Wo ọ̀pọ̀ ìròyìn òfégè tó gba ìgbòrò lórí ìkọlù agbébọn ní Owo

Àwòrán àwọn tọkọtaya tó gba orí ayélujára àti

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Onírúurú àhesọ ọ̀rọ̀ àti ìròyìn ló gba orí ẹ̀rọ ayélujára kan lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìkọlù àwọn agbébọn sí ilé ìjọsìn St Francis Owaluwa, Owo, ìjọba ìbílẹ̀ Owo ní ìpínlẹ̀ Ondo.

Ní ọjọ́ Àìkú ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹfa ní àwọn agbébọn yawọ ilé ìjọsìn St Francis lásìkò tí ìjọsìn ń lọ lọ́wọ́ tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀.

Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà tí àwọn mìíràn sì farapa yánnayànna tó fi mọ́ àwọn ọmọdé àti àwọn obìnrin.

Ìkọlù yìí ṣokùnfà oríṣiríṣi awuyewuye lórí ayélujára níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti ń fi ìbànújẹ́ wọn hàn lórí ipò tí ètò ààbò orílẹ̀ èdè Nàìjíríà wà.

Bákan náà ni àwọn mìíràn lo àǹfàní náà láti gbé àwọn ìròyìn irọ́ lórí ohun tí kò ṣẹlẹ̀ ṣùgbọ́n tí wọ́n ló ṣẹlẹ̀ nítorí ìkọlù náà.

Lára àwọn ìròyìn irọ́ èyí tí ẹ̀ka tó ń mójútó ìròyìn òfégè ní BBC ṣe àkójọ wọn lórí ìkọlù àwọn agbébọn náà nìyí:

Àwọn tọkọtaya tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbéyàwó tí wọ́n ní wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn

Àwòrán àwọn tọkọtaya tó gba orí ayélujára

Oríṣun àwòrán, Twitter

Lára àwọn ìròyìn tó da omi tútù sí àwọn ènìyàn lọ́kàn ní ìròyìn àwọn tọkọtaya tí wọ́n ní wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbéyàwó ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrin kí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà tó wáyé lọ́jọ́ Àìkú.

Ìròyìn tó gba ìgbòrò ni pé àwọn tokọtaya náà lọ sí ilé ìjọsìn St Francis fún ìdúpẹ́ ètò ìgbéyàwó ṣùgbọ́n wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìkọlù náà.

Ẹ̀wẹ̀, lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí àwọn ènìyàn ti ń gbé ìròyìn náà lórí ayélujára ni fọ́nrán obìnrin kan tó pe ara rẹ̀ ní ìyàwò náà gbòde pé lóòótọ́ ni àwọn lọ sí ilé ìjọsìn fún ìdúpẹ́ àmọ́ àwọn ti kúrò kí ìṣẹ̀lẹ̀ laabi yìí tó wáyé.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé BBC kò le fìdí rẹ̀ múlẹ̀ dájú pé bóyá obìnrin tí wọ́n ń gbé àwòrán òun àti ọkọ́ rẹ̀ lórí ayélujára pé wọ́n ti jáde láyé náà ni obìnrin tó wà nínú fọ́nrán náà.

Àmọ́ ìwádìí lẹ́nu akọ̀wé ilé ìjọsìn St Francis, Joseph Oladimeji sọ fún BBC pé lóòótọ́ ni àwọn tọkọtaya náà wá sí ilé ìjọsìn fún ìdúpẹ́ ní ọjọ́ ṣùgbọ́n wọ́n ti kúrò kí àwọn oníṣẹ́ ibi náà tó dé.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Ọlọ́pàá Togo

Ìròyìn òfégè mìíràn nípa ìṣẹ̀lẹ̀ ikọlù náà ni tí ọlọ́pàá kan tí wọ́n ní ó nawọ́ gán ọ̀kan lára àwọn afurasí tó le ṣe ìkọlù sí ilé ìjọsìn St Francis.

Nínú fọ́nrán tó gba ayélujára ní èyí tó ṣàfihàn ọlọ́pàá kan tó ń gba ìbọn AK-47 lọ́wọ́ afurasí kan.

Ìwádìí fi hàn wí pé kìí ṣe ọ̀kan lára àwọn afurasí tó ṣọṣẹ́ ní ìlú Owo ló wà nínú fọ́nrán náà àti pé ẹnìkan ló ti fi fọ́nrán náà sórí Twitter ṣaájú kí ìṣẹ̀lẹ̀ ìlú Owo tó wáyé.

Kìí ṣe ọlọ́pàá Nàìjíríà ló wà nínú fọ́nrán náà, Lome ni orílẹ̀ èdè Togo ni ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún gan ti wáyé.

Igbákejì Ààrẹ ní ìjàmbá ọkọ̀

Ní ọjọ́ Kejì tí àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí ìlú Owo, ti àwọn ọmọ Nàìjíríà ṣe ń ṣọ̀fọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ láabi lọ́wọ́ ni ìròyìn tún gba orí ayélujára pé igbákejì Ààrẹ Yemi Osinbajo ní ìjàmbá ọkọ̀.

Kódà iléeṣẹ́ ìròyìn orí ayélujára kan tilẹ̀ gbe ní ìròyìn yàjóyàjó kí agbẹnusọ Osinbajo, Laolu Akande tó ní irọ́ ni ìròyìn náà.

Akande ni àwọn ń lọ sí pápákọ̀ òfurufú láti lọ bá àwọn ènìyàn ìlú Owo kẹ́dùn ni àwọn rí àwọn tó ní ìjàmbá ọkọ̀ lọ́nà tí àwọn sì dúró láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

Yàtọ̀ sí àwọn wọ̀nyí, àwọn kan tún gbe kiri pé àwọn agbébọn tún ṣe ìkọlù sí ẹ́sítéètì Gwarimpa ní ìlú Abuja ṣùgbọ́n àwọn ara agbègbè náà ti ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni ìròyìn náà.

Skip X post, 4
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 4

Gbogbo bí àwọn ìròyìn òfégè ṣe ń gba ìgbòrò kan lásìkò yìí ti ń fa kí àwọn èniyàn máa bèrè pé kí ló dé tí àwọn iléeṣẹ́ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ kìí ṣe ìwádìí wọn dada kí wọ́n tó gbé ìròyìn jáde.

Skip X post, 5
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: The BBC is not responsible for the content of external sites.

End of X post, 5