Wọ́n ti fi orúkọ mi ráńṣẹ́ sí INEC gẹ́gẹ́ bí igbákejì Peter Obi – Doyin Okupe

Peter Obi àti Doyin Okupe

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Adarí ìpolongo ètò ìdìbò fún olùdíje sípò Ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party, Doyin Okupe ti kéde wí pé òun ni ẹni tí ẹgbẹ́ òṣèlú náà fà kalẹ̀ báyìí gẹ́gẹ́ bí igbákejì Peter Obi.

Okupe ló kéde ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó ń kópa lórí ètò “Politics today” ti iléeṣẹ́ iléeṣẹ́ amóhùnmáwòrán Channels Television ní alẹ́ ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Kẹfà, ọdún 2022.

Bákan náà ló ní ó ṣeéṣe kí òun fi ipò náà sílẹ̀ tí àwọn bá rí ọ̀dọ́ tó lè gba ipò lọ́wọ́ òun.

Ó ní ìgbésẹ̀ tó ṣì ń lọ lọ́wọ́ ni ọ̀rọ̀ yíyan igbákejì Ààrẹ jẹ́ fún ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party nítorí àwọn ṣì ń bá àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú mìíràn sọ̀rọ̀ láti darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú àwọn.

Ó fi kun pé òfin àjọ tó ń rí sí ètò ìdìbò ní Nàìjíríà fi àyè gba pé olùdíje sípò Ààrẹ le fi orúkọ kan sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí igbakejì, tó sì lè yí orúkọ náà padà tí àwọn ìpinu tàbí àyípadà mìíràn bá wáyé nínú ẹgbẹ́.

“Ohun ta fẹ́ nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party ni pé kí àwọn ọ̀dọ́ pọ̀ nínú òṣèlú, gbogbo àwa ta sì ti fìgbà kan wà nínú ìjọba nígbà kan rí sẹ́yìn ti ṣetán láti fipò sílẹ̀ fún àwọn ọ̀dọ́ tó ń bọ̀ lẹ́yìn wa.

“Irú àwọn ìgbésẹ̀ báyìí ló le mú kí àwọn ọ̀dọ́ dé ipò àṣẹ àti olórí, mo ṣetán láti fipò náà sílẹ̀ kí àwọn ọ̀dọ́ le rí ìgbéga.

Doyin Okupe ló ti fìgbà kan rí jẹ́ olùrànlọ́wọ́ pàtàkì lórí ìròyìn àti ìpolongo sí Olusegun Obasanjo nígbà tó wà nípò gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ.

Atiku kéde Ifeanyi Okowa gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀ nínú ètò ìdìbò ọdún 2023

Ifeanyi Okowa ni Atiku kéde gẹ́gẹ́ bíi igbákejì rẹ̀ nínú ètò ìdìbò ọdún tó ń bọ̀

Atiku Abubakar

Oríṣun àwòrán, @atiku

Oludije sipo Aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, Atiku Abubakar, ti kede gomina ipinlẹ Delta, Ifeanyi Okowa, gẹgẹ bii igbakeji rẹ.

Atiku funra rẹ lo kede orukọ Okowa nibi eto kan ti wọn ṣe niluu Abuja, ko to fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ.

Nigba to n sọrọ lori eredi to ṣe yan Okowa, Atiku sọ pe ẹni ti yoo ṣe igbakeji oun gbọdọ jẹ ẹni ti yoo le di ipo Aarẹ mu, ti yoo si le ṣe atilẹyin fun oun gẹgẹ bii Aarẹ.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post

O fi kun pe irufẹ ẹni bẹẹ gbọdọ ṣe afihan iṣokan Naijiria ati ẹni ti ko ni bẹru lati sọrọ soke ti nnkan ko ba lọ dede, ti yoo si le fun ijọba ni amọran to dara.

Atiku tun sọ pe igbakeji oun gbọdọ ni imọ nipa ibi ti nnkan bajẹ de ni Naijiria ati ọna ti awọn fi le ṣe atunṣe.

Ohun to kan lẹyin ikede yii

Ni bayii ti wọn ti kede Okowa gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije gẹgẹ bii igbakeji Atiku, igbimọ kan yoo ṣe ayẹwo ati iwadii ọkunrin naa.

Ṣaaju lawọn eeyan kan ti kọkọ n sọ pe gomina Nyesom Wike ni Atiku yoo yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ.

Amọ lọjọru ni ẹgbẹ oṣelu PDP kede pe ko si ohun to jọ pe awọn yoo yan Wike gẹgẹ bii igbakeji Atiku.

Agbẹnusọ ẹgbẹ naa, Debo Ologunagba ni irọ nla gbaa ni awọn iroyin to lọ laarin igboro pe PDP ti yan Wike sipo ẹni ti yoo dije du ipo igabkeji ọhun.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ibo 237 ni Wike ni ninu eto idibo abẹnu ẹgbẹ ọhun lati yan ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu eto idibo ọdun to n bọ.

Amọ Wike fidi rẹmi, nigba ti Atiku gbegba oroke.

Lẹyin eto idibo naa ni Wike ṣo ni gbangba pe ẹnikẹni ti ẹgbẹ ọhun ba ti yan gẹgẹ bii Aarẹ ni oun yoo ṣatilẹyin fun, fun ilọsiwaju ẹgbẹ naa.