Àwọn agbébọn pa ènìyàn méjì ní ìpínlẹ̀ Kwara, jí ọ̀pọ̀ gbé lọ

Oríṣun àwòrán, Screenshot
Kò dín ní ènìyàn méjì tí àwọn agbébọn ṣekúpa nínú ọkọ̀ èrò tó gbé ènìyàn méjìdínlógún ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹfà ọdún 2022 ní ìpínlẹ̀ Kwara.
Àwọn agbébọn náà tún jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrò tí a kò le fi iye wọn múlẹ̀ báyìí gbé lọ ní òpópónà Obbo Aiyegunle sí Osi, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekiti, ìpínlẹ̀ Kwara.
Nínú àtẹ̀jáde kan TÍ agbẹnusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara Ajayi Okasanmi fi síta ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kẹfa, ọdún 2022 ló ti fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀.
Ó ṣàlàyé pé àwọn agbébọn ọ̀hún pa awakọ̀ ọkọ̀ náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akeem àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mama Ariye tí àwọn méjéèjì sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Obbo Aiyegunle.
Ó ní kété tí ìròyìn náà ti tẹ àwọn léti ní iléeṣẹ́ ọlọ́pàá àti àwọn fijilanté, àwọn ọdẹ àti àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò mìíràn ti ya wọ ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ láabi náà ti wáyé.
Okasanmi fi kun pé àwọn ti gbé òkú àwọn ènìyàn méjéèjì tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ sí ilé ìgbókùúpamọ́ sí ní ilé ìwòsàn Carosi fún àyẹ̀wò.
Bákan náà ló ní àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò ti fọ́n sínú igbó láti ṣàwárí àwọn agbébọn tó ṣọṣẹ́ náà àti láti dóòlà àwọn ènìyàn tí àwọn agbébọn náà jí gbé lọ.
Ó tẹ̀síwájú pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara, Tuesday Assayomo kòrò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó sì ti pa àwọn láṣẹ láti rí pé àwọn oníṣẹ́ ibi kúrò ní ìpínlẹ̀ Kwara pátápátá.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara da àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò sí Obbo Aiyegunle
Ìjọba ìpínlẹ̀ Kwara ti rọ àwọn ènìyàn ìlú Obbo Aiyegunle láti má fòyà bí àwọn agbébọn ṣe jí àwọn ènìyàn tí wọ́n sì tún pa àwọn méjì ní agbègbè náà.
Nínú àtẹ̀jáde tí Kọmíṣọ́nà fún ètò ìròyìn ìpínlẹ̀ Kwara, Bode Towoju fi síta lọ́jọ́ Àìkú ní nítorí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni ìjọba ṣe da àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò tó fi mọ́ àwọn ọlọ́pàá, ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ àti àwọn ọmọ ogun sí agbègbè náà.
Bákan náà ni wọ́n bá àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn tó pàdánú ẹ̀mí nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà kẹ́dùn, tí ìjọba sì sọ pé àwọn yóò ri dájú pé àwọn tí wọ́n jí gbé padà sí ilé wọn ní ayọ̀ àti àláfíà.
Towoju ní ìjọba ń sa gbogbo ipá láti ri pé àwọn onísẹ́ ibi náà fojú winá òfin.












