Ọ̀pọ̀ èèyàn dáná sun ọkùnrin kan tó bú Ànọ́bì nílùú Abuja

Oríṣun àwòrán, other
Ileeṣẹ ọlọpaa ti fidi rẹ mulẹ pe awọn eeyan kan pa ọdẹ adugbo kan n'ilu Abuja, ti wọn si tun dana sun oku rẹ lọjọ Abamẹta, ọjọ kẹrin, oṣu Kẹfa, ọdun 2022.
Ninu atẹjade ti ọlọpaa fi sita, ọ̀pọ̀ eero kan kan ti inu n bi, pa ọkùnrin ẹni ọgbọn ọdún naa, Ahmad Usman, nitori pe o sọ ọrọ ẹgbin nipa anọbi.
Wọn ni ọkùnrin naa to jẹ ọdẹ ni adugbo, ni ede aiyede pẹlu Alfa kan ni agbegbe Tipper Garage, n'ilu Abuja.
Ede aiyede naa pada di eyi to kọja agbara, titi àwọn eeyan kan to to igba fi lu u pa, ti wọn tun dana sun un.
Ko tii si ẹni to le tọka si Alfa naa, tabi orúkọ rẹ.
Iṣẹlẹ pípa àwọn eeyan nitori wọn sọ̀rọ̀ abuku si anọbi, wọpọ laarin oṣù diẹ si asiko yii.
Ninu oṣù Kẹrin, ni awọn eeyan kan dana sun akẹ́kọ̀ọ́ ile ẹ̀kọ́ giga College of Education, n'ilu Sokoto.
Wọn fi ẹ̀sùn kan Deborah Samuel pe o bu anọbi.
Iṣẹlẹ naa fa awuyewuye jakejado Naijiria.
Bákan naa ni iwọde waye laarin awọn ọdọ kan, pe ijọba gbọdọ tu awọn afurasi ti ọlọpaa mú silẹ.
Ọṣẹ meji sẹyin ni ori tun ko obinrin kan yọ nipinlẹ Kano, lasiko ti awọn eero kan ń wa lati da sẹria fun nitori pe o bu anọbi lori ayelujara WhatsApp.
Ọpẹlọpẹ àwọn òṣìṣẹ́ alaabo DSS to gbe kuro nílé, kí àwọn eero naa to de ibẹ.
Ao ma a fi to yin l'eti bi iroyin nipa iku ọkunrin naa ba ṣe tun n jade si i.










