Lai Mohammed: Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tí wọ́n fẹ̀sùn kàn pé ó bú Lai Mohammed gbá ìtúsílẹ̀ lẹ̀yìn ọjọ́ 45 látìmọ́lé

Lai Mohammed ati Rotimi Jolayemi

Oríṣun àwòrán, Facebook/Akewi Jolayemi

Ileesẹ ọlọpaa lorileede Naijiria ti tu akewi nii Rotimi Jolayemi ti wọn fẹsun kan pe o kọrin ewi bu Minisita feto iroyin Naijiria Lati Mohammed.

Orin to kọ ọhun gbori ẹrọ ayelujara kaakiri ti ọpọ eeyan si ṣe alabapin rẹ.

Ọjọ marundinlaadota ni o lo latimole ki wọn to kede itusilẹ rẹ.

Iwe iroyin Naijiria The Punch so pe iyawo rẹ Dorcas so fun awọn pe lọjọ Ẹtì ni awọn ọlọpaa tu silẹ.

"Mo dupẹ pupọ lọwọ ileesẹ iroyin Punch bi wọn ki ti ṣe dakẹ lori ọrọ ọkọ mi ti wọn timọle lọna aitọ.

Wọn pada tu silẹ ki ma lọ ile lọsan ọjọ Ẹtì ṣugbọn wọn ni kó pada wa buwọlu awọn iwe kan kọkọ Ajé"

Ajọ ajafẹtọmọniyan Amnesty International to ṣaaju kesi awọn ọlọpaa lati da Jolayemi silẹ.

O ti lo ọsẹ marun un lahamọ ki wọn to wọ lọ sí iwaju adajọ ni ọjọ kọkànlá oṣu Kẹfa ọdun 2020.

Atọkun eto ni Jolayemi jẹ ti a si ma seto kan yi wọn n pe ni 'Bi aye se ri' lori ikani redio ipinlẹ Osun ati ni Radio Kwara Ilorin.

Ọjọ kaarun oṣu kaarun ni awọn ọlọpaa mu lori ẹsun pe o fi orin ewi bu Minisita Lai Mohammed.

Awọn ọlọpaa gbe lọ si Abuja ni ojo keje oṣu karun to sí wa níbẹ ki o to foju ba ile ẹjọ nibi ti adajọ ti so pe ki wọn lọ fi si ahamọ.