Tinubu mókè nínú ìbò abẹ́nú APC, ó di olùdíje ààrẹ fẹ́gbẹ́

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Ẹgbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC ti kéde Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bí ẹni tó jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò abẹ́nú láti yan olùdíje tí yóò gbé àsíá ẹgbẹ́ náà dání láti díje dupò Ààrẹ lọ́dún 2023.
Tinubu tó ni ìbò ..... tí Rotimi Amaechi sì gba ipò kejì pẹ̀lú ìbò 316.
Ètò ìdìbò abẹ́nú náà ló bẹ̀rẹ̀ láti àná ọjọ́ Keje, oṣù Kẹfà, ọdún 2023 ní Eagles Square, Abuja.
Tinubu, igbákejì Ààrẹ Ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo, Rotimi Amaechi, Rochas Okorocha, Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi, Yahaya Bello, Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà, Ahmed Lawan àti àwọn olùdíje mìíràn ni wọ́n jọ wàákò níbi ètò ìdìbò náà.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn gómìnà ẹgbẹ́ òṣèlú APC gbìyànjú láti ri dájú pé wọ́n dín àwọn olùdíje tí yóò kópa nínú ètò ìdìbò náà kú sí mẹ́ta àwọn olùdíje kan bíi Yahaya Bello fárígá.
Wọ́n ní àwọn kò gbà láti fẹnukò sórí olùdíje kan ṣoṣo gẹ́gẹ́ bí Ààrẹ Muhammadu Buhari ṣe gba gbogbo àwọn olùdíje náà lámọ̀ràn.
Àmọ́ nígbà tí ètò ìdìbò náà yóò fi bẹ̀rẹ̀, àwọn olùdíje bíi gómìnà ìpínlẹ̀ Ekiti, Kayode Fayemi, gómìnà tẹ́lẹ̀ rí ní ìpínlẹ̀ Ogun, Sénétọ̀ Ibikunle Amosun, gómìnà ìpínlẹ̀ Jigawa, Muhammad Badaru juwọ́lẹ̀ fún Asiwaju Bola Ahmed Tinubu.
Bákan náà ni obìnrin kan ṣoṣo tó ń kópa nínú ìdíje náà, Uju Ohanenye, Abẹnugan tẹ́lẹ̀ rí ní ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin, Dimeji Bankole àti Ajayi Boroffice náà ni kí àwọn ènìyàn àwọn dìbò fún Asiwaju Tinubu.
Iye ìbò tí àwọn olùdíje kọ̀ọ̀kan ní nìyí:
Bola Ahmed Tinubu - 1271
Yemi Osinbajo - 235
Yahaya Bello – 47
Ahmed Lawan – 152
Rotimi Amaechi – 316
Badaru Abubakar
Godswill Akpabio
Ibikunle Amosun
Tein Jack -Rich
Chukwuemeka Nwajiuba - 1
Christopher Onu - 1
Nweze Umahi
Rochas Okorocha
Ben Ayade - 37
Tunde Bakare - 0
Sani Yerima - 4
Ken Nnaman-
Felix Nicholas
Uju Ken-Ohanenye
Kayode Fayemi
Dave Umahi 38
Ikeobasi Mokelu - 0

Kò sì ẹni tí láàkayè rẹ̀ pé tó ti bàbá mi Tinubu nínú àwọn tí wọ́n ń dupò Ààrẹ - Iyaloja ìlú Èkó
Iyaloja ìlú Eko, Folashade Tinubu-Ojo ni bi awọn kan ṣe n sọ kiri pe ìlera Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ko gbe ipò Aarẹ orile-ede Naijiria ni ko boju mú nítorí pe ọpọlọ ni yoo o fi tukọ to ba di Aarẹ. Folashade lọ soro yìí nígbà tí BBC News Yoruba n baa sọrọ nibi eto ìdibo abẹle ẹgbẹ oselu All Progressive Congress niluu Abuja. O ni ti a ba woo, ẹni tí o ba ni ilera ti o peye ko le maa bọ lati ilu kan sì omii lati kede erongba rẹ lati di Aare orile-ede Naijiria .
"Awọn onisọkusọ onibajẹ ni wọn n sọ kiri pe Bola Ahmed Tinubu ko ni agbara lati ṣe ipo Ààrẹ.
"Gbogbo enu ni mo fi sọ, ninu gbogbo awọn ti wọn jọ dije, ko si ẹni ti laakaye rẹ pe to tí Asiwaju Bola Ahmed Tinubu." Bakana ni iyaloja ni bi foomu ẹgbẹ oselu APC ṣe gbowo lori lo jẹ ifaseyin fun ọpọlọpọ awọn obinrin lati kede erongba wọn fun ipo kan tàbí omiiran. "Ara idi ti obìnrin o fi kopa ninu eto ìdibo ni bi owo foomu ṣe gbowo lori nítorí ọpọlọpọ obìnrin ni olowo eti aṣọ." "Ṣugbọn ti a ba wo ìṣàkóso Asiwaju Bola Ahmed Tinubu ni Ipinlẹ Eko nígbà tí wọn jẹ Gomina, awọn ni Gomina akoko ti o yan obìnrin gege bí igbakeji."















