Baba Ijesha:Ẹ Ọmọ ajá pọ̀ nínú àwọn èèyàn tẹ́ẹ jọ ń gbé ilé ayé - Ifayemi Elebuibon

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Gẹgẹ bi gbajugbaja oṣere fiimu Baba Ijesha ṣe bẹ akẹgbẹ rẹ, Princess pe Ogun lo n ja oun toun fi ṣe aṣemaṣe pẹlu ọmọ to n tọ, BBC Yoruba kan si agba onimọ iṣẹṣe ati aṣa, o si jẹ ko di mimọ pe "Ọmọ igi, ajá, wà nínú 'awọn èèyàn tẹ́ẹ rí tó ń rìn kiri".
Ẹni tó bá ń fipá bá ọmọdé lòpọ̀ o ni iru n kan ti wọn pe e ninu aṣa Yoruba gẹgẹ bo ṣe sọ.
Eyi n jẹ jade latari ariwo to kọkọ gba ẹnu awọn eeyan nigba ti ọwọ tẹ gbajugbaja oṣere, Baba Ijesha pe o gbiyanju lati fipa ba ọmọdebinrin kan lopọ.
Oloye Elebuibon ni awọn ọkunrin ati obinrin mii wa to jẹ pe abuda aja ni wọn fi da wọn, iru wọn kii lojuti, wọn o ki n kọ lati baayan ṣere ifẹ ni gbangba, "ohun ni wọn fi maa n sọ pe ọmọ aja ma leleyii"
O ni ninu awọn ẹda eeyan ti ẹ ri nile aye, ọmọ aja wa nibẹ, ọmọ igi ni kii gbọrọ, ko si bẹẹ́ ṣe ba wọn wi to".
Nigba ti oṣerebinrin akẹgbẹ rẹ ti wọn tun jọ jẹ ọrẹ to jẹ alagbatọ ọmọ naa, Princess pariwo sita pe Baba Ijesha ti fipa ba ọmọ naa lopọ ri amọ awọn ko ni ẹri ti wọn le fihan fun agbofinro.
O ni idi eyi ni wọn ṣe duro de asiko yii ti o si ta Kamẹra CCTV mọle lati maa ṣọ .
Ko pẹ naa lawọn eeyan ba tan an kalẹ pe "haaa, 'Paedophine ni iruu wọn, haa kini abẹ wọn o ki n duroo... ko mọ ọmọ ọdun kan tabi mẹfaa...
Ẹwẹ nigba taa kan si agba oniṣẹṣe ati aṣa nilẹ Yoruba, Oloye Ifayemi Elebuibon ti ko tilẹ lọdii ọrọ rẹ mọ ti ariwo to gbode nipa Baba Ijesha, o sọrọ ilẹ kun.
Baba sọ pe labẹ aṣa ilẹ Yoruba, ti iru nkan to ṣe Baba Ijesha ti a n sọ yii ba waye, o tumọ si pe afọwọfa ni ti yoo si wa maa ni aye lo n ṣe oun ti yoo tun maa rawọ ẹbẹ.
"Ẹlomii yoo tun maa sọ pe egun lo n ja oun, epe lo n ja oun bẹẹ oun lo si n ṣe ara rẹ".
Baba Ẹlẹbuibọn ni nilẹ Yoruba, lootọ inunibini maa n wa, awọn eeyan maa n binu eeyan to si maa n mu ki wọn sa asasi si eeyan.
Amọ Baba ni tori rẹ naa ni aajo ṣe wa ti eeyan ma fi n kapa gbogbo nkan bẹẹ.
"Awọn baba wa maa n sọ wipe eegun nii ṣe mi o ṣee wi, ajẹ lo n ṣe ni o ṣee ba ni daro, emi nii mọ n ṣe ara mi o".

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ni nkan to n jẹ ogun idile, afọwọfa, edi, asasi wa daadaa amọ "to ba jẹ pe ogun idile ni, ṣe oun nikan lo wa ninu idile ọhun, awọn eeyan rẹ melo lo ti ṣe iru rẹ, ṣe baba rẹ ti ṣe iru rẹ ri?
Elebuibon ni to ba jẹ egun tabi ogun idile ni, o yẹ ki wọn ti re egun yẹn kuro, torinaa afọwọfa ni tirẹ.
Koda o tun le pe Eṣu ni, aa mọ nkan ti Eṣu ni ko mu wa".
Tori eyi, Oloye Elebuibon ni Baba Ijesha funra rẹ ni ko ronu piwada, "ko pe aro inu, ko pe odofin ko yiwa rẹ pada".
O ni ti Olanrewaju Omiyinka, o dabi igba ti wọn dẹ panpẹ ọran silẹ fun eeyan ti oun naa si nifẹ iru rẹ tẹlẹ lo fi jọ to fi di afọwọfa ati aibikita.

Oríṣun àwòrán, others
Iyatọ wo lo wa ninu edi ati asasi?
Agba onimọ iṣẹṣe ati aṣa, to gbọn ṣaṣa ninu Ifa, Oloye Yemi Elebuibọn ṣalaye iyatọ ati ijọra to wa ninu eedi, asasi ati afowofa.
Baba elebuibọn si jẹ ko di mimọ pe wọn yatọ si ara wọn ati pe ti nkan ba yiwọ tan fun eeyan ni yoo ma ni wọn n sa si oun.
Baba Ifayemi Elebuibon ni ti wọn ba fi edi mu eeyan. yoo maa hu iwakiwa, "lo maa n mu ki awọn sọ pe eedi ha mu ọ ni abi wọn n di ọ ni".
Baba nitori rẹ naa leeyan ṣe maa n ṣe aajo ki ẹfu o ma mu mi ki edi o ma di mi".
Ṣé ǹkan oṣù rẹ ń dà hìì hìì lẹ́yìn tóó gba abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19? Ẹ gbọ́ tuntun lẹ́nu àwọn Dókítà
Baba ni ọkunrin mii to n ṣe iru ẹ le jẹ pe o jogun rẹ ni tabi ko jẹ adamọ.
O ṣe apẹrẹ ọkunrin to n ba ọkunrin lo tabi obinrin to jẹ onibalopọ abosabo, bi Eleduwa ṣe da awọn mii ni bi wọn o ba tete ṣe atunṣe nigba ti Obi ba kiyesi iwa ọmọ latilẹ, ki wọn ti ṣe aajo lati fi tọju rẹ.




















