Owo Church Attack: Tinubu, Osinbajo ṣàbẹ̀wò sílé ìjọ́sìn tí agbébọn kọlù, wón ni ọwọ́ ìjọba yóò tẹ àwọn apààyàn naa
Tinubu kéde ẹ̀bùn owó ₦75m lórí ìkọlù Owo

Gomina ana ni Ipinlẹ Eko, Bola Ahmed Tinubu ati Igbakeji Aare Yemi Oshinbajo ti ṣabewo ibanikedun si ile ijọsin aguda St Francis ni ilu Owo.
Abẹwo naa lo waye lẹyin ikọlu tí awọn agbebon se si ile ìjọsìn naa lọjọ Aiku, ti ọpọlọpọ ẹmi si ba iṣẹlẹ naa lọ.
Bola Ahmed Tinubu, nigba ti o sabewo si ile ìjọsìn naa ni ohun ìbanuje ni iṣẹlẹ naa fun orile-ede Naijiria.
Tí ẹ̀yin gómìnà bá fọwọ́ lẹ́rán, Yorùbá yóò já fún ara wọn - Ooni
Tinubu ni o fun awọn ti o farapa ati Molebi awọn ti wọn ba isele naa lọ ni aadọta milionu ati pẹlu milionu medogbon fun ile ìjọsìn St Francis Catholic Church.
Ninu iforowero rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Tinubu ni iṣẹlẹ naa ni o jẹ ohun ìbanuje ayeraye fun orile-ede Naijiria.

Ninu iforowero rẹ pẹlu BBC News Yoruba, Tinubu ni iṣẹlẹ naa ni o jẹ ohun ìbanuje ayeraye fun orile-ede Naijiria.
O si ro ẹnikẹ́ni to ba mọ iroyin nípa awọn onisebi naa lati mase bẹru lati tí fi to ile ise olopaa leti.
"Oro Ọlọ́run nìkan la le ba awọn to farapa ati mọlẹbi awon ti o ba isele naa lọ sọ, kí Ọlọ́run duro tí awọn molebi naa.
"Ẹnikẹni ti o ba ni ìròyìn nípa àwọn agbebon naa, kí wọn mase bẹru lati fi to Ile ise olopaa leti."
Oludije aarẹ labẹ ẹgbẹ oselu APC naa wa gbadura pe ki Ọlọ́run duro tí awọn ti o farapa ati Molebi awọn ti o ba isele naa lọ.

Awọn agbebọn yoo ri ija ofin laipẹ - Yemi Osinbajo
Igbakeji Aare Yemi Oshinbajo, ninu oro rẹ ní ìjọba orile-ede Naijiria ni ko sinmi lati dẹkun awọn iwa ibaje ati iwa agbebon ti o ti di tọrọ fọn kale ni ayika wa.
Igbakeji Aare ni ijọba rí pe awọn agbebon ni o ri ija ofin laipe.
Tinubu ati Igbakeji Aare ni o gbera kuro ni Abuja nibi ti eto ìdibo abele ẹgbẹ oselu APC ti n waye.
Wọn si wa darapo mo gomina ipinle Ondo, Rotimi Akeredolu ati Olowo ti ilu Owó, Oba Ajibade Gbadegesin Ogunoye, lati se ibanidaro lori isele naa.

"Mo pàdánù àbúró mi àti ọmọ rẹ̀ nínú ìkọlù ṣọ́ọ̀ṣì ní Owo"

Ọjọ́ tí àwọn ènìyàn ìlú Owo, ìjọba ìbílẹ̀ Owo ìpínlẹ̀ Ondo kò ní gbàgbé ní ìgbé ayé wọn ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹfà ọdún 2022.
Nítorí ìkọlù tí àwọn agbébọn ṣe sí ilé ìjọsìn St Francis tó wà ní Owaluwa níbi tí wọ́n ti gbẹ̀mí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn tó fi mọ́ àwọn ọmọdé.
Títí di àsìkò tí à ń kó ìròyìn yìí, kò ì tíì sí ìròyìn pé iye ènìyàn báyìí pàtó ló bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ ṣùgbọ́n iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ní ìwádìí ń lọ lọ́wọ́.
Arákùnrin kan, Cletus Okafor tí àbúrò rẹ̀ àti ọmọ àbúrò rẹ̀ bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní òun gbá ìpè wí pé àwọn agbébọn ti pa àbúrò òun àti ọmọ rẹ̀.

Ó ní nígbà tí òun yóò fi dé ilé ìjọsìn ọ̀hún òkú àwọn méjééjì ni òun bá pẹ̀lú ọta ìbọn lára.
Ó ṣàlàyé pé òun bá ojú ọta ìbọn ní ẹsẹ̀ àti àyà àbúrò òun ṣùgbọ́n orí àti ẹsẹ̀ ni wọ́n ti yìbọn mọ́ ọmọ rẹ̀.
“Nígbà tí mo dé ibẹ̀ ni mo pe ọkọ̀ láti bámi gbé òkú wọn lọ sí ilé ìgbókùúpamọ́sí.”
Ẹlòmíràn tí òun náà farapa, Alex Micheal sọ fún BBC Yorùbá pé òun kò rí irú ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀ rí láti ijọ́ tí òun ti ń lọ sí ilé ìjọsìn náà.
Ó ṣàlàyé pé òun sáré fi ara pamọ́ nígbà tí àwọn agbébọn náà dé ṣùgbọ́n ẹsẹ̀ òun tó hàn ní ìta ní àwọn agbébọn náà yìbọn mọ́.
“Gbogbo ènìyàn tí wọ́n rí ni wọ́n kàn ń yìbọn mọ́ àti ọmọdé àti àgbà, kòdá ọlá wí pé mo fi ara pamọ́ síbì kan ni mo fi ṣì wà láyé.”
“Láti ijọ́ tí mo ti dé ilé ayé mi ò rí irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí rí”
Ìjọba Ondo kéde fífa àsìá dé ìdajì fún ọjọ́ méje láti sọ̀fọ̀ àwọn tó forí sọta ìkọlù ní Owo

Gomina ipinlẹ Ondo, Rotimi Akeredolu ti pasẹ pe ki wọn fa asia Naijria de idaji nipinlẹ naa lawọn ileesẹ ijọba gbogbo.
Ọjọ meje gbako ni wọn yoo fi fa asia naa de idaji lati se ọfọ awọn eeyan to fori sọta ikọlu awọn agbebọn to kọlu ile ijọsin nilu Owo.
Atẹjade kan ti ijọba ipinlẹ Ondo fisita lọjọ Aje lo sisọ loju ikede yii nilu Akure.
Atẹjade naa ni “Mo ti pasẹ pe ki wọn fa gbogbo asia de idaji fun ọjọ meje, bẹrẹ lati oni ọjọ Aje titi di ọjọ kejila osu Kẹfa ọdun yii.
A gbe igbesẹ naa lati se ọfọ awọn eeyan to se agbako ikọlu awọn agbebọn nile ijọsin nitori gbogbo wa nipinlẹ yii ni adanu naa ba.”
Ọpọ oku lo sun , ti aimọye eeyan si fara pa nigba ti awọn agbebọn kan kọlu ijọ Aguda St Francis nilu Owo nipinlẹ Ondo.
Aarọ ọjọ Aiku lasiko ti isin ọjọ isinmi n lọ lọwọ ni isẹlẹ naa waye nigba ti awọn agbebọn dara pọ mọ awọn olujọsin.
Awọn agbebọn yii si lo yin ado iku ati ibọn lati pa ọpọ eeyan lara nile ijọsin naa.
Oku awọn eeyan to gbẹmi mi ati awọn eeyan to fara pa si ni wọn gbe lọ sawọn ile iwosan meji nla nla to wa nilu naa fun itọju.
Owo Church Attack:Okú mẹ́fà, ogún aláyè tó farapá ni wọ́n kó wá sí iléèwòsàn FMC Owo - Ọ̀gá àgbà FMC
Nigba ti BBC Yoruba kan sawọn ibudo itọju alaisan mejeeji ti wọn gbe awọn eeyan naa lọ, a ba awọn olutọju alaisan to wa nibẹ sọrọ.
Awọn osisẹ adoola ẹmi nile iwosan ijọba apapọ FMC Owo ati ile iwosan St Luis, niluu Owo naa ni wa n bẹbẹ pe ki awọn araalu wa fun awọn eeyan to farapa ni ẹjẹ lọna ati doola ẹmi wọn.
Ọga agba fun ile iwosan FMC Owo, Dokita Ahmed Adeagbo sọ fun BBC Yoruba pe, eeyan mẹfa lo ti jade laye ni nnkan bii aago kan ọsan.
O fikun pe awọn eeyan to to ogun n gba itọju lọwọ nile iwosan naa, yatọ si awọn to wa nile iwosan miran.

Ẹ dákun, ẹ mase kọlu ẹya Hausa to wa lagbegbe yin – Akeredolu rawọ ẹbẹ
Ni kete ti isẹlẹ naa waye ni gomina ipinlẹ Ondo, tii tun se ọmọ bibi ilu Owo nibi ti ikọlu naa ti waye, yara kankan morile ile ijọsin ti ijamba naa se.
Se ni gomina Akeredolu si n tara poro nigba to foju gan ni ẹjẹ awọn eeyan nilẹ ati ọsẹ tawọn agbebọn se nile ijọsin naa.
Nigba to n bawọn akọroyin sọrọ lasiko abẹwo rẹ naa, Akeredolu ni Iṣẹlẹ yii ba oun ninu jẹ pupọ, to si da omi tutu si oun lọkan pẹlu.
O fikun pe idi eredi ti oun ṣe kuro niluu Abuja wa si Owo bi o tilẹ jẹ pe lootọ ni ipalẹmọ fun eto idibo abẹnu lati yan ọmọ oye fun ipo aarẹ ti doju ọgbagade niluu Abuja.
Amọ gomina Akeredolu salaye pe ki awọn to wa l’Abuja maa ṣe eto ti wọn n ṣe lọ, eyii to kan oun julọ ni oun waa mojuto yii.
Bakan naa ni gomina tun rawọ ẹbẹ sawọn araalu lati mase gbẹsan isẹlẹ naa lọwọ ara wọn nipa kikọlu awọn ẹya Hausa ati Fulani to wa ni agbegbe wọn.
O wa n tara poro pe eremọde lasan ni awọn ohun to n sẹlẹ l’Amẹrika si ohun to ṣẹlẹ niluu Owo lọjọ Aiku yii.
“Ẹyin ọmọ ilu Owo, ẹ jọwọ, ẹ ma gbẹsan o, ẹma ṣe kọlu awọn Hausa to yi yin ka, ẹ jẹ ki awọn agbofinro ṣe iṣẹ wọn.
Ẹ ma jẹ ki a sọ ọrọ yii di ogun. Ti ogun ba maa bẹ silẹ, ogun yoo bẹ silẹ amọ ẹ ma jẹ ki a sọ ilu Owo di oju ogun.”
A ti n tọpinpin awọn to ṣe iṣẹ ibi yii lọwọlọwọ:
Bakan naa ni gomina Akeredolu fikun pe awọn ti n tọpinpin awọn to ṣe iṣẹ ibi yii lọwọlọwọ
“O jọ pe inu iho apata kan to wa loju ọna ilu Ute, ni awọn kọlọrọsi naa n fara pamọ si, amọ a oo wa wọn jade laipẹ, wọn yoo si foju wina ofin.
Irufẹ iṣẹlẹ yii ko ni waye mọ nitori a ko le farada iru rẹ mọ.
Gẹgẹ bii ohun ti a ri, ‘dynamite’ ni wọn fi kọlu ṣọọṣi yii, a si foju ganni agbara ẹjẹ.
Awọn to ku nibi iṣẹlẹ yii ju ogun lọ, to ba tilẹ jẹ ogun ni a jan gan, a ko le padanu iye eeyan to pọ to bayii.












