Owo Church Attack:Okú mẹ́fà, ogún aláyè tó farapá ni wọ́n kó wá sí iléèwòsàn FMC Owo - Ọ̀gá àgbà FMC

Dokita Ahmed Adeagbo, to jẹ oludari agba fun ileewosan ijọba, Federal Medical Centre, sọ fun BBC pe oku eeyan mẹfa ni wọn gbe de ileewosan naa.
Yatọ si awọn yii, o ni eeyan bi ogún ni wọn gbe wa to ti farapa.
Ileewosan FMC, Owo, ni ọkan lara awọn ileewosan ti wọn gbe awọn to farapa nibi ikọlu ti awọn agbebọn ṣe si ile ijọsin Aguda kan nilu naa.
O tun sọ pe eeyan marun-un ni wọn sare gbe wọn yaara iṣẹ abẹ.
“Ọgbẹ ọta ibọn ati bi i pe nkan jo eeyan ni ara, lo wa lara awọn ti wọn gbe wa sileewosan FMC.”
Bakan naa lo sọ pe awọn ọmọde naa wa lara wọn.
'Kò sí àlùfàá tí wọ́n jígbé níbi ìkọlù sí ṣọ́ọ́ṣì ní Owo'
Awọn olori ijọ Aguda nipinlẹ Ondo, ti koro oju si ipaniyan to waye ni ẹka ile ijọsin naa kan nilu Owo, nipinlẹ Ondo, lọjọ Aiku.
Ninu atẹjade ti akọwe ikede ile ijọsin naa fi sita, Alufaa Augustine Ikwu, sọ pe ibanujẹ nla gba a ni iṣẹlẹ naa jẹ fun ijọ.
O ni gbogbo awọn alufa ati bisọọpu to wa ninu ijọ St. Francis Catholic church, ti iṣẹlẹ naa ti waye lo wa ni alaafia.
O sọ eyi gẹgẹ bi esi si iroyin kan to n lọ lori ayelujara pe awọn agbebọn naa ji lara awọn alufaa gbe lọ.
Ọ̀fọ̀ ayérayé n dúró de àwọn tó kọlu ilé ìjọsìn ní Owo - Buhari

Oríṣun àwòrán, others
Aarẹ Muhammadu Buhari ti bu ẹnu atẹ lu ikọlu ti awọn agbebọn ṣe si ile ijọsin Aguda kan nipinlẹ Ondo lọjọ Aiku, ọjọ karun-un, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.
Ninu atẹjade ti agbẹnusọ rẹ, Femi Adesina fi sita lori ayelujara Facebook, ni Buhari ti sọ pe awọn ẹlẹmi okunkun nikan lo le ṣe iru iṣẹ buruku bẹẹ.
“Aarẹ sọ pe ọ̀fọ̀ ayeraye lo n duro de awọn to sẹ ikọlu ọhun, ni aye ati ni ọrun.”
O ni orilẹ-ede Naijiria ko nii fi aaye silẹ fun awọn oniṣẹ okunkun, lati bori imọlẹ rẹ.
Ọwọ́ ìjọba yóò tẹ àwọn agbébọn tó kọlu ṣọ́ọ̀ṣì l‘Owo, á gbẹ̀san ìwà ìpànìyàn náà - Akeredolu

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu, ti koro oju si ikọlu to waye nile ijọsin kan nilu Owo lowurọ ọjọ Aiku.
Iroyin sọ pe isin ọjọ isinmi ṣẹṣẹ pari ni, nigba ti awọn agbebọn ti ẹnikẹni ko mọ yabo ile ijọsin ọhun, ti wọn si n yinbọ mọ awọn olujọsin.
Gomina Akeredolu sọ pe iṣẹlẹ naa jẹ eyi to jani laya, ti oun ko si nireti iru rẹ rara.
“Iṣẹlẹ yii ba mi lojiji. Ṣugbọn ju gbogbo rẹ lọ, ao lo gbogbo nkan to wa ni ikapa wa, lati mu awọn to ṣe ikọlu yii.
“Mo ba awọn eniyan mi nilu Owo kẹdun, paapaa mọlẹbi awọn to ku, ati ijọ Aguda.”
Akeredolu rọ awọn eniyan ilu Owo, lati ma gbeja ara wọn, ki wọn o si ma a kiyesara.
O ni oun ti ba awọn olori ileeṣẹ eto aabo sọrọ, idaniloju si ti wa pe awọn alaabo yoo da alaafia pada silu Owo.
Ọpọ eeyan, to fi mọ awọn ọmọde ati obinrin, lo ku, to si farapa nibi iṣẹlẹ naa.
'Àdó ikú 'dynamite' ni wọ́n kọ́kọ́ jú, kí wọ́n tó yìnbọn mọ́ olùjọ́sìn'
Iroyin to n jade lati ilu Owo, nipinlẹ Ondo sọ pe ọpọ eeyan lo ku ninu agbara ẹjẹ ninu ile ijọsin Aguda kan lowurọ ọjọ Aiku.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, isin owurọ ọjọ isinmi n lọ lọwọ ninu ijọ naa, St. Francis Catholic Church, Owaluwa, Owo, ni awọn agbebọn yabo ṣọọṣi naa ti wọn si ṣina ibọn bo awọn olujọsin.
Nkan ti akọroyin BBC Yoruba fojuri
Akọroyin BBC to lọ sibi iṣẹlẹ naa jabọ pe, awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe awọn afurasi darandaran lo kọlu ile ijọsin naa.
O ni oun paapaa fi oju ri ẹjẹ rẹpẹtẹ ati oku eeyan ninu ile ijọsin naa.
Awọn eeyan naa tun sọ pe wọn ti gbe awọn oku kan lọ si mọṣuari, ati awọn eeyan kan lọ si ileewosan ṣaaju ko to o de ibẹ
Akọwe ẹgbẹ ọdọ ninu ijọ naa, sọ fun BBC pe, alufaa ti ṣe oore-ọfẹ ipari isin, ti awọn eeyan si fẹ ma a jade.


“Ọkunrin kan to n ta nkan ẹlẹrindodo ni ẹnu ọna ṣọọṣi naa ni wọn kọkọ yinbọn mọ.
“Bi a ṣe rii nkan to ṣẹlẹ, a sare ti ilẹkun lati daabo bo gbogbo wa. Lẹyin asiko diẹ, a ro pe iṣẹlẹ naa ti rọlẹ, a si ni ki awọn eniyan ma a lọ.
“Sadeede ni awọn eeyan kan yawọ inu ṣọọṣi, ti wọn si ju nkan abugbamu ‘dynamite’, ki wọn o to bẹrẹ sini yinbọn mọ awọn olujọsin.












