Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde

Àkọlé fídíò, Akomolede ati Aṣa lori BBC Yoruba: Wo díẹ̀ nípa àbùdá Olodumare- Iyabo Ayinde

Orukọ Olodumare sọ nipa awọn abuda adamọ Olodumare- Arabinrin Iyabo Ayinde.

Ero ati Igbagbọ Yoruba ninu Olodumare ni a n gbeyẹwo loni lori eto Akomolede ati Aṣa lori BBC loni.

Arabinrin Iyabo Ayinde lati ile ẹkọ Nigeria Navy Secondary School to wa ni Iresa- Apa ni Ogbomoso ni ipinlẹ Oyo ni oluko to yaranti to n kọ wa loni.

Olukọ wa ṣalaye ni kikun lori igbagbọ awọn babanla Yoruba ninu ẹsin si Olodumare.

O sọ nipa pataki ẹsin mẹtẹẹta ti Yoruba n gba fi sin Olorun.

Esin Ibilẹ, ti Imale ati Igbagbọ ni awọn Yoruba gbagbọ ninu rẹ ti wọn si fi n sin Olodumare pẹlu awọn ohun eelo ti igbagbọ wọn rọ mọ