Akomolede àti Asa: Kí ni Ìjálá láàrin àwọn ewì alohùn àti bí wọ́n ṣe ń sun-ún?

Àkọlé fídíò, Akomolede àti Asa: Kí ni Ìjálá láàrin àwọn ewì alohùn àti bí wọ́n ṣe ń sun-ún?

Ki ni Yoruba n pe ni Ijala, irufẹ awọn eeyan wo lo n sun, asiko wo ni wọn n sun ati pe bawo ni wọn se n sun Ijala?

Lọsẹ yii lori eto Akomolede ati Asa lori BBC Yoruba, Arabinrin Modupe aya Azzez, tii se olukọ ile ẹkọ girama Akure kọ wa nipa Ijala sisun.

Ninu alaye rẹ, aya Azeez ni Ijala jẹ ere awọn ọdẹ , to si sọ nipa iyatọ to wa laarin Ijala ati Iremoje, eyi tawọn ọdẹ maa n sun lasiko ti ọkan ninu wọn ba ku.

Bakan naa la tun kọ nipa ọna tawọn ọdẹ maa n gba lo Ijala lati fi ki ara wọn, se abẹwo sira wọn ati awọn itan nipa Ijala to ti waye ri.

Bakan naa ni olukọ ede Yoruba naa tun kọ wa nipa awọn aseyọri awọn ọdẹ to ti waye sẹyin lati ipasẹ Ijala ati oriki awọn ẹranko nla nla tawọn ọdẹ ti pa ninu igbo.

Ẹ fara balẹ lati kọ ẹkọ toni lori eto yii nipa Ijala sisun.