Ìtàn Mánigbàgbé: Adebisi Idikan ni olówó tó kọ́kọ́ ra ọkọ̀ nílẹ̀ Ibadan

Oríṣun àwòrán, Busari Adebisi
Ilu Ibadan jẹ ilu to gbajumọ nilẹ Afirika ati lawujọ agbaye, to si ni awọn akọni ẹda ti ko lonka.
Ọkan lara awọn ọmọ bibi ilẹ Ibadan to jẹ akọni ti ko see gbagbe ni Asiwaju Sanusi Adebisi Giwa Idikan.
Gẹgẹ bi itan ti sọ fun wa, olowo, ọlọrọ ati ẹlẹyinju aanu ni Adebisi nigba aye rẹ eyi to to ọgọrun un ọdun sẹyin.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Gẹgẹ bi a se rii ka loju opo itakun agbaye, olokiki ati gbajumọ nla ni ọkunrin yii, ti okiki rẹ si tan kale, ka oko ati nilẹ okeere.
Koda, Adebisi kọ ile agbayanu ati awodamiẹnu kan si agbegbe Idikan nilu Ibadan, eyi to ni ojule to lee ni ọgọrun un, eyi si lo mu kawọn ọmọ Yoruba fi maa powe pe 'N o kọle mi bii ti Adebisi, esu aini kọ ọkankan ni'
Awọn ohun arikọgbọn nipa Sanusi Adebisi Idikan:
- Adesina ni orukọ baba Adebisi, ilu Ẹfọn Alaaye si lo ti wa tẹdo silu Ibadan
- Ile Lanasẹ ni adugbo Arẹmọ ni Adesina kọkọ gbe pẹlu aburo rẹ kan to n jẹ Alabi, to si maa n hun asọ ofi rẹ, bẹẹ lo tun maa n difa fun Alaafin Atiba nilu Ọyọ
- Idi ree ti Alaafin Atiba se fi ọmọbinrin rẹ kan, Ogboja ta Adesina lọrẹ to si bi ọmọ mẹta fun-un, orukọ wọn n jẹ Adetinrin, Adeoti Ati Adebisi, tii se abikẹyin
- Ọdun 1882 ni Adebisi Idikan dele aye, Aarẹ Latoosa si lo wa lori itẹ bii Baalẹ Ibadan nigba ti wọn bii
- Okoowo asọ ofi tita ni Adebisi Idikan ati awọn ọmọ baba rẹ yoku yan laayo, ti wọn si maa n kiri yika igboro ilu Ibadan ati agbegbe rẹ
- Adebisi funra ara rẹ lo maa n hun asọ oke to n ta pẹlu awọn yoku rẹ, eyi to jẹ ko di kori kosun awọn eeyan to ba ni ọjọ ayẹyẹ lọna bii igbeyawo sise, oku agba ati isọmọlorukọ
- Koda, nigba ti Adebisi yoo fi di ẹni ọdun mejidinlogun, o ti ni awọn onibara kaakiri ni ọja Iwo, Ile Ogbo, Ikire, Osogbo, Ifẹ, Ondo titi de ilu Benin ati awọn agbegbe miran ti wọn ti n lo asọ oke
- Eyi to mu ki Adebisi Idikan di olowo ati ọlọrọ tabua nigba aye rẹ
- Nigba ti owo de, Adebisi ko di owo pamọ sinu saka rara, tabi ko maa nawo bii ẹlẹda laini itumọ, sugbọn o tun ya sidi okoowo miran, eyi ti ko ni jẹ ki owo rẹ tete run
- Adebisi Idikan tun ya lọ sidi isẹ ọgbin, to si mu ilẹ si abule Asipa lẹba oko Mámu lọna Ijẹbu, to si dawọle ọgbin koko lọpọ yanturu, lẹyin eyi lo tun lọ mu oko si adugbo Apata nilu Ibadan nibi to ti ni sare ilẹ bii igba to fi se ọgbin koko
- Adebisi ni itan tun sọ fun wa pe oun ni ọmọ Ibadan akọkọ ti yoo ra mọto yatọ si ẹsin tawọn gbajumọ maa n lo laye igba naa
- Nitori aseyọri to ni nidi ọgbin koko yii ati buruji to wa lapo rẹ, lawọn olokoowo koko yoku ti wọn dijọ n se ẹgbẹ, fi jẹ olori wọn
- Wọn si n pe e ni Giwa ẹgbẹ onikoko, idi si ree to se fi Giwa sẹyin orukọ rẹ, to si n jẹ Sanusi Adebisi Giwa
- Lasiko ti buruji ji sọwọ Adebisi, dandan lowo ori nilu Ibadan nigba naa, gẹgẹ bi asọ ibora naa se jẹ tulaasi lasiko ọyẹ
- Awọn eebo amunisin kii fi ọrọ owo ori sere nigba naa pẹlu awọn ọdọ ati ọkunrin abarapa, ẹnikẹni ninu wọn to ba si fi aake kọri pe oun ko ni san owo ori, yoo jẹ iyan rẹ nisu loke Mapo lọdọ awọn eebo
- Idi niyi ti Adebisi se maa n tiraka lati ba awọn akẹgbẹ, ẹbi, ara, ọrẹ ati awọn ojulumọ rẹ san owo ori, ki awọn oyinbo ma baa kọ oju wọn si oorun ọsan gangan loke Mapo
- Sugbọn ọrọ naa papa bẹyin yọ lori sisan owo ori yii nigba ti Balogun ilẹ Ibadan nigba naa,Ola gbẹmi ara rẹ nitori pe o ni o san ki oun ku, ju ki oun maa ri awọn ọkunrin Ibadan ki wọn maa lọ sẹwọn nitori aisan owo ori
- Lẹyin isẹlẹ yii, ni omi aanu to maa n san loju Adebisi lọpọ igba tun bẹrẹ si san, to si tọ awọn eebo lọ loke Mapo pe oun ṣetan lati maa san owo ori gbogbo ọkunrin to ba to owo ori san nilu Ibadan, ki ijọba si dẹkun yiyọ àwọn eeyan Ibadan lẹnu mọ
- Lati igba naa wa, ni eebo to n gba owo ori yoo se akojọpọ apapọ iye owo ori to yẹ ki gbogbo ọkunrin nilẹ Ibadan san, ti yoo si lọ gba a nile Adebisi Idikan
- Adebisi kọ ile awodamiẹnu si adugbo Idikan nilu Ibadan lọdun 1927, to si tun ra ile nla kan lojule kẹrinlelọgbọn, opopona Whitman ladugbo Ebute-Mẹta nilu Eko
- Lọjọ Kẹrindinlọgbọn, osu Kọkanla, ọdun 1926 ni wọn fi Adebisi jẹ oye Asiwaju ilẹ Ibadan
- Kokoro ko jẹ kawọn ọmọ Ibadan gbadun obi Asiwaju Sanusi Adebisi Giwa Idikan dọjọ alẹ, nitori ọjọ Ẹti, ọjọ Kọkanlelogun, osu Kẹfa, ọdun 1938 ni ẹlẹyinju aanu naa jẹ ipe Ọlọrun lẹni ọdun mẹrindinlọgọta (56) lasiko aisan ranpẹ eyi to fihan pe igi to tọ, kii pẹ nigbo.
Ẹkọ ti itan Adebisi Idikan kọ wa:
- O kọ wa lati maa ṣiṣẹ kara, ka lee ni owo lọwọ lọna to tọ yatọ si owo ojiji tawọn ọdọ iwoyi n wa kiri
- Itan Adebisi Idikan tun kọ wa lati maa ṣe aanu, ka si maa ran awọn alaini lọwọ nitori pe ika ko dọgba
- Bakan naa tun ni itan igbe aye rẹ kọ wa lati maa ṣe iṣẹ loriṣiriṣi nitori ọna kan ko wọ ọja, eyi ti yoo jẹ ka tete jana
- Itan Adebisi tun kọ wa lati gbe ile aye se rere nitori a ko mọ igba ti ọlọjọ yoo de, boya ni igba ewe ni abi ni ọjọ ogbo, a ko gbọdọ fi isẹ rere falẹ
- Itan naa tun kọ wa pe ba ba lowo lọwọ, o yẹ ka fi jo nkan ni, ko si yẹ ka maa na ina apa
- Eeyan kii sunkun wọ ile adebisi, ko ma rẹrin jade, tori naa, ẹ jẹ ka maa ran awọn alaini to ba ba iranwọ wa sọdọ wa.
Fidio ti BBC Yoruba se nipa ile Adebisi to wa ni Idikan ree nisalẹ yii:
A wa n gbadura pe Ọba oke yoo dẹ ilẹ fun Asiwaju Sanusi Adebisi Giwa Idikan, gẹgẹ bi a se n ranti iwa rere to gbe ile aye se lasiko yii, nitori bi onirese rẹ ko tilẹ fin igba mọ, awọn eyi to ti fin silẹ, ko parun rara.


















