Owo church attack: Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn ìkọlù Owo, níbo ni nnkan dé dúró?

- Author, Busayo James-Olufade
- Role, Senior Journalist
- Reporting from, BBC Yoruba, Lagos
- Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 6
O pe ọdun mẹta bayii, ti awọn agbebọn kọlu ile ijọsin kan niluu Owo, nipinlẹ Ondo, nibi ti wọn ti ṣeku pa eeyan to le ni ogoji, ti ọpọ si tun farapa.
Awọn agbebọn naa kọlu ile ijọsin St. Francis Catholic Church, ni owurọ ọjọ isinmi, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, lasiko ti ijọsin n waye.
Lẹyin ọdun meji, awọn ti iṣẹlẹ naa kan ẹbi wọn, ijọ Ọlọrun, ati ilu Owo, ṣi n beere fun idajọ ododo.
Oore-ọfẹ ni alufaa n ṣe lọwọ nigba ti iro ibọn akọkọ dun. Adura oore-ọfẹ to si yẹ ko jẹ adura ipada lọ sile lẹyin isin, pada di adura a gba lọ si ọrun fun ọpọ ọmọ ile ijọsin St Francis Catholic Church, niluu Owo.
Ado oloro dynamite ti awọn agbebọn to yabo ile ijọsin naa fi fọ ilẹkun ṣọọṣi ọhun ni nnkan bi aago mọkanla aabọ owurọ ọjọ isinmi ọhun lo fa ere a sa pajude, ẹni ori yọ, o di le.
Bi awọn eeyan ṣe n gbiyanju lati sa jade, ni wọn n ko awọn agbebọn lọna, bẹẹ ni iro ibọn tun n dun lakọ-lakọ.
Awọn ti isẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe, ko din ni aadọta oku eeyan ti awọn ka, lara eyi ti awọn ọmọde ati arugbo wa.
Ọpọ farapa, bẹẹ ni ẹjẹ n ṣan bi omi lori pẹpẹ ati ilẹ ile ijọsin naa.

Ẹsẹ mejeeji ni Folayemi Atah padanu

Isin ọjọ naa jẹ akanṣe – Isin Pẹntikọsi ni – eyi to jẹ ajọdun bi ijọ ṣe bẹrẹ, o si tun jẹ opin asiko ọdun Ajinde.
Ẹnikan lara awọn to farapa ninu ikọlu ọhun, Arabinrin Folayemi Margaret Atah ba BBC Yoruba sọrọ. Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin ni.
Arabinrin Atah sọ pe iṣẹlẹ naa lo sọ ohun di ẹni ti ko ni ẹsẹ mejeeji mọ, ti oju rẹ kan si tun fọ.
"Emi ati ẹbi mi wa si ile ijọsin lọjọ naa, gẹgẹ bi iṣe wa. Aaye akọrin ni mo joko si, ki n to deede gbọ iro nla.
"Iro nla naa ni mo gbọ kẹyin, ko to o di pe mi o gbọ nkankan mọ. Niṣe lo dabi i pe eti mi di, ti eefin si gba gbogbo inu ṣọọṣi."
Nigba ti iye Arabinrin Attah yoo fi sọ pada, gbogbo oju rẹ ti kun fun ẹjẹ, ẹsẹ rẹ si ti "di akisa".
Bakan naa lo sọ pe oun ko le sọrọ mọ lẹsẹkẹsẹ.
'Iya ati baba mi lo ku lọjọ naa'
Ni ti Onuoha Chinedu Dominic, ẹni to padanu iya ati baba rẹ sinu iṣẹlẹ naa, o sọ pe alufa ijọ ni oun kọkọ ro pe awọn agbebọn wa a ji gbe.
Ọgbẹni Onuoha sọ pe iya oun ni oun kọkọ ri nibi to farapa si, ti awọn si sare gbe e lọ sileewosan.
"Nigba ti ma a fi pada wa pe ki n wa baba mi, mo ba a ni ẹgbẹ odi nibi ti wọn ti fi ibọn fọ ori rẹ si."
O ni ero ọkan oun ni pe ki oun wa baba oun nibi to sa si, ki oun si jẹ ko mọ pe wn ti ri iya oun, amọ oku rẹ lo ba.
Akojọpọ awọn to ku ninu ikọlu naa
Ko din ni ogoji eeyan ti ijọba ipinlẹ Ondo sọ pe o padanu ẹmi wọn sinu iṣẹlẹ laabi ọhun, ninu eyi ti ọmọde mẹrin wa.

Oríṣun àwòrán, Ondo State Government

Oríṣun àwòrán, Ondo State Government

Oríṣun àwòrán, Ondo State Government

Oríṣun àwòrán, Ondo State Government

Oríṣun àwòrán, Ondo State Government
Nibo ni awọn ti awọn ti agbofinro sọ pe awọn mu wa?

Iyalẹnu gba a ati nnkan ojiji ni ikọlu yii jẹ, paapaa nitori pe iroyin nipa rogbodiyan kii ṣaba wa lati ilu Owo bi ti awọn ilu mii ni Naijiria.
Lootọ si ni ikọlu ti ma n waye si awọn ile ijọsin ọmọlẹyin Kristi ṣaaju, eyi to jẹ ara ọna ti ẹgbẹ agbesunmọmi Boko Haram n lo. Ipakupa to waye ni Owo ṣi n jẹ kayeefi fun ọpọ eeyan.
Ijọba Naijiria labẹ iṣakoso Aarẹ Muhammadu Buhari, gbagbọ pe, ikọ agbesunmọmi Islamic State lo wa nidii ikọlu ọhun, amọ awọn ara ilu ko gba bẹẹ, to fi mọ Gomina Rotimi Akeredolu.
Oṣu diẹ lẹyin ikọlu yii ni ijọba ipinlẹ Ondo kede pe ọwọ tẹ awọn afurasi to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa. Ṣugbọn lati igba naa, awọn ara ilu Owo sọ pe awọn ko gbọ ohunkohun nipa wọn mọ.
Ninu oṣu Kẹjọ, ọdun 2022 bakan naa ni iroyin tẹ BBC lọwọ pe ọwọ ileesẹ ologun ti tẹ awọn agbebọn ti kọlu sọọsi kan ni Owo.
Olori awọn osisẹ alaabo , Ọgagun Lucky Irabor lo sisọ loju isẹlẹ naa lasiko to n ṣe ipade pẹlu awọn akọroyin.
Irabor ni kii se igi awọn ologun nikan lo da igbo se nidi ọrọ naa amọ awọn se aseyọri naa nifọwọkọwọ pẹlu awọn ileesẹ agbofinro yoku.
Gomina Akeredolu, paapaa sọ pe lootọ ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ awọn agbebọn to wa kọlu sọọsi Owo.
Akeredolu ni bakan naa ni ọwọ awọn agbofinro ti tẹ baba onile ti awn agbebọn naa gbe ile rẹ saaju ikọlu naa.
O ni awọn agbofinro ko fi epo bọ iyọ lati se awari awọn agbebọn to sisẹ laabi nilu Owo naa.
Amọ titi di akoko yii, ko si iroyin kankan to sọ boya afurasi kan tabi baba onile ti ọwọ tẹ, ṣi wa ni ahamọ agbofinro tabi ti gba idajọ kankan nile ẹjọ.
BBC Yoruba ba kọmisanna ọlọpaa fun ipinlẹ Ondo, Wilfred Olatokunbo Afolabi sọrọ lori ibi ti iwadii de duro lori ikọlu ọhun.
Olatokunbo Afolabi sọ pe nnkan ti oun le sọ lori ikọlu naa ko ju pe, iru rẹ ko ni i ṣẹlẹ mọ.
"Emi kọ ni kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Ondo lasiko naa."
"Amọ, gbogbo ọjọ Aiku ni mo n ko awọn ọlọpaa lọ siluu Owo lati pese aabo to daju fun gbogbo awọn ile ijọsin."












