Menstrual cycle and Covid vaccine: Ṣé ǹkan oṣù yín ń dà hìì hìì lẹ́yìn tẹ́ẹ gba aabẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19?

Too ba lọ fun ayẹwo tabi lati gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19, o ṣeeṣe ki wọn kilọ fun ọ nipa atubọtan rẹ bii iba, ori fifọ, apa kikan ni fun bii ọjọ kan si meji lẹyin gbigba abẹrẹ naa.
Ki iyatọ de ba nkan oṣu obinrin ko lee si lori iwe ti wọn kọ awọn nkan wọnyi si.
Amọ awọn obinrin kaakiri ti bẹrẹ si ni beere pe ṣe ki nkan oṣu maa wa ṣaaju ọjọ rẹ tabi ko maa da wii wii tabi ko maa dun eeyan lee jẹ ara nkan to le ṣe eeyan to ba gba abẹrẹ naa amọ ti wọn ko fi faraye gbọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita Kate Clancy to jẹ onimọ iṣegun oyinbo nipa ayika ọmọniyan fi soju opo twitter rẹ pe oun ni iriri nkan oṣu to n da pupọ pupọ lẹyin ti oun gba abẹrẹ ajẹsara Moderna vaccine.
Lo ba pawọpọ pẹlu akẹgbẹ rẹ, Dokita Katharine Lee lati ṣe agbekalẹ ayẹwo kaakiri lati ni akọsilẹ iriri awọn eeyan to gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
- Wo ìhùwàsí Buhari, àwọn èèkàn Nàìjíríà àti ibòmíì tó ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19
- Ìjọba àpapọ̀ gbé ₦10b kalẹ̀ fún ìpèsè abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 alábẹ́lé
- Gba abẹ́rẹ́ Covid-19 kí o fi ọtí, "Doughnut", ẹ̀bùn owó ọ̀fẹ́ ṣararindin
- Ẹ má dán abẹ́rẹ́ Covid-19 wò lára mi, mi ò gbà! Mi kìí ṣe ẹmọ́ òyìnbó- David Oyedepo
- Ọmọdé méje àti olùkọ́ kan jẹ́ Ọlọrun nípè lẹ́yìn tí agbébọn ẹni ọdún 19 ṣíná ìbọn bolẹ̀ nílé ẹ̀kọ́ wọn
Amọ, Dokita Victoria Male to jẹ onimọ nipa ibimọ ni Imperial College ni London sọ nipa iwoye rẹ lara awọn obinrin kan.
O ni pe awọn obinrin kan to ti kọja asiko ọmọ bibi atawọn mii ti wa sọ fun awọn pe awọn mii to n lo ogun lati ma ri nkan oṣu wọn mọ lo ni awọn n da ẹjẹ bayii.
Ọpọ awọn onibalopọ akọsakọ atawọn obinrin to ti kọja asiko nkan oṣu lo ti wa n sọ pe awọn n ri ẹj lẹyin gbigba abẹrẹ ajẹsara.
Bo tilẹ jẹ pr ko tii si aridaju rẹ, awọn idi to pọ wa pe o ṣee ṣe ki abẹrẹ naa maa mu iyatọ ba nkan oṣu obinrin ṣugbọn eyi kii ṣe ohun to yẹ ko da iporuru ọka silẹ. Awọn onimọ ipa ibimọ lo sọ bẹẹ.
O jọ gate ko jọ gate
Itẹlẹ inu ile ọmọ obinrin jẹ́ pataki, lẹyin ti eeyan ba si ti gba abẹrẹ ajẹsara tan, ọpọlọpọ kẹmika ni yoo ranṣẹ sinu ara to si ni agbara lati ṣakoba fun sẹẹli to n yi kiri ara.
Eyi lee mu ki itẹlẹ inu ile ọmọ yọ ti yoo si di ẹjẹ to n da.
Amọ awọn onimọ ti ni ko ni nkankan ṣe pẹlu ki oyun walẹ. Lasiko iloyun, oniruuru ilana lo n ṣetọju inu ile ọmọ koda to fimọ wiwa nib olubi ọmọ eyii tii ṣe nkan to so ọmọ pọ mọ ẹjẹ to n wa latara iya.
Ko si tun si aridaju gidi kan to fihan pe gbigba abẹrẹ ajẹsara ko lee mu oyun walẹ.
Awọn onimọ ni awọn oloyun lee gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
- Lẹ́yìn ìwọ́de Yomi Fabiyi, ọlọ́pàá sọ ìdí tí wọ́n kò fi gba béélì Baba Ijẹsha, àti ìgbà tó ṣe é ṣe kí wọ́n ó fi sílẹ̀
- Ṣé lóòtọ́ọ́ ni akẹ́kọ̀ọ́bìnrin fásítì Akungba l'Ondo gbẹ̀mí ara rẹ̀?
- Kí ló mú Yomi Fabiyi àti Iyabo Ojo máa sá aṣọ ìdọ̀tí ara wọn síta?
- Davido sí Yomi Fabiyi: Mùmú ni ẹ́
- Òṣèré tíátà Yorùbá míràn tún kó sí gbaga ọlọ́pàá
Dokita Male ni "ọpọlọpọ ẹri ati aridaju" lo wa to fihan pe kii ṣakoba fun ati ri ọmọ bi.
Ninu iwe ti Dokita Male atawọn to ku rẹ sọ pe o ṣe pataki lati ka nipa atubọtan ti abẹrẹ ajẹsara naa lee mu wa ki wọn lee mọ ohun ti wọn yoo ma reti bi wọn ba gba a.
"Ọrọ kan wa nilẹ bayii nipa ilera obinrin, to ba jẹ pe iba wa lara ohun ti abẹrẹ Covid-19 le mu wa nkọ too si mọ? Dokita Jen Gunter to n risi itọju oloyun sọ bẹẹ.
"O le maa ro nkankan lo n ṣẹlẹ si agọ ara rẹ to si jẹ pe gbogbo nkan ti o n ri patapata lo abẹrẹ coronavirus wa. Bẹẹ gẹlẹ naa ni ṣegeṣege nkan oṣu ri".
Bakan naa fun awọn onibalopọ akọsakọ atawọn obinrin to ti kọja asiko nkan oṣu, dida ẹjẹ lee jẹ apẹrẹ aisan jẹjẹrẹ, torinaa wọn gbudọ mọ boya tun lee jẹ aidaa to n wa latara gbigba abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
Dokita Sue Ward to jẹ igbakeji aarẹ awọn olukọni nipa oyun ni Royal College sọ pe ẹnikẹni to ba rii pe dida ẹjẹ lara gba odi lara rẹ ko lọ ri dokita o si tun gba awọn eeyan nimọran ki wọn tete maa sọ ohun ti wọn ba ri to yatọ lara wọn.
- Kí ló mú Yomi Fabiyi àti Iyabo Ojo máa sá aṣọ ìdọ̀tí ara wọn síta?
- Ohun tí mo fẹ́ ṣe fún ẹbí ẹ̀gbọ́n mí, Dare Adeboye rè é ... -Leke Adeboye
- Baba Ijesha yóò ṣì wà látìmọ́lé títí ilé ẹjọ́ yóò fi parí ìyanṣẹ́lódì- Kọmisọ́nà Ọlọ́pàá
- Obìnrin ẹni ọdún 67 di àwátì lásìkò tó ń lọ sí ìṣọ́ òru
- Àjọ́ CAN pàṣẹ ètò àdúrà ọlọ́jọ́ mẹ́tà fún Naijiria ní May 28 sí 30, ẹ wo kókó àdúrá...
- Wo bí wọ́n ṣe kírun ìtúnu àwẹ̀ Ramadan 2021 ní Makkah àti Medina ní Saudi lónìí

















