‘Nígbà tí màá fi sọjí lẹ́yìn ariwo tí mo gbọ́, ojú mi ti kún fún ẹ̀jẹ̀, ẹsẹ̀ mi ti di àkísà'

Àkọlé fídíò,
‘Nígbà tí màá fi sọjí lẹ́yìn ariwo tí mo gbọ́, ojú mi ti kún fún ẹ̀jẹ̀, ẹsẹ̀ mi ti di àkísà'
    • Author, Olumide Owaduge, Oluwadara Onipede
    • Role, BBC Journalist

O pe ọdun meji bayii, ti awọn agbebọn kọlu ile ijọsin kan niluu Owo, nipinlẹ Ondo, nibi ti wọn ti ṣeku pa eeyan to le ni ogoji, ti ọpọ si tun farapa.

Awọn agbebọn naa kọlu ile ijọsin St. Francis Catholic Church, ni owurọ ọjọ isinmi, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, lasiko ti ijọsin n waye.

Lẹyin ọdun meji, awọn ti iṣẹlẹ naa kan ẹbi wọn, ijọ Ọlọrun, ati ilu Owo, ṣi n beere fun idajọ ododo.

Ṣaaju ni ijọba kede pe ọwọ tẹ awọn afurasi to lọwọ ninu iṣẹlẹ naa. Ṣugbọn lati igba naa, awọn ara ilu Owo sọ pe awọn ko gbọ ohunkohun nipa wọn mọ.

BBC yoruba ṣe abẹwo si ile ijọsin naa, to si tun ba meji sọrọ lara awọn to kagbako ninu iṣẹlẹ ọhun.

Ẹnikan lara awọn to farapa ninu ikọlu ọhun, Arabinrin Folayemi Margaret Atah ba BBC Yoruba sọrọ. Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ akọrin ni.

Arabinrin Atah sọ pe iṣẹlẹ naa lo sọ ohun di ẹni ti ko ni ẹsẹ mejeeji mọ, ti oju rẹ kan si tun fọ.

“Emi ati ẹbi mi wa si ile ijọsin lọjọ naa, gẹgẹ bi iṣe wa. Aaye akọrin ni mo joko si, ki n to deede gbọ iro nla.

“Iro nla naa ni mo gbọ kẹyin, ko to o di pe mi o gbọ nkankan mọ. Niṣe lo dabi i pe eti mi di, ti eefin si gba gbogbo inu ṣọọṣi.”

Arabinrin Atah ṣalaye pe nigba ti iye oun yoo fi sọ pada, gbogbo oju oun ti kun fun ẹjẹ, ẹsẹ rẹ si ti “di akisa".

Bakan naa lo sọ pe oun ko le sọrọ mọ lẹsẹkẹsẹ.

Ẹlomiran ti a tun ba sọrọ, Ọgbẹni Onuoha Chinedu Dominic, ẹni to padanu iya ati baba rẹ sinu iṣẹlẹ naa, sọ pe alufa ijọ ni oun kọkọ ro pe awọn agbebọn wa a ji gbe.

Ọgbẹni Onuoha sọ pe iya oun ni oun kọkọ ri nibi to farapa si, ti awọn si sare gbe e lọ sileewosan.

“Nigba ti ma a fi pada wa pe ki n wa baba mi, mo ba a ni ẹgbẹ odi nibi ti wọn ti fi ibọn fọ ori rẹ si.”

O ni ero ọkan oun ni pe ki oun wa baba oun nibi to sa si, ki oun si jẹ ko mọ pe wn ti ri iya oun, amọ oku rẹ lo ba.

Alufaa ijọ naa. Rev’d Michael Abugan, sọ pe iṣẹlẹ naa ti mu adinku ba iye awọn olujọsin ninu ijọ St. Francis.

O ni o ma n to ẹgbẹta eeyan to n jọsin lẹẹkan naa ṣaaju ikọlu ọdun 2022, amọ lasiko yii, awọn to n wa kii ṣaba a pe igba.

O ni ọpọlọpọ lo ti sọ pe awọn ko ni i wa si ile Ọlọrun mọ.

Olowo ti Owo, Ọba Ajibade Gbadegesin Ogunoye III, sọ pe awọn ko ri pato kankan lati igba ti ijọba sọ pe iwadii n lọ lori iṣẹlẹ ọhun.

Ẹni to jẹ agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Ebenezer Adeniran sọ pe ijọba ti gbe gbogbo ọrọ naa le awọn to wa ni ẹka idajọ lọwọ.

Bakan naa ni agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Arabinrin Funmilayo Odunlami sọ pe iṣẹ ṣi n tẹsiwaju lori ikọlu naa, ti idajọ ododo yoo si waye lọjọ kan.

Fidio bi inu ile Ijọsin St. Francis ṣe ri ni kete ti ikọlu naa waye

Skip Facebook post

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post