"A máa gbé ohun ìjà wá láìpẹ́, Ọlọ́pàá tí kùnà." Akeredolu sọ fún Malami

aworan akeredolu ati malami

Oríṣun àwòrán, screenshot

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredilu ati Agbẹjọro Agba fun Naijira, Abubakar Malami gbena woju ara awọn lori oro atunto ise ijọba ati oro eto abo orilede Naijira.

Akeredolu sọ fun agbẹjoro agba Malami pe olopaa ti kuna lati dola ẹmi ati dukia awọn ọmọ orilede Naijira, ti ọpo si ti sẹtan lati gbe ohun ija wọn laipe nitori ijakulẹ awọn olopaa orilede Naijira.

Awọn mejeeji lo wa laarin awọn sọrọ nibi ayẹyẹ ipade awọn agbẹjọro agba to waye ni ipinlẹ Eko

aworan gomina akeredolu

Oríṣun àwòrán, screenshot

Nigba ti Akeredolu sọrọ, bi ijọba apapọ se kuna lati dabo bo ẹmi ati dukia awọn ara ilu, lo jẹ ki opo ma gbinyanju lati dabo bo ara wọn.

O tẹsiwaju pẹ awọn ileese olopaa kakiri orilede Naijira ni ijọba o se amujuto lori nipa rira irinse igbalode fun wọn lati dola ẹmi ati dukia awọn ara ilu.

Ni afikun, O salaye iṣẹlẹ to waye niluu Owo gẹgẹ bi apẹẹrẹ lẹyin ti awọn olopaa agbagbe naa ni awọn ko ni anfani lati dola ẹmi awọn to ba iṣẹlẹ naa lo nitori pe ko si ọko ti wọn gbe de ibi iṣẹlẹ naa lasiko ikọlu naa waye.

“ileese olopaa ti kuna lati dola ẹmi ati duj=kia awọn ọmọ orilede Naijiria.”

“Ẹto abo lorilede Naijiria ti jẹ ka ri dajudaju pẹ a lilo olopaa ipinlẹ.”

“Olopaa ti jawa kulẹ, a si gbe ohun ija laipe”

Nigba ti o di esi oro, Abubakar Malami ni awọn gomina ipinlẹ ko le ma fun atunto iṣe ijọba ati olopaa ipinlẹ nigba ti awọn gan ko tẹlẹ eto iṣe ijoba.

aworan agbejoro agba malami

Oríṣun àwòrán, screenshot

Malami wa fi ẹsun kan awọn gomina lori bi wọn se fu awọn ijọba ibile ni agbara to tọ si wọn ninun ẹto ise ijọba orilede Naijira