Ìdí tí àwọn obìnrin ń ṣùrù bò mí lásìkò tí mo gun Ọkadà láti London nìyí àti ohun tí mo ṣe
"Mo gbọ pe awọn eeyan n beere pe elo ni owo ti mo ti ri ko jọ fun igbogun ti aarun Polio gẹgẹ bi mo ṣe fi ori rẹ pe irinajo mi".
Kunle Adeyanju to fi Ọkada alupupu rinrinajo lati orilẹede London wa si Naijria ṣalaye gbogbo iriri rẹ fun BBC Yoruba ninu irinajo to ṣẹṣẹ ti de yii.

Elo ni owo ti Kola ri ko jọ ni irinajo rẹ fun Polio?
O ni gbogbo owo ti oun ko jọ fun aarun Polio, apo ẹgbẹ Rotary Club lo n lọ mi o si ni ọna lati toju bọ apo asuwọn owo naa.
"Aṣalẹ Sahara desert yẹn kii ṣe ibi to yẹ ki ọmọ eniyan wa rara, ilẹ yẹn ko ko eeyan mọra.

Ibẹ yẹn, o da bii pe o fẹ pa eeyan. Bi aṣalẹ Sahara ṣe ri niyẹn. Bi oru ibẹ́ ko ba paayan ojo ibẹ ni yoo lu eeyan pa.
O ṣalaye pe ninu Kilomita ẹgbẹrun mejila, ẹgbẹrun mẹta o le ọgọrun ni mo fi wa ọkada laarin awọn orilẹede Yuroopu amọ gbogbo mẹsan to ku, ilẹ Afirika ni o ti lo gbogbo ẹ.

"Afirika ni mo ti ja si oju ọna ti mo n ri igboro ati inu ilu, gbogbo eyi ti mo gba kọja ṣaaju, inu igbo ni gbogbo rẹ.
Adeyanju to rinrinajo yii gba aarin orilẹede mẹrinla kọja sọ bi o ṣe gba aṣalẹ Sahara eyi to ni ibi yii lo le jẹ eyi to le ju lati la kọja.

















