Lekan Kingkong: Níbikíbi tí mo bá wà, màá gbé àṣà Yorùbá ga
Ọlalẹyẹ Ọlalekan tabi Agba Inaki n gbe ni orilẹ-ede South Afrika, amọ ko gbagbe ile bi o tilẹ n gbe ni ajo.
Lori awọn oju opo ikansira ẹni lori itakun agbaye si lawọn eeyan ti mọ fun ọna to n gba gbe asa ati ise ilẹ Yoruba larugẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Agba Inaki maa n fi owe, ewi, ẹdọki ede ati awada se agbekalẹ awọn ọrọ rẹ, eyi to fi n se iwuri fun awọn ọdọ iwoyi ati gbogbo ọmọ Yoruba lapapọ lati mase gbagbe asa abinibi wa.
Lekan Kingkong, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ wa rọ gbogbo ọmọ Kaarọ oojire, paapa awọn to wa lajo lati maa gbe asa Yoruba larugẹ nitori ọmọ to ba sọ ile nu, o so apo iya kọ ni.