Jimoh Odutola: Gbajúmọ̀ olókoòwò tó n sọ àlòkù táyà di tuntun ní Afíríkà

Oloye Jimoh Odutola

Oríṣun àwòrán, Yoruba history /twitter

Ọkan pataki ni Jimoh Odutola lara awọn to kọkọ dá ileesẹ silẹ ni Naijiria, ati awọn oníṣòwò to lami-laaka.

Ilu Ijebu-Ode ni wọn bi Jimoh si, oun si ni aburo gbajugbaja onisowo to tun jẹ ẹlẹyinju aanu, Oloye Timothy Adeola Odutola.

Jimoh ko lọ si ileewe rara, koda ọmọ ọdun mejila lo ti bẹrẹ isẹ aje ni ṣíṣe.

O bẹrẹ isẹ gẹgẹ bi ọmọ ọdọ ati ọmọ ikọsẹ lọdọ oníṣòwò maalu, Alhaji Abdul-Kareem Otupa.

Àwọn ìtàn mánigbàgbé tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sugbọn, òpin de ba irinajo rẹ nibẹ ni ọdun 1918 nitori ajakalẹ aarun to waye ni agbaye ni ọdun naa.

Nigba to pe ọmọ ọdun mẹrindinlogun, o bẹrẹ isẹ aṣọ tita pẹlu Pọun mẹfa, ti ọkọ iya rẹ, Sanni Bilesanmi, fún.

Oloye Jimoh Odutola

Oríṣun àwòrán, Yoruba history /twitter

Ọkunrin yii ni iya Jimoh fẹ, lẹyin ti baba rẹ di oloogbe. Lọdun 1927, Jimoh tun gba ọna mii yọ nidi okoowo ṣíṣe.

O bẹrẹ si ni ṣe owo eto irinna ọkọ. Bakan naa, lọdun 1929, o fi owo katakara kòkó kun isẹ rẹ.

Ìtàn sọ pe o ṣe àṣeyọrí pupọ nidi isẹ yii, nitori pe otitọ inu lo fi n ṣe okoowo rẹ.

Sugbọn ṣa, ifasẹyin kan de ba lasiko ti oun ati ẹ̀gbọ́n rẹ, Adeola Odutola, jọ da òwò pọ.

Itan sọ pe iya wọn lo fi dandan mu àwọn mejeeji ni ọdun 1932, lati jọ ṣe òwò pọ. Saaju asiko naa, akọwe ile ẹjọ ni Adeola, o si tun n ṣe okoowo keekeeke.

Àkọlé fídíò, Taooma: Ìbáṣepọ̀ mi pẹ̀lú àwọn òbí mi yàtọ̀ sí bí mó ṣé n polongo nínú fídíò mi
Oloye Jimoh Odutola ati aya rẹ

Oríṣun àwòrán, Yoruba history /twitter

Okoowo karakata èrè oko si ilẹ okeere, aṣọ hihun, ati iwakusa goolu ni wọn n ṣe.

Àmọ́, kii dun ko pọ ni ọrọ ajọsepọ wọn jẹ. Lọdun 1948, ajọsepọ wọn fi ori sanpọn, ti wọn si tuka.

Àmọ́, wọn di orogun òwò. Awọn mejeeji lo si pada di alaseyọri ni ọna ti wọn rìn.

Lọdun 1950, o da ileesẹ J. A Odutọla and Company Limited silẹ. Abẹ ileesẹ naa si ni gbogbo okoowo rẹ wa.

Lẹyin ọdun mẹrin, o da ileesẹ West African Tyre Retreading and Company Ltd silẹ.

Àkọlé fídíò, Bed Wetting: Tolulope Joseph ní ò lé ní ogún ọdún tí òun fi tọ̀ sílé kí ìwòsàn tó dé

Ileesẹ naa ni akọkọ iru rẹ ni ilẹ Africa. Ohun ti ileesẹ naa ma n ṣe ni pe o ma n sọ aloku taya tabi eyi ti ko dara mọ di tuntun.

Ileesẹ naa gbooro debi pe ijọba orilẹ-ede Ghana ati Kenya ránṣẹ́ pe Jimoh Odutola, lati wa a da iru rẹ silẹ ni orilẹ-ede wọn.

Àṣeyọrí Odutola ko tán sibẹ o. Oun kan naa tun ni ẹni akọkọ to da ileesẹ ti wọn ti n ṣe timutimu (foam) onirọba silẹ lọdun 1958, ati eyi ti wọn n fi ike ṣe ni ọdun 1960.

Nigba ti yoo fi di ọdun 1951, o ti ṣi ọfiisi kan si ilu Oldham, United Kingdom. Lọdun 1967, o gba iwe ẹri apọnle gẹgẹ bi ọmọ Africa to kọkọ lọ si North Pole.

Àkọlé fídíò, Nigerian Drone Maker: Roqeeb Aderogba ní ìgbà mẹ́fà l‘òun kùnà láti ṣe dírónù, kó tó yege

Ni ọdun naa bakan naa lo tun di ọmọ Afirika akọkọ to wọ baalu Lufthansa lati ilu Tokyo ni orilẹ-ede Japan, lọ si Alaska lorilẹ-ede America, ati Alaska lọ si Copenhagen.

Bo tilẹ jẹ pe Jimoh Odutọla ko kawe, o ri daju pe gbogbo ọmọ mẹrinlelogun to bi kawe debi to wu wọn.

Lara awọn ọmọ rẹ ni Ọjọgbọn Ebun Clark, Ọjọgbọn akọkọ ninu imọ ere ori itage ni Nigeria. Oun si ni iyawo gbajugbaja onkọwe, Ọjọgbọn J. P Clark.

Ẹlẹyinju aanu ni Alhaji Jimoh Odutọla. O kọ ileewe girama kan ati ile ẹ̀kọ́ Kuraani ní ìlú Ijẹbu-Ode.

Bakan naa lo ṣe ojupopo oni maili mẹsan lati ìlú Irogbo si Iperindo ni Ilesha.

Aworan ileesẹ ati taya ti Jimoh Odutola n se

Oríṣun àwòrán, Yoruba history /twitter

Lara oore aritọkasi to tun ṣe ni bo ṣe kọ ibusun igba fun ileesẹ ologun nilu Ibadan lati ṣe atilẹyin fun ijọba Naijiria lasiko ogun Biafra.

O pe ẹni ọdun marunlelọgọrun ko to o kú ni ọdun 2010.

Titi di oni, orúkọ rẹ ni wọn fi sọ opopona naa kan ni ọjà Ogunpa/Dugbẹ nilu Ibadan.

Bakan naa ni ipinlẹ Eko, wọn fi orukọ rẹ sọ adugbo kan ni agbegbe Surulere.