Wọ́n lù mí, kódà wọ́n ya aṣọ mọ́ mi lọ́rùn ní Alaba- Lawal Waheed

Ẹya Igbo to fẹ gba kaadi PVC
Àkọlé àwòrán, Wo ohun to selẹ̀ lórí Fídíò tó ní wọn tako ẹ̀yà Igbo láti gba káàdì PVC lọ́jà Alaba l‘EkoWàhálà Ọ̀tọ̀ ni ǹkan tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ẹ̀yà Igbò fẹ́ gba káàdì INEC

A tun ti gbe ise wa de lori ikanni yi nipa titan imọlẹ si iroyin to ba ruju lawujọ wa ni Naijiria tabi nibomiran.

Lọtẹ yi, ohun taa fẹ gbe yẹwo ni iroyin to gbode pe awọn kan n kọdi awọn ẹya Igbo lati le forukọsilẹ gba kaadi idibo PVC ni ọja Alaba ni ipinlẹ Eko.

Ninu fọnran fidio kan ni ọrọ yi ti ṣebi ẹni jade.

Kini nkan taa mọ nipa rẹ? Ṣe lootọ ni abi iroyin ofege leleyi naa?

Alaye ree:

Ìwádìí BBC rèé lórí Fídíò tó ní wọn tako ẹ̀yà Igbo láti gba káàdì ìdìbò PVC

Ki ni o han siwa ninu fidio naa?

Ninu fidio yi nkan taa ri ni pe awọn eeyan kan n sọ ni ileeṣẹ́ INEC to wa ni Igbede ijọba ibilẹ Ọjọọ ni Eko pe wọn ko jẹ ki awọn forukọsilẹ gba kaadi idibo PVC notori pe awọn jẹ ẹya Igbo.

Ẹya Igbo yi jẹ ọkan lara awọn ẹya orileede Naijiria to wa ni iha Guusu ilẹ naa.

Ni ọja ilumọọka nii, ọja Alaba ni iṣẹlẹ yi si ti waye.

Awọn oniṣowo ẹya Igbo pọ ni ọja yi daadaa.

Loju opo Twitter ni paapa lawọn eeyan ti n ṣe alabapin fidio lori ọrọ yi ti onikaluku si n sọ ohun to ro nipa iṣẹlẹ naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 2

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

A gbọ ninu fidio kan tawọn eeyan to n kọja si n sọrọ lede Igbo pe ''se awọn eeyan to n ja ninu ọfisi INEC lagbara lati ja ni?

Ṣugbọn o ṣoju mi koro sọ fun BBC pe wahala to waye ko niṣe pẹlu pe oṣiṣẹ INEC ko jẹ ki awọn eeyan forukọsilẹ nitori ẹya wọn.

Ọkan lara awọn taa ba sọrọ, Chinaza Ikemeziem, sọ pe nkan to da ija silẹ nipe awọn eeyan kan yari pe ki awọn oṣiṣẹ INEC ma gbe irinṣẹ iforukọ́silẹ wọn kuro ninu ọfisi naa.

''Ohun to ṣẹlẹ ko ṣẹyin pe awọn ero pọ.

Wọn ti ọja Alaba tori ki awọn eeyan baa le jade wa gba kaadi idibo.

Ẹgbẹgbẹrun lawọn to tu sita ti ipa awọn oṣiṣẹ INEC ko si kawọn.

Ohun to fa wahala nibi oṣiṣẹ INEC kan se wa lati gbe irinṣẹ iforukọsilẹ lọ si ibomiran ti wọn ti n ṣe iforukọsilẹ.

Awọn to wa nibẹ yari fun wọn ibẹ si ni wahala ti bẹrẹ''

Arabinrin Ikemesiem lo ṣalaye ọrọ yi fun BBC.

O ni ṣaaju ki wahala naa to waye, ko si ede aiyede kankan to niiṣe pẹlu ọrọ ẹlẹyamẹya.

''Ẹrọ iforukọsilẹ kan ṣoṣo lo wa nibẹ awọn to si wa forukọsilẹ ko fẹ ki wọn gbe lọ ni nkan to ṣẹlẹ''

Chinaza Ikemeziem ati Lawal Waheed

Arakunrin Lawal Waheed, ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ sọ fun BBC pe awọn eeyan doju ija kọ oun nigba toun fẹ daabo bo oṣiṣẹ INEC taa n wi yi.

''O ni awọn irinṣẹ kan ti awọn oṣiṣẹ INEC maa n gbe lọ si awọn adugbo miran kawọn ti ko ba raaye lati wa si ọfiisi wọn naa baa le ribi forukọsilẹ''

O ni iru nkan bayii ko ṣẹṣẹ maa waye nibi tawọn to ba wa forukọsilẹ yoo yari pe wọn ko gbọdọ gbe awọn irinṣẹ yi lọ ayafi bi wọn ba forukọ ti wọn silẹ ṣaaju.

''Gbogbo alaye ti wọn ba n ṣe fun wọn pe ibomiran lawọn ti fẹ lọ lo awọn irinṣẹ yi kii wọ awọn eeyan yi leti.

Wọn kọlu oṣiṣẹ INEC ọkunrin kan ṣugbọn ẹni keji rẹ to jẹ obinrin ribi gbe ọkada sa mọ wọn lọwọ''

O ni koda wọn lu oun ti wọn si ya aṣọ mọ oun lọrun nigba toun fẹ gba oṣiṣẹ Inec yi lọwọ wọn.

''Wọn tun lu baalẹ kan lagbege naa eleyi to mu ki awọn ọdọ adugbo ọhun naa wa das i ọrọ to fi di gbas gbos laarin wọn.

Arakunrin Waheed ni awọn eeyan kan n sọ pe bawo ni ẹrọ iforukọsilẹ yoo ṣe wa nibi ti wọn ko si ni jẹ ki awọn ẹya Igbo forukọsilẹ.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye o ni ko si ohun to jọ bẹ to waye nitori ẹya tabi idi miran ju eleyi toun tio ṣalaye lọ.

Skip X post, 3
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 3

Ẹwẹ aarẹ awọn oniṣowo to n ta ẹrọ ilo ile ni ọja naa Paulinus Ugochuwu ti paṣẹ pe ki wọn ti ọja naa lọjọ kan si ki awọn ọlọja baa le ribi gba kaadi idibo wọn.

Bakan naa ni ajọ eleto idibo lorileede Naijiria INEC ti sọ pe awọn mọ inira taraalu n koju ni paapa lori gbigba kaadi idibo ọlọjọ pipe.

Ọga INEC to n risi idanilekọ araalu,Festus Okoye lawọn ti fi ẹrọ iforukọsile mii sita lawọn ipinlẹ maraarun to wa ni ila oorun Guusu Naijiria ,Eko ati Kano nibi ti ero ti pọ.

Iye ẹrọ to lawọn ko si ta si jẹ mọkandinlaadọfa.

O tẹsiwaju pe awọn yoo sayewo bi nkan ba se n lọ lati mọ igbese to kan.