Peter Rufai, ogbóntarìgì golí fún Super Eagles, jáde l'áyé

Peter Rufai

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Agba ọjẹ goli fun ikọ agbabọọlu Super Eagles, Peter Rufai ti jade laye.

Rufai, ti ọpọ eeyan mọ si Dodomayana, ni iroyin sọ pe o ku ni owurọ Ọjọbọ, ọjọ kẹta, oṣu Keje, ọdun 2025.

Ajọ NFF kede iku Rufai, loju opo X rẹ ni alẹ Ọjọbọ.

Bo tilẹ jẹ pe BBC Yoruba ko ti i le fidi ohun to pa ogbontarigi agbabọọlu naa, awọn iroyin kan sọ pe o ṣe aisan fun igba pipẹ, ki ọlọjọ to o de.

Ẹni ọdun mọkanlelọgọta ni.

Ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹjọ, ọdun 1963 ni wọn bi Rufai niluu Eko.

Lasiko to fi jẹ agbabọọlu, o ṣiṣẹ ni orilẹede Belgium, Netherlands, Portugal ati Spain, fun ogun ọdun.

Rufai ṣoju Naijiria ni idije World Cup meji, ati ni ọpọ Africa Cup of Nations, AFCON.

Bawo ni Peter Rufai ṣe bẹrẹ bọọlu gbigba?

Ẹgbẹ agbabọọ̀lu Stationery Stores FC ati Femo Scorpions, ni akọsilẹ sọ pe Peter Rufai ti bẹrẹ bọọlu gbigba niluu Eko.

Lẹyin naa lo lọ si Benin lọdun 1986, nibi to ti gba bọọlu fun AS Dragons FC de l'Ouémé.

Yatọ si pe o gba bọọlu ni ilẹ okeere, ẹni ti ko ṣe e fi ọwọ rọ sẹyin l'agbo bọọlu ni Naijiria ni Rufai jẹ.

Igba meji ọtọọtọ lo ṣoju Naijiria ni idije agbaye - ọdun 1994 ati 1998 – gẹgẹ bi aayo goli.

Bakan naa lo tun ṣe iranlọwọ fun Naijiria lati gba ife 1994 African Cup of Nations ni Tunisia.

Peter Rufai

Oríṣun àwòrán, Mark Leech/Getty Images

Ọdun mẹfa ni Rufai fi gba bọọlu ni orilẹede Belgium pẹlu agbabọọlu K.S.C. Lokeren Oost-Vlaanderen ati K.S.K. Beveren.

Lọdun 1994, Peter Rufai darapọ mọ ẹgbẹ agbabọọlu S.C. Farense l'orilẹede Portugal.

Iṣẹ takuntakun rẹ mu ko ni anfaani lati darapọ mọ idije La Liga, to si gba bọọlu fun Hércules.

Rufai pada si orilẹede Spain lọdun 2003 lati fi ṣe ibugbe, to si da ile ẹkọ kan silẹ fun awọn goli.

Peter Rufai, Stephen Keshi ati agbabọọlu Super Eagles kan re e, to n ṣe ajọyọ pẹlu ife African Nations Cup ti wọn gba lọdun 1996.

Oríṣun àwòrán, Shaun Botterill /Allsport/Getty Images

Àkọlé àwòrán, Peter Rufai, Stephen Keshi ati agbabọọlu Super Eagles kan re e, to n ṣe ajọyọ pẹlu ife African Nations Cup ti wọn gba lọdun 1996.