Gọńgọ sọ!, Àwọn olùdíje sípò Sẹ́nétọ̀ méjì jẹyọ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC ni ìpínlẹ̀ Oyo

Olujide meji ninu ẹgbẹ oselu All Progressive Congress ni ipinlẹ Oyo to ni erongba lati gba asia ẹgbẹ oselu naa fun ipo sẹnetọ ni guusu ipinlẹ naa ti kede pe awon jawe olubori ninu eto idibo abele to waya niluu ibadan.
Eto idibo naa ni wọn sun si iwaju lẹ meji lẹyin ti oro awọn 'delagates' je yoo laarin awọn oludeji naa.
Nigba wo ni idibo naa waye?
Idibo naa si pada waye lojo Aiku ni Le Chateau Event Centre to wa ni agbegbe Bodija niluu Ibadan.
Sugbon wọn da eto idibo naa duro lẹyin ti awọn alamojuto idibo kẹfin pe awọn oludibo po ju nomba ti o wa ninu iwe idibo.
idibo naa ni o wa tẹsiwaju lọjo segun pẹlu eto abo ti ko fun aiye fun awọn akoroyin lati darapo m#o eto idibo naa.
Sugbọn lọgbọn oṣu karun-un ọdun 2022, Bashorun Kolapo Kola-Daisi, kede pe oun lohun bori awọn akẹgbẹ oun nibu eto idibo abele naa.
O ni oun bori Sẹnẹtọ Kola Balogun, Sharafadeen Alli, Adegboyega Adegoke, Bimbo Adekanmbi, Rotimi Adeniyi ati Waheed Olajide.

Kola-Daisi ni oun tayo awọn akẹgbẹ oun pẹlu okòólénígba dín mẹjo ibo, ti Sẹnetọ Kola Balogun si mu mẹ́tàléláàdọ́rùn ún ninu ibo.
Nigba ti Sharafadeen Alli mu mẹ́tàdínláàdọ́fà, Adegboyega Adegoke mu mẹ́tàlélógójì (53 votes);
Bimbo Adekanmbi méjídínlọ́gọ́rùn ún, Rotimi Adeniyi ibo meerin ti Waheed Olajide si mu ibo meji.
Sugbon oro tun ba ona tuntun jade lojo keji, ojọ kọ́kànlélọ́gbọ̀n oṣu karun-un lẹyin ti Sharafadeen Alli, akowe ijọba Oyo ipinlẹ nigba kan ri jade pe oun ni jawe elubori ninu eto idibo to waye to t#esiwaju ni ose yii.
Alli ni oun tayo pẹlu ibo mẹ́rìnlélọ́gọ́sàn án lapapo lati bori aburo Olubadan, Kola Balogun, eni to se ijọba sẹneto lowo ni agbẹgbẹ guusu ni ipinle Oyo














