Fíìmù tuntun ‘Lady of Heaven’ dá ìfèhónúhàn, ìfòfindè sílè
Lady of Heaven: Àwọn ilé sinima fòfin de Fíìmù tuntun ‘Lady of Heaven’

Oríṣun àwòrán, AFP
Ileeṣẹ to n risi ọrọ sinima ni orilẹede Morocco ti fofin de wiwo fiimu ti wọn ṣe ni Ilẹ Gẹẹsi, ti akọle rẹ n jẹ ‘Lady of Heaven.’
Idi ti wọn fi gbegile ni pe o tabuku ̣ọrọ ẹsin, ti awọn alaṣẹ ẹsin nilẹ naa si fofin de.
Ohun ti fiimu naa da le lori ni itan Lady Fatima, to jẹ ọmọ Prophet Muhammad.
Awọn alaṣẹ Supreme Ulema Council ni fiimu naa tabuku ẹsin Islam ti ko si naani awọn ohun to ṣe koko ti wọn tọkasi ninu ẹsin Islam naa.
Bakan naa ni ifẹhọnuhan ti waye ni UK, Egypt, Pakistan, Iran ati Iraq lori fiimu naa ti wọn si tabuku rẹ.
Ajọ naa ni fiimu ọhun fari apa kan da ikan si, ti wọn si tun ni awọn to ṣe fiimu naa kan fẹ da ilumọọka ni kiakia ni.
Wọn ni fiimu naa da ọgbẹ si ọkan awọn Musulumi lagbaye, to si le da wahala silẹ kaakiri.
Onimọ nipa ọrọ ẹsin ni BBC, Aleemil Maqbool ni fiimu naa da le awọn ikọ ẹlẹsin Sunni, to si ṣafarawe laarin wọn ati ikọ agbesunmọmi ni Iraq.
Olotu fiimu naa, Malik Shibak ni ko si ohun to buru ninu fiimu ti oun ṣe, ki awọn ẹlẹgan lọ gbẹnu dakẹ.
Bakan naa lo ni kii ṣe gbogbo Musulumi lo n fẹ ki wọn gbegile fiimu ohun.
Lẹyin ifẹhọnuhan ni UK ni awọn ileeṣẹ sinima nibẹ fofin de fun anfaani awọn oṣiṣẹ sinima naa.
Amọ eyi tun fa ibinu, paapaa lati ọdọ awọn musulumi ti wọn fẹ wo fiimu naa.












