo to n ls loju opo ayelujara gbogbo bayii ni ibeere boya aarẹ yoo ṣi tun sun aṣẹ igbele tipatipa naa siwaju sii ni labẹ #lockdownextension

Coronavirus Update: Ìséde káàkiri Nàìjíríà lọ̀nà àbayọ sí ìtànkálẹ̀ ààrùn coronavirus

Onimọ nipa ajakalẹ aarun to ba BBC Yoruba ṣalaye pe iṣede kaakiri orilẹede Naijiria yoo ṣe iranwọ nipa gbogbogun ti itankalẹ aarun coronavirus.

Lai jẹ bẹẹ, aarun coronavirus maa ran ni kiakia de awọn ipinlẹ ti ko tii de ti ko ba si iṣede kaakiri orilẹede Naijiria.

O ni otitọ nipe iṣede kaakiri orilẹede Naijiria yoo mu idiwọ ba awọn onimọtọ atawọn mii ti iṣẹ wọn jọ mọ ki wọn maa rinrin ajo.

O rọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ara daa fun ọsẹ meji nitori anfaani gbogbo ọmọ Naijiria naa ni.

Ni ipinlẹ Osun, agbẹnusọ gomina, sọ pe awọn ti di gbogbo ọna to wọ ipinlẹ Osun lati awọn ipinlẹ miran. To si jẹ pe niṣe ni awọn ọlọpaa n da ọkọ ati eero to ba fẹ ẹ wọ ipinlẹ naa pada si ibi ti wọn ba ti n bọ.Ni ti akọwe ikede fun gomina Ondo, sọ fun BBC pe lootọ ni ofin de awọn ọkọ lati ipinlẹ miran si Ondo, aaye gba awọn ọlọkọ eero laarin ipinlẹ Ondo, kiki pe wọn ko gbọdọ gbe ju eero meji lọ.

Lori ẹsun pe awọn oṣiṣẹ alaabo n gba owo lọwọ awọn awakọ lati wọ ipinlẹ naa, o sọ pe lootọ ni iru nkan bẹ ẹ waye, ṣugbọn "a ti mojuto, o ti dawọ duro. Gomina ṣepade pẹlu awsn eleto aabo ni kete to mọ pe wọn n ṣe bẹ, ko si si iru ẹ mọ".

Gomina Kayọde Fayẹmi

Oríṣun àwòrán, Ekiti state government

Fun ipinlẹ Oyo, Agbẹnusọ Gomina, Taiwo Adisa sọ pe awọn ti fi ofin de ọkọ lati ipinlẹ miran si ipinlẹ Oyo ko tiẹ to o dipe ẹgbẹ awọn gomina ṣe bẹ ẹ.

Ṣugbọn o, o ni awọn kẹẹfin pe awọn ọkọ maa n yọ ọ wọle ni alẹ, awọn si ti dawọ rẹ duro.

Koda, o sọ pe ọwọ tẹ awọn ọkọ ileeṣẹ nla kan mẹfa, to yẹ ko ko ounjẹ, ṣugbọn wsn tun fi ko awọn eeyan lọna aitọ.

Lọwọlọwọ, wọn ti n dawọn pada si ibikibi ti wọn ba wa.

Ìséde ń bọ̀ káàkiri Nàìjíríà, àwọn gómìnà ìpínlẹ̀ fẹ́nukò

Awọn gomina ipinlẹ gbogbo lorilẹede Naijiria ti fẹnu kolori titit gbogbo ẹnubode ipinlẹ si ipinlẹ pa jakejado orilẹede Naijiria fun ọsẹ meji bayii lati pinwọ itankalẹ ajakalẹ arun Coronavirus lorilẹede Naijiria.

Alaga igbims awọn gomina ipinlẹ lorilẹede Naijiria to tun jẹ gomina ipinlẹ Ekiti, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi lo sọ eyi di mimọ lẹyin ipade ori ayelujara tawọn gomina naa ṣe lọjọru.

O 'salaye pe awọn eeyan ti iṣẹ wọn jẹ koṣemaani nikan ni aaye yoo wa fun lati maa rin lasiko naa.

O ni wọn fi ọrọ to awọn gomina ipinlẹ gbogbo leti nibi ipade naa lori bi nnkan ṣe n fojojumọ yii sii lori ija gbigbogun tarun COVID-19 pẹlu ipa ti awọn ẹka aladani nko pẹlu idasilẹ eto CACOVID ti wọn gbe kalẹ lati ṣe iranwọ to ba yẹ.

Àkọlé fídíò, Epo rọ̀bì ti ṣàkóbá fáwọn olùgbé apá odò l'Ondo

O ni pẹlu bi arun naa ti ṣe tan kalẹ de awọn ipinlẹ marundinlọgbọn bayii, awọn gomina ti fọwọ si pinpin eto idojukọ arun COVID-19 kakiri awọn ipinlẹ lorilẹede yii.