A kò bèèrè owó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti fòpin sí gbèǹdéke ìyanṣẹ́lódì – ASUU

ASUU Strike Update: ASUU ní àwọn kò bèèrè ‘crowd funding’ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti wọlé padà

ASUU

Oríṣun àwòrán, Google

Ẹgbẹ awọn olukọ Fasiti ni Naijiria ti ni awọn ti kọ owo ti awọn eniyan kojọ ki wọn le pada si ileẹkọ.

Awọn olukọ Fasiti naa ni wọn bẹrẹ iyanṣẹlodi ni Oṣu Keji lori aisan owo osu wọn ati owo ajẹmọnu wọn.

Lẹyin ti ẹgbẹ ASUU kede pe iyanṣẹlodi naa yoo tẹsiwaju da Oṣu Kẹjọ ni ileeṣẹ Redio Berekete Family Radio wa bẹrẹ si ni beere owo lọwọ awọn ara ilu fun ajọ naa.

Ni Ọjọ Satide ohun ni ileeṣẹ redio naa, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke pe aarẹ ẹgbẹ naa wa si ori eto .

Bi wọn ṣe n ṣe eto naa lọ ni atọkun ti wọn n pe ni ‘Ordinary President' bẹrẹ si ni da owo silẹ, to si sọ pe gomina kan fun wọn ni aadọta miliọnu naira ti awọn si fẹ ko biliọnu mejidinlogun naira jọ fun wọn.

Amọ aarẹ naa gba ẹrọ agbohunsafẹfẹ to si sọ pe awọn ko fẹ owo naa, ki ẹnikẹni ma si da ASUU mọ irufẹ owo bẹẹ.

O ni idi ti awọn fi wa si ori eto naa ni lati kede idi ti awọn fi gunle iyanṣẹlodi.

‘’A ko beere owo lọwọ ijọba apapọ fun ara wa amọ fun awọn fasiti wa kaakiri Naijiria.’’

Lẹyin naa ni ileeṣẹ redio naa kesi awọn eniyan lati fi ‘account number’ wọn ranṣẹ ki wọn le da owo wọn pada.

Amọ awọn to pe si ori eto ni ọjọ naa koro oju si ASUU ati igbeṣẹ wọn naa.

Kini igbesẹ ijọba lori ọrọ iyanṣẹlodi ẹgbẹ ASUU?

Minisita fun ọrọ igbanisiṣẹ ti bẹ ASUU ati awọn ẹgbẹ fasiti yoku lati wọgile iyanṣẹlodi wọn.

O ni idi ti oun fi n bẹbẹ ni ki eto ẹkọ le pada ni awọn fasiti kaakiri Naijiria.

Ngige ni laipẹ ni ijọba yoo bẹrẹ si ni san gbedeke owo osu oṣiṣẹ ti wọn ṣeleri fun wọn kaakiri fasiti ni Naijiria.

Bakan naa lo ni fasiti yoo gba miliọnu mẹtalelogun o le, ti ‘polytechnics’ yoo si gba biliọnu mẹfa naira ti awọn ileẹkọ akọṣẹmọṣẹ yoo gba miliọnu mẹrin naira.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Google

Aṣuwọn owo ti wọn yoo ma a fi san owo fun wọn ni ‘’Integrated Personnel and Payroll Information System (IPPIS) ti ijọba apapọ;

ati ti University Transparency Accountability Solution (UTAS) ti ASUU, ati Universities Peculiar Personnel Payroll System (UPPPS) fun awọn oṣiṣẹ Fasiti ti ki n ṣe olukọ.

Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ naa n bere fun amuṣẹ adehun to wa laarin awọn oṣiṣẹ fasiti ASUU ati ijọba apapọ Naijiria.