Ọmọọba ní èmi náà, mo sì lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ Aláàfin - Bíṣọ́ọ̀bù Ladigbolu

O ti foju han gbangba bayii pe ifigagbaga lati yan ẹni ti yoo gun itẹAlaafin tilu Oyo ti de oju ọgbagade bayii.
Lọwọlọwọ, idile ọba Agunloye to kan lati fi orukọ awọn ọmọ oye to n dije lati de ipo Alaafin sọwọ, ti fi orukọ eeyan mejidinlaadọta ransẹ si olori awọn ọmọ ọba ti wọn n pe ni Baba Iyaji, tii se olori ọmọ ọba, Mọgaji Mukaila Afonja.
Lara awọn gbajumọ to wa ninu awọn ọmọ oye to fẹ jẹ Alaafin ni Bisọọbu Ayo Ladigbolu.
Nigba to n fidi okodoro ọrọ yii mulẹ fun BBC Yoruba, ọmọọba Ayo Ladigbolu ni bi wọn se kede ọrọ naa lo ri.
“Wọn ko le pa irọ iru nnkan bẹẹ mọ eeyan, ti wọn ba ni orukọ mi wa ninu awọn ti yoo jẹ Alaafin, gbagbọ pe bẹẹ lo ri.
Ọmọọba naa ni emi naa, mo si lẹtọ lati jẹ Alaafin”
Bisọọbu agba ni ijọ eleto, Methodist to ti fẹyin ti, ni ọmọọba Ayo Ladigbolu, tii se ẹni ọdun mẹrinlelọgọrin.
Ọmọọba ni baba Ladigbolu lati idile oye Agunloye, to si sun mọ Alaafin to gbesẹ bi isan ọrun.
Nigba to n gbe iwe ẹbẹ awọn ọmọ oye kalẹ siwaju Baba Iyaji, Olori idile Agunloye, alagba Samuel Adeladan ni gbogbo awọn ọmọ oye naa ni wọn wẹ, yan kain-kain.
O ni ọmọ ọba to poju owo ni gbogbo wọn, ti wọn si ti laami laaka ninu awọn isẹ ti wọn yan laayo.
Olori idile Agunloye ni ẹka ile marun to wa labẹ agboole naa ni awọn ọmọ oye to fẹ jẹ Alaafin yii ti wa.

Oríṣun àwòrán, screen shot
Fọ́nrán kan lo ti gbòde wí pé ọkọ̀ ńlá méjì tí àwọn Fulani kún inú rẹ̀ ti ya wọ Ikere Ekiti, ìpínlẹ̀ Ekiti pẹ̀lú àwọn ohun ìjà ní oríṣiríṣi àti ìbọn.
Èyí sì ti ń dá inú fu àyà fu kalẹ̀ sí ara ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn pàápàá nítorí ìkọlù tí àwọn agbébọn ṣe ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣọṣẹ́ ní ilé ìjọsìn Aguda St Francis, Owaluwa ìlú Owo, ipínlẹ̀ Ondo ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹfa, ọdún 2022.
Níbi ìkọlù náà ni àwọn agbébọn náà ti gba ẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí iye wọ́n gẹ́gẹ́ bí ilé ìjọsìn náà ṣe wí lé ní ọgbọ̀n, tí ọ̀pọ̀ náà sì farapa tí wọ́n ṣì ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́ ní ilé wòsàn.
Nínú àtẹ̀jáde kan tó wà lórí fọ́nrán tó gba orí ayélujára kan, àwọn ènìyàn ni lọpẹ́lọpẹ́ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò Amotekun àti OPC tó dínà mọ́ àwọn Fulani náà tí kò jẹ́ kí wọ́n rí ààyè wọ ìlú Ikere Ekiti.
Wọ́n ní nígbà tí ikọ̀ Amotekun àti OPC tú àwọn ọkọ̀ méjéèjì yìí, àwọn nǹkan ìjà ogun ni àwọn Fulani náà kó kún inú ọkọ̀ tí wọ́n sì fi koríko bò wọ́n mọ́lẹ̀.
Fọ́nrán náà ló ti ń tàn ká orí ẹ̀rọ WhatsApp.
Kí ni ó wà nínú fọ́nrán yìí?
Ohun tó wà nínú fọ́nrán tó tẹ BBC News Yorùbá lọ́wọ́ ṣàfihàn ibi tí OPC ti dá àwọn ènìyàn kan dùbúlẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣàyẹ̀wò ọkọ̀ ńlá akẹ́rù kan.
Nínú ọkọ̀ náà la ti rí ọkùnrin kan tó ń tú ẹru tí ẹ̀ṣọ́ OPC sì dúró tìí láti mọ ohun tó wà nínú ẹrù tó ń tú.
Bákan náà la rí àwọn ènìyàn tí wọ́n wà ní ìdùbúlẹ̀ tí ẹ̀ṣọ́ màáràn sì dúró tì wọ́n ṣùgbọ́n a kò le fìdí rẹ̀ múlẹ̀ bóyá wọ́n bá ohun ijà ogun tàbí nǹkan olóró nínú ọkọ̀ ńlá náà.
Àwọn ọ̀dọ́ tó ń sọ̀rọ̀ lábẹ́lẹ́ nínú fọ́nrán ọ̀hún ni àwọn kò ní fún àwọn Fulani náà ní ààyè láti wá ṣọṣẹ́ tàbí wùwà láabi gẹ́gẹ́ bó ṣe wáyé ní ìlú Owo láìpẹ́ yìí.
Wọ́n ní kò ní sí ààyè fún àwọn oníṣẹ́ ibi láti gba ìlú Ikere Ekiti kọjá débi tí wọn yóò rí ààyè dúró nínú rẹ̀.

Oríṣun àwòrán, WhatsApp
Kí ni iléeṣẹ́ ọlọ́pàá sọ?
Àtẹ̀jáde tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá fi léde lórí ẹ̀rọ Twitter ní ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹfà ọdún 2022 fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé lóòótọ́ ni àwọn ọ̀dọ́ kan dá àwọn ènìyàn kn tó fẹ́ ya wọ ìlú Ikere Ekiti lọ́jọ́ Keje, oṣù Kẹfà, ọdún 2022.
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ènìyàn náà kò ju ogun lọ lòdì sí bí àwọn ènìyàn ṣe ń gbe kiri pé wọ́n kún inú ọkọ̀ ńlá akẹ́rù méjì.
Àtẹ̀jáde náà ni àwọn ọ̀dọ́ ọ̀hún wá fi ọ̀rọ̀ náà tó iléeṣẹ́ ọlọ́pàá létí tí àwọn sì jí gìrì sí ojúṣe àwọn nípa ṣíṣe àyẹ̀wò àwọn ọkùnrin ọ̀hún àti wọn.
“Gbogbo ọkọ̀ wọn la gbọ̀n yẹbẹyẹbẹ àmọ́ a ò bá ohun ìjà kankan tàbí ohun tó le kóbá ènìyàn nínú rẹ̀.”
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ri dájú pé àwọn sin àwọn Fulani náà kúrò nínú Ikere Ekiti ṣùgbọ́n kìí ṣe wí pé àwọn bá ohun ìjà ogun kankan lọ́wọ́ wọn gẹ́gẹ́ bó ṣe gba orí ayélujára.
Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ní àwọn Fulani náà ni kìí ṣe ìlú Ikere Ekiti gan ni àwọn ń lọ, àwọn kàn ń kọjá ni.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post















