Covid toe: Ṣé o mọ̀ pé o leè kó Covid pẹ̀lú ọmọ ìka ẹ̀sẹ̀ rẹ̀ láì mọ̀?

Oríṣun àwòrán, CHRIS CURRY/GETTY
Awọn onimọ Sayẹnsi gbagbọ pe awọn lee ṣalaye idi ti awọn eeyan kan ṣe n ko arun kan to jọ eyi ti wọ́n n pe chillblain-like lesions lori ọmọ ika ẹsẹ ati ti ọwọ.
Aisan naa ni wọn n pe ni Covid toe eyi to si jẹ ifarahan ki ara maa yi si ọna ati ba ikọlu aisan naa ja.
Awọn oniwadii ijinlẹ sọ pe awọn ti ṣawari ibi agọ ara to maa n ba ja.
Awari ti wọn ṣe yii gẹgẹ bi o ṣe wa ninu iwe iroyin igba de igba Bristish Journal of Dermatology lee ṣeranwọ lati din ifarahan aisan naa ku lara.
Ki ni itumọ Covit toe?
Aisan yii le ṣẹlẹ si eeyan ni ọjọ ori to ba wuu, amọ awọn ọmọde ati ọdọ langba lo saba maa n mu.
Fun igba diẹ, o le ma dun eeyan ṣugbọn kurukuru naa lee so gidi gan ko si maa yun eeyan pẹlu awọn esusu ati bii ko maa wu sita.
Sofia, ọmọ ọdun mẹtala kan to wa lati Clackmannanshire ni Scotland ko lee fibẹẹ rin tabi wọ bata nigba to ni Covid toe nibẹrẹ ọdun yii.
O sọ fun ileeṣẹ BBC Scotland's The Nine bo ṣe jẹ pe ori kẹkẹ arọ lo n joko le to ba nilo ati rin irin to gun.
Ṣé ǹkan oṣù rẹ ń dà hìì hìì lẹ́yìn tóó gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19? Ẹ gbọ́ tuntun lẹ́nu àwọn Dókítà
Apa ibi to ran ni agọ ara eyi to saba maa n jẹ ọmọ ika ẹsẹ tabi ọwọ nigba mii lee da pọn tabi ko ni awọ alaro purple. Awọn mii, ara wọn yoo so yoo si maa dun wọn pupọ tabi ki apa ibẹ gbẹ fuurufu.
Ẹlomii a nii fun ọpọlọpọ oṣu awọn mii ko ni ju ọsẹ melo kọ. Ni ọpọ igba, wọn le ma ni awọn ami gboogi to jẹ ti Covid-19 bii ikọ, iba ati ai le gboorun tabi mọ adidun ounjẹ.
Ki lo de to maa n ṣẹlẹ?
Iwadii ijinlẹ to waye laip yii fihan pe latari ayẹwo ẹjẹ ati awọ ẹran ara, aba jade pe o lee koba ihuwasi ara.
Ọkan ninu ohun to maa n ṣẹlẹ ni mudunmudun ara (protein) to n ba arun ja eyi to n jẹ type 1 intterferon, ekeji si ni iru ajagun alaabo ara eyi to maa n mọọmọ kọlu sẹẹli ara eeyan ti ko kan ni dede ṣe bii ajakalẹ arun.
Awọn aṣewadii woye pe aadọta eeyan ni wọn rii pe wọn ni Covid toe ni ọdun 2020 atawọn mẹtala mii to ni irufẹ rẹ, chilblains leisons ti wọn ko si lọọ mọ ifarahan arun Covid toripe wọn ṣẹlẹ ṣaaju gidi gan ki arun Covid-9 to bẹrẹ.
Wọn lero pe iwadii awọn yii yoo ran awọn alaisan ati dokita lọwọ lori arun naa. Wọn ni omii lara wọn lee lọ nipa lilo ipara atawọn oogun mii.
"Aridaju pe aisan yii wa ati ohun to n ṣokunfa rẹ yoo ṣeranwọ lati ṣawari ogun fun itọju rẹ".
Dokita Veronique Bataille to jẹ dokita onimọ nipa awọ ara ati agbẹnus fun ajọ ilẹ Britain lori ẹra ara ni wn ṣawari Covid toe lọpọ igba nigba ti ajakalẹ arun covid-19 ṣẹṣẹ bẹrẹ amọ ko wa wọpọ lasiko ti Delta variant to n waye lọwọ lọwọ.
Eyi le jẹ boya toripe ọp eeyan ti n gba abẹrẹ ajẹsara sii tabi wọn n lo ọna mii lati daabo bo ara wọn lati ma nii.
Ẹgbẹ awọn dokita onimọ nipa awọ ara nilẹ Britain ni akọsilẹ oniruuru aisan ara to lee ni ṣe pẹlu Covid.
















