Ẹgbẹ́ òṣèlú tó bá yan olùdíje ààrẹ àti igbákejì rẹ̀ nínú ẹ̀sìn kan ṣoṣo yóò kùnà - CAN

Atiku ati Tinubu

Oríṣun àwòrán, BAT

Ẹgbẹ ọmọlẹyìn kristi lorileede Naijira CAN ti fariga pe awọn lodi si ki ẹgbẹ oloṣelu kankan yan oludije ipo ààrẹ ati igbakeji labẹ tíkẹ́ẹ̀tì ẹlẹsin kanna.

 Wọn ni eyikeyi ẹgbẹ to bá ṣe iru eleyi yoo kuna ni.

 Ọrọ yi jẹyọ ninu atẹjade kan ti akọwe ẹgbẹ naa Joseph Bade Daramola fi sita.

 O ni awọn ki awọn to jawe Olubori ninu idije idibo abẹnu to yan oludije ipo ààrẹ labẹ asia ẹgbẹ ṣugbọn awọn fẹ fi to awọn ẹgbẹ yi leti pe patapata l'awọn tako yiyan Musulumi ati Musulumi tabi Kristeni ati Kristeni gẹgẹ bí aarẹ ati igbakeji Ààrẹ ninu tikẹẹti ẹgbẹ wọn ni 2023.

 Igba àkọkọ kọ ni yi ti CAN yoo maa fi ikilọ yi si'ta fawọn ẹgbẹ oṣelu ni Naijiria.

 Ikilọ eleyi sí n waye lẹyìn ti iroyin gbòde pé oludije ẹgbẹ oṣelu APC fun ipo ààrẹ Bola Ahmed Tinubu n gbero lati yan igbakeji musulumi.

 Ìkọ Tinubu ti sọ pe ko sí ootọ ninu iroyin boti lẹ jẹ pe ko ti sọ pato ẹni tí yoo yan.

 Ati Tinubu àti Atiku Abubakar l,oludije ipo ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party to jẹ ẹgbẹ alatako, musulumi láwọn mejeeji.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Nítorí kini CAN ṣe fariga?

 Atẹjade lati ọdọ CAN mẹnu ba awọn alaye kan gẹgẹ bí eredi tàwọn ko fi faaye gba tikẹẹti ẹlẹsin kanna.

 Ninu ọrọ rẹ akọwe kan mu akawe awọn iṣẹlẹ to ti waye sẹyìn tó sì ni láwọn ìgbà tí ẹgbẹ oloṣelu yan oludije ẹlẹsin kanna nkan ko rọgbọ fawọn ọmọlẹyìn kristi ni Nàìjíríà.

 Ni paapa CAN ni iru igbesẹ yi yoo mu kí alaafia Naijiria ti ko f'ẹsẹ múlẹ daada tẹlẹ "wa nínú ewu nla"

 CAN sọ pe awọn oloṣelu lè máa ṣọ ọrọ oṣelu ṣugbọn awọn kò faramọ tikẹẹti ẹlẹsin kanna tori pe ẹgbẹ to bá ṣe bẹẹ yóò kùnà ní.

"Eleyii kìí ṣe ọdún 1993"

 1993 ti wọn mẹnu ba yi ni igba ti oludije ààrẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party ,MKO Abiola yan Baba Gana Kingibe gẹgẹ bi igbakeji rẹ tí aráàlú sí dibo fún wọn.

 Ninu àkọsílẹ itan òṣèlú eleyii lo fẹ ẹ jẹ igba kan táa rí ti tikẹẹti ẹlẹsin kanna waye.

 Laipẹ yi,Gómìnà ipinlẹ Kaduna Nasir El-Rufai yan igbakeji musulumi ti eleyi ko sí dùn mọ awọn Kristiẹni ipinlẹ naa ninu.

 Gẹgẹ bi CAN ṣe sọ," koda ki a ní tikẹẹti Musulumi ati Kristiẹni, iya ṣi máa njẹ awọn ọmọlẹyìn Kristi ni Naijiria.Olorun nikan lo mọ iye àwọn Kristẹni tí wọn ti pa ti nkankan ko si ṣẹlẹ sí awọn to p'awọn tabi ki wọn sì pe wọn lẹjọ"

Ni bayii CAN ti wa la kalẹ pe igbakeji ti Bola Tinubu ẹgbẹ APC bá yan gbọdọ jẹ Kristẹni lati ariwa Naijiria.

Atiku Abubakar PDP naa gbọdọ yan igbakeji Kristẹni lati iha Guusu Naijiria.

 Peter Obi ẹgbẹ Labour Party naa sì gbọdọ yan igbakeji lati Ariwa Naijiria ko sí jẹ musulumi.

 Ohunkohun to ba yatọ sí eleyi gẹgẹ bi wọn ṣe sọ tunmọ sí pé àwọn ẹgbẹ yi ko nifẹ si isọkan ati alaafia Naijiria ni.

 Labẹ ofin ko si ohun tó takò pe ki oludije ààrẹ yan igbakeji to ba wu.

 Lọpọ ìgbà awọn oloṣelu maa n wo iwoye yiyan igbakeji ti yóò jẹ kí wọn lè gbegba oroke ninu idibo ṣaaju boya o jẹ ẹlẹsin kan tabi omiran.

 Nítorí pé Naijiria jẹ orileede ti ẹlẹya mẹya ati ẹlẹsinmẹsin,iru tikẹẹti ti ẹgbẹ ba yan maa n kopa ninu boya wọn yóò dé ori ipo.

 Amọ ṣa kò sí aridaju pe yiyan ẹlẹsin ọtọọtọ le mú kí ìṣèjọba mu anfaani ba araalu.

 Labẹ ìjọba tó kọjá ati eleyi to wa níbẹ ati musulumi ati Kristẹni ní ìnira n ba ni paapa lọwọ awọn agbesunmọmi ajinigbe ati awọn ti n dunkoko mọ alaafia orileede Naijiria.

 Ni eleyi to fẹẹ sunmọ ootọ, awọn to n ṣé àkóbá fún araalu yala nipa iwa ajẹbanu tabi akoso ti ko gunrege, ẹlẹsin musulumi ati Kristẹni lapapọ lo pọ ninu wọn.

Wo gbèdéke tí àwọn olùdíje Ààrẹ ní láti yan igbákejì wọn
Atiku Abubakar , Bola Tinubu, Peter Obi, ati Rabiu Kwankwaso

Oríṣun àwòrán, Daily Post

Àkọlé àwòrán, Atiku Abubakar , Bola Tinubu, Peter Obi, ati Rabiu Kwankwaso

Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ti fun gbogbo awọn to fẹ dije fun ipo aarẹ lọdun 2023, ni gbedeke lati yan igbakeji wọn.

Alaga ajọ INEC, Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, kede ninu atẹjade kan pe Ọjọru, ọjọ kẹtadindogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2022, ni gbedeke fun wọn.

Nigba ti tawọn gomina jẹ ọjọ kẹẹdogun, oṣu Kẹfa.

Ọjọgbọn Yakubu sọ pe ẹgbẹ kọọkan gbọdọ fi orukọ oludije wọn ranṣẹ titi ọjọ gbedeke naa, pẹlu orukọ igbakeji wọn.

“Awọn to fẹ dupo aarẹ ati gomina gbọdọ fi orukọ wọn ranṣẹ pẹlu ti ẹni ti yoo jẹ igbakeji wọn. Lai ṣe bẹẹ, iyansipo wọn gẹgẹ bi oludije ẹgbẹ wọn ko fẹsẹ mulẹ.”

Bakan naa lo tun ṣalaye pe oju opo ayelujara ajọ INEC, ni wọn gbọdọ kọ gbogbo rẹ si, ki wọn o to ti oju opo naa pa ni aago mẹfa irọlẹ ọjọ gbedeke kọọkan.

Titi di asiko yii, ko si oludije fun ipo aarẹ to tii kede orukọ igbakeji rẹ.

Fun oludije ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party (PDP), Atiku Abubakar, ẹkun Gusu Naijiria ni ireti wa pe yoo ti yan igbakeji rẹ, nitori pe Ariwa ni oun ti wa.

Bakan naa lo ri fun oludije ẹgbẹ New Nigeria Peoples Party (NNPP), Rabiu Kwankwaso.

Ṣugbọn fun alatako rẹ lati inu ẹgbẹ osẹlu All Progressives Congress (APC), Bola Ahmed Tinubu, Ariwa ni ireti wa pe oun yoo ti yan tiẹ.

Bakan naa ni fun oludije ẹgbẹ Labour Party, Peter Obi.

Iha Gusu ni awọn mejeeji ti wa.