Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale

Àkọlé fídíò, Ansoogun jagunjagun Iresa Adu Ogbomoso tó máa ń bínú gba ẹbọ- Oloye James Olawale

Ansoogun ati awọn ẹru ati ẹṣọ rẹ ti wọn jọ m bọ lati oju ogun lo di okuta oriṣiiriṣi lori apata yii- Baba Iresa

Bi ọmọ ko ba ba itan ni ọrọ akọni Oodua, Ansoogun....

Ansoogun jẹ jagunjagun to gbona nigba aye rẹ.

Ansoogun lọ jagun lójó kan ni o gba iroyin ibanujẹ nigba to n pada bọ wa sile lo ba binu wọlẹ to si di okuta ni agbegbe Iresa Adu nijọba ibilẹ Suurulere ni Ogbomoso ni ipinlẹ Oyo ni guusu iwọ oorun Naijiria.

Koda, kii ṣe Ansoogun nikan lo di Apata nla o, gbogbo ẹru ati ẹṣọ to wa pẹlu rẹ lasiko naa lo sọ di apata yika ara rẹ ni agbegbe naa.

Oloye James Olawale to jẹ Baba Irasa ni Irẹsa Adu lo farabalẹ ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun BBC Yoruba nigba ti a kan sibẹ.

BBC Yoruba n jade lọ kọ sii nipa awọn akọni Oodua ki yoruba ma baa parun ni.

Ansoogun

Oloye Olawale salaye pe gbogbo nkan ti wọn fi n bọ oriṣa Ogun naa ni wọn fi n bọ Apata Ansoogun bii aja, Epo, ẹmu, obi ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Koda, Oloye ni Baba Ansoogun to di apata yii a maa ranṣẹ beere fun ẹbọ nigab miran tabi fun etutu.

O ni Baba Ansoogun a maa gbọ adura loju ẹsẹ ni pe ko si ohun ti eeyan wa beere lọwọ rẹ ti kii ṣe fun ni.

Eewọ ti ojubọ apata yii ni ni pe Ọba kankan ko gbodọ foju kan apata Ansoogun.

Oloye ni iru Oba bẹẹ kọ lo maa pada sile lọjọ to ba dẹjaa

Idi niyi ti wọn fi maa n mu gbogbo Oba ni Ogbomoso wa si iloro ọna apata yii fun etutu ṣugbọn wọn ko ni jẹ ki Oba rin sori apata naa tabi ko sunmọ ọ ju lati fi oju kan apata naa.

Baba Irẹsa sọ awọn ẹkọ to yẹ ki iwa akóni Ansoogun yii kọ wa.