Nínú kí wọ́n kéde ikú mi àti kí n san owó ìdóòlà ₦100m tó takò ìjọba èwo lẹ fẹ́ kí n ṣe?

Oríṣun àwòrán, GETTY/BBC
Olori ijọ Methodist Prelate Samuel Uche Kanu tawọn ajinigbe tu silẹ laipẹ yi ti tu kẹkẹ ọrọ lori ohunti oju rẹ ri ni ahamọ awọn ajinigbe.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ BBC, Kanu sọ pe lẹba Leru ni ipinlẹ Abia nigba toun n lọ si papakọ ofurufu ni awọn ajinigbe yi yọ si oun loju ọna.
O sọ pe awọn ajinigbe Fulani mẹjọ lo gbe oun ati awọn meji mii to fi mọ Biṣọọbu Owerri lẹyin tawọn pari isin nile ijọsin.
O ni awọn ajinigbe yi gbe awọn lọ si inu igbo ti wọn si lu awọn.
''Mo ṣeṣe loju mi ọtun to si n ṣẹjẹ ṣugbọn awọn alaburu yi kobikita rara''
Mi o ṣe ni san owo idoola, ṣe ki wọn gbẹmi mi ni?
Labẹ ofin Naijiria eleyi tawọn aṣofin buwọlu, ijiya ẹwọn ọdun mẹẹdogun lo wa fun ẹni to ba san owo idoola fawọn ajinigbe.
Fawọn to ba si ji eeyan gbe, idajọ iku ni wọn la kalẹ fun wọn.
Niṣe lawọn eeyan si n sọrọ pe Prelate ti tapa si ofin Naijiria nipa sian owo idoola fawọn ajinigbe yi.
Prelate Kanu sọ pe awọn ajinigbe sọ pe kawọn san owo idoola miliọnu aadọjọ miliọnu Naira ṣugbọn wọn pada gba miliọnu ọgọrun Naira.
O tẹnumọ pe ijọ Methodist lo ṣa owo jọ lati san owo idoola yi.
Nipa pe o gbẹsẹ lori sisan owo idoola yi, o fi ibeere dahun pe ṣe awọn eeyan fẹ kioun ku tan ki wọn to bẹrẹ si ni ko woo jọ ni?
O ni ti eeyan ba ti wa ni ahamọ awọn ajinigbe ri,ko ni maa daba pe ki eeyan ma gbiyanju sisan owo lati fi doola ẹmi rẹ.
''ṣe awọn ijọba fẹ ki n wa nibẹ titi laelae ni ki n ma ṣapa lati mu ara mi kuro?Bi wọn ba fẹ tori eleyi mu mi, mo n reti wọn''
Ileeṣẹ Ologun tako ọrọ ti Prelate sọ pe awọn lẹdi apo pọ pẹlu ajinigbe
Prelate Kanu tun bẹnu atẹ lu awọn ọmọ ogun Naijriia pe wọn n lẹdi apo pọ pẹlu awọn ajinigbe yi ati lori ipa ti wọn n ko nipa awn agbesunmọmi.
Ileeṣẹ ologun Naijiria si ti fesi pada pe awọn ko lọwọ ninu ẹsun ti Prelate naa fi kan awọn ati pe ile ijọsin ko fi to awọn leti debi pe awọn mọ nipa owo idoola ti wọn san.
Esi wọn wa ninu atẹjade kan ti agbẹnusọ wọn fi sita tako ọrọ Prelate Kanu.
Onyema Nwachukwu sọ pe
ileeṣẹ ologun kii hu iru iwa to lawọn hu yi ati pe awọn yoo kesi Prelate lati wa yanana ọrọ to sọ.












