Eid Al Fitri Public holidays: Wo àwọn ìpínlẹ̀ tó kéde àfikún ọjọ́ ìsinmi ọdún ìtúnu awẹ̀ síi

Obinrin musulumi

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Awọn ipinlẹ kan lorilẹ-ede Naijiria ti ṣafikun ọjọ isinmi fun ọdun itunu aawẹ Ramadan ti 2021 siwaju sii.

Awọn ipinlẹ naa fi oni ọjọ Eti, ọjọ kẹrinla, oṣu karun un kun ọjọ meji ti ijọba apapọ kọkọ kede tẹlẹ, iyẹn ọjọru, ọjọ kejila ati ọjọbọ, ọjọ kẹtala, oṣu karun un.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Gomian ipinlẹ Kano, Abdulahi Ganduje lo kọkọ kede pe oun ti fi ọjọ Eti kun isinmi awọn eniyan ipinlẹ naa ni eyi ti wọn yoo fi fi ọjọ mẹta sami ayẹyẹ ipari awẹ Ramadan tọdun 2021.

Ogbeni Muhammed Garba Shehu to jẹ kọmiṣọnna ifitonileti ati iroyin gbogbo fun ipinlẹ Kano lo kọkọ fi eyi sita.

Àkọlé fídíò, International Nurses Day 2021: Wo ìpèníjà àti àǹfàní inú iṣk nọ́ọ̀sì- Adetokunbo Shaba

Lẹyin naa ni ijọba ipinlẹ Jigawa naa kede itẹsiwaju isinmi pe ki ti ipinlẹ naa di ọjọ mẹta.

Hussaini Ali Kila to jẹ olori awọn oṣiṣẹ ni ipinlẹ Jigawa lo fi atẹjade sita lati kede isinmi ọjọ Eti kun eyi ti ijọba apapọ kede tẹlẹ.

Àkọlé fídíò, Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale

Wọ́n ti kírun ọdún ìtúnu àwẹ̀ n'Ibadan

L'Ọjọru ni Imam agba ilẹ Ibadan, Sheikh AbdulGaniyu Abubakry Agbotomokekere le iwaju irun itunu awẹ ni gbagede Yidi to n bẹ ni gbegbe Agodi nilu Ibadan.

Igbakeji gomina ipinlẹ Ọyọ, Rauf Olaniyan ati Olubadan ilẹ Ibadan, Oba Saliu Adetunji wa lara awọn eeyan pataki to pejupesẹ sibi irun naa.

Olubadan ti ilu Ibadan

Adura yii waye t'oun ti bi ajọ to n mojuto ọrọ ẹsin Islam lorilẹede Naijiria, 'Nigerian Supreme Council for Islamic Affairs (NSCIA)' ṣe paa laṣẹ wi pe ki awẹ Ramadan tẹsiwaju nitori osupa Shawal ko yọ ni alẹ ana.

Aṣẹ yii lo mu ki awẹ di ọgbọn.

Awọn musulumi ni Ibadan

Ọrọ kan ti wọn fi lede loju ọpọ ikansiraẹni Facebook Sheik Agbotomokekere lana lo kede rẹ wi pe awẹ Ramadan ti pari l'ọjọ Iṣẹgun, ọdun itunu awẹ yoo si waye l'Ọjọru.

Awọn Musulumi ni Yidi

Gẹgẹ bi ileri ti o ṣe, Sheik Agbotomokekere le iwaju awọn Musulumi kan lọ si Yidi, ṣugbọn pupọ ninu awọn adari ẹsin bi i Aarẹ Musulumi ilẹ Yoruba, Edo ati ipinlẹ Delta, Alhaji Dawud Makanjuola Akinola De-Damak, gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Oloye Rashidi Ladoja ati awọn mii ko si nibi ipejọpọ naa.

Ọdun Yidi

Bo tilẹ jẹ wi pe awọn eeyan pọ nibi ipejọpọ naa, onka awọn to kirun ọdun itunu awẹ nibẹ ko to iye awọn to n wa tẹlẹri. Iredi sini wi pe awọn eeyan kan ṣi gba awẹ titi di oni.

Eleyii ki i ṣe igba akọkọ ti iru igbese yii yoo waye, asaaju ẹsin yii kede iru igbese yii ni ọdun mẹta sẹyin, botilẹ jẹ wi pe awọn alaṣẹ ni o yẹ ki awẹ tẹsiwaju.