Osun Akomolede: Àwọn Olùkọ́ Yorùbá ní ìpínlẹ̀ Osun ṣe bẹbẹ lórí ètò Akomọlede àti Aṣa lórí BBC

Awọn Olukọ lati ipinlẹ Osun dárà lori eto Akomolede ati Asa lori BBC Yoruba pupọ.
Eto yii jẹ eto ti BBC Yoruba n ṣe pẹlu ajọṣepọ ẹgbẹ Akọmọlede Naijiria ati ẹgbẹ Onimọ Yoruba YSAN.
A n gbe e kakiri awọn ipinlẹ Naijiria ni, ipinlẹ Osun ni a ti ṣe eyi ti awọn olukọ wọn si fakọyọ pupọ.
- Wo awọn iroyin manigbagbe to waye ni ọsẹ yii
- Mọ̀ sií i nípa Oba Yesufu Asanike , Olubadan tí kìí fi ọ̀rọ̀ sí abẹ́ ahọ́n sọ kódà níwájú sọ́jà
- Irú ẹ̀dá wo ni Lamidi Adeyemi? Aláàfin tó rí ìbẹ̀rẹ̀ àti opin sáà gómìnà mọ́kànlélógún l‘Oyo
- Àwọn Ọba Yorùbá kan rèé tí wọ́n rọ̀ lóyè, tí ọba míràn jẹ lójú ayé wọn
1) Àròkọ Alariyanjiyan ni Arabinrin Bolanle Adekanmi kọ wa.
Olukọ yii wa lati St Anthony Grammar School, Ikoyi Ile ni ipinlẹ Osun.
Bolanle Adekanmi salaye kikun nipa oriṣi Aròkọ ti yoruba ni pẹlu alaye kikun lori Aròkọ alariyanjiyan to jẹ koko ti a gbe yẹwo.
Iṣẹ agbẹ dara ju iṣẹ olukọ lọ ni koko ti a lo gẹgẹ bii afojusun ẹkọ.
2) Iparojẹ ati Isunki ninu Girama ede Yoruba ni Olukọ wa fun girama gbeyẹwo lati ileẹkọ Fakunle Comprehensive High School nilu Osogbo oroki to jẹ olu ilu ipinlẹ Osun.
Alagba Ajibola ni olukọ to kọ wa ni koko girama yii.
3) Ere Idaraya ti awọn ọmọde iran Yoruba n ṣe ni ere Osupa ni a n gbeyẹwo bayii.
Omowe Yetunde Olaleye to jẹ olukọ to dantọ lati Ile Ifẹ nipinlẹ Osun ni olukọ wa.
Nibẹ ni olukọ ti yanana pataki awọn ere wọnyii ati ohun to n ṣe fun iṣọkan awọn ọmọde nilẹ Oodua.
4) Ewi Alohun ni a gbajumọ ninu ẹkọ kilaasi yii.
Oriki si ni apa ti a ya si ni pato.
Arabinrin Omolara Olasumbo Aarẹ ni oluko wa lati ile ẹkọ George Burton Memorial School, Ileṣa ni ipinlẹ Osun.
Olukọ mẹnuba awọn oriki ti a ni bii ti oriki orilẹ, oriki idile, oriki ẹranko ati bẹẹ bẹẹ lọ.
- Ọ̀rọ̀ǹpọ̀tọ̀niyùn, Aláàfin obìnrin àkọ́kọ́ rèé, tó ní nǹkan ọkùnrin
- Lisabi Agbongbo Akala rèé, ẹni tó fi ìfẹ́, ìṣọ̀kan àti ìrẹ́pọ̀ gba ilẹ̀ Ẹ̀gbá lọ́wọ́ ìmúnisìn
- Ẹfunsetan Aniwura, ọmọ Ẹ̀gbá tó di akíkanjú obìnrin nílẹ̀ Ibadan
- Wo ibi tí o ti lè fi orúkọ síìmù rẹ sílẹ̀ tàbí gba nọ́mbà tuntun tí síìmù rẹ bá sọnù
5) Awẹ Gbolohun ni koko girama ti olukọ wa tun fi ara balẹ ṣalaye fun awa akẹkọọ.
Arabinrin Bisola Bose Olajide ni olukọ wa to to gbangba naa sun lọyẹ.
Ile ẹkọ Adeleke University High School ni ilu Ede nipinlẹ Osun ni olukọ wa ti n kọ awọn akẹkọọ.
Wo awọn apẹẹrẹ ti olukọ wa fi ṣalaye ni kikun lori Awẹ Gbolohun ede Yoruba.
6) Àrokò Pípa ní ilẹ̀ yorùbá ni koko ti a n gbeyẹwo bayii.
Alagba Ilupeju Moses to jẹ agba ọjẹ olukọ ede ati aṣa Yoruba ni olukọ to kọ wa ni ọrinkininiwin nipa Aroko.
Ilu Ejigbo ni ipinlẹ Osun ni olukọ wa ti wa.
Awọn wo lo n pa arokọ?
Awọn wo ni a n pa a si?
Awọn ohun eelo wo lo n fi itumọ aroko han ninu aṣa Yoruba?
Ati awọn ibeere miran ni olukọ Moses Ilupeju fi kọ wa ni kilaasi.
































