Kí lo lè ṣe láti dá àbò bo ara rẹ lọ́wọ́ ààrùn Monkeypox?

Eeyan to ni aarun Monkeypox

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Aarun Monkeypox ti pada si orilẹede Naijiria ti awọn eniyan to le ni ogun si ti ko arun naa.

Ajọ to n gbogun ti ajakalẹ aarun ni Naijiria, NCDC ni o kere tan eniyan mọkanlelogun lo ti lugbadi arun naa, ti ẹmi eniyan kan si ti lọ si arun naa.

Ajakalẹ arun naa ti wa ni orilẹede Amẹrika, Yuroopu, Australia ati aarin gbungun orilẹede agbaye.

Eeyan to ni aarun Monkeypox

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Nitori naa bawo lo ṣe le da abo bo ara rẹ lọwọ arun Monkeypox yii? Ati wipe kilo le ṣe to ba ko arun naa?

Monkeypox je ajakale arun kan ti ko ni ipa lopo, ti o si wopo ni ile Afika bii orileede Cameroon, Central African Republic ati Democratic Republic of Congo to fi mo orileede Naijiria.

Ileeṣe ̣orilẹede Amerika to n risi idena ajakalẹ arun, Ajọ eto ilera ni agbaye ati ileeṣẹ to n risi eto ilera ni Ilẹ Gẹẹsi lo fi awọn ọna lati da abo bo ara ẹni yii lede…

  • Ṣọra fun awọn ti wọn ba lugbadi arun naa ati awọn to le ko arun naa.
  • Wọ ibomu ti o ba fẹ sunmọ ẹni to lugbadi arun naa.
  • Lo rọba idaabobo ti o ba ṣẹṣẹ paarọ ọrẹkunrin tabi ọrẹbinrin to n ni ibalopọ pẹlu.
  • Ṣọra fun awọn ẹranko ti wọn le ko aarun naa paapaa awọn ti wọn ti fi igba kan ko arun kan tabi omiran, awọn bi inaki, eku ati awọn aja igbo.
  • Jẹ ki o mọ ọ lara lati ma a fọ ọwọ rẹ ni orekoore paapaa nigba ti o ba fi ọwọ kan eniyan tabi ẹranko to n ṣe aisan.
  • Fun apẹrẹ, fọ ọwọ rẹ pẹlu ọṣẹ ati omi ni igbakugba to fi mọ ti o ba fi ọwọ kan eniyan tabi ẹranko to ṣeese ko ni arun naa lara.
  • Wọ aṣọ idaabobo ni gbogbo igba ti o ba n tọju alaisan paapaa ẹni to ṣafihan ami arun Monkeypox.
  • Ẹran ti wọn ṣe daradara nikan ni ko o jẹ.

Kí lo lè ṣe tóo bá kó ààrùn náà?

Aarun Monkeypox

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Yẹra kuro ni ọdọ awọn eniyan ti o ba ṣakiyesi pe o ni arun Monkeypox, ki o si kesi awọn eleto ilera ni kiakia.

Lara awọn ami to ṣafihan arun Monkeypox ni iba, ori fifọ, ara riro, ki ara wu ati ẹyin didun.

Ki ara ole paapaa ni oju, ọwọ, ẹnu ati abẹ laarin ọjọ kan si marun un ṣeeṣẹ ko jẹ arun Monkeypox.

Amọ awọn arun miran to farajọ arun yii ni Chickenpox, Herpes tabi Syphilis nitori naa ni a ṣe nilo idaniloju ni ileewosan nipa iru arun to n ba ẹni naa finra. Ti o ba jẹ arun Monkeypox ni, ẹni naa ni lati yago fun awọn eniyan titi arun naa yoo fi tan ni ara.

Arun naa ki n pa ọpọlọpọ eniyan, ti yoo si lọ laaarin ọsẹ meji si ọsẹ mẹrin. Jọwọ wo nkan ti awọn eleto ilera sọ ni orilẹede rẹ nipa arun Monkeypox.