Àjọ NAHCON kéde iye tí àwọn tó fẹ́ lọ fún Hajj 2022 yóò san

Aworan awọn olujọsin nilẹ mimọ nilu Mecca

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ajọ to n ṣe amojuto irinajo Hajj ni Naijriia, NAHCON), ti kede iye ti gbogbo awọn to ba fẹ lọ si Hajj ọdun 2022 yoo san.

Alaga ajọ NAHCON, Alhaji Zikrullah Kunle Hassan, lo kede awọn owo naa lọjọ Satide, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, nibi ipade kan ti awọn oludari ninu ajọ naa ṣe nilu Abuja.

Alhaji Kunle Hassan sọ pe awọn arinrinajo lati awọn ipinlẹ to wa ni Gusu Naijria yoo san miliọnu meji aabọ din ẹgbẹrun mẹrin Naira (N2,496,815.29).

Awọn to wa lati Ariwa yoo san N2,449,607.89.

Amọ fun awọn eeyan to wa lati ipinlẹ Adamawa ati Borno, owo ti wọn din dikẹ si ti awọn to ku. Miliọnu meji ati ẹgbẹrun lọna irinwo le mẹjọ (N2,408,197.89) ni wọn o san.

Idi ni pe ipinlẹ mejeeji sunmọ orilẹ-ede Saudi Arabia.

Alaga ajọ NAHCON sọ pe owo irinna baalu nikan lo yatọ fun gbogbo awọn to ba fẹ lati rinrinajo Hajj ọdun 2022.

Ẹwẹ, o ni ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ni awọn arinrinajo yoo san fun ayẹwo aarun Covid-19.

Bakan naa lo sọ pe ki gbogbo ipinlẹ kọkọ ṣamulo iye eeyan ti wọn lanfaani si na, titi ajọ naa yoo fi ri esi gba lori afikun si iye eeyan ti Saudi Arabia yọnda pe ko kopa.

Lọdọọdun, paapaa lati igba ti aarun Covid-19 ti bẹrẹ, ni awọn alaṣẹ orilẹ-ede Saudi Arabia nibi ti ilu Mecca wa, ma n fun orilẹ-ede kọọkan nio iye eeyan to le ko wa fun irinajo Hajj.