Biafra at 51: Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Nàíjíríà ń bèèrè pé níbo ni ìwé ìtàn ogun abẹ́lé wà fún ìkẹ́kọ̀ọ́?

Oríṣun àwòrán, @DeclanIfeanyi1
Awọn onpitan kan ti sọ pe awọn adari orilẹ-ede Naijiria ko kọ ẹkọ kankan lẹyin ogun Biafra to waye ni ọdun mọkanlelaadọta sẹyin.
Olukọ kan nipa itan ni Fasiti Adekunle Ajasin, to wa ni Akungba-Akoko, nipinlẹ Ondo, Ọmọwe Simon Odion Ehiabhi wa lara awọn onwoye ọrọ yii lasiko to n ba BBC sọrọ.
Ehiabhi woye pe iṣoro akọkọ ti Naijiria ni ni pe, gbogbo awọn to ti n dari ijọba lati ọdun 1960 ko du ipo lati tun ilu ṣe, ṣugbọn n ṣe ni ọpọ ninu wọn du ipo, lati tun apo ara wọn ṣe.
O ni lara awọn nnkan to fa ogun abẹle naa ni awọn adari Naijiria ṣi n ṣe laye ode oni, eyi to tumọ si pe wọn ko kẹkọọ kankan lara ogun abẹle ọhun.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, o ni ijọba apapọ ti ko gbogbo awọn iwe itan to le ṣalaye ẹkunrẹrẹ nipa ogun abẹle naa pamọ.
O ni "ko si opitan kankan nilẹ yii to le sọ pe oun ti foju ganni awọn iwe to le sọ ẹkunrẹrẹ bi ogun ọhun ṣe waye."
"Fun apẹrẹ, gbogbo awọn atẹjiṣẹ laarin ọgagun Ojukwu, Gowon, Aburi atawọn eeyan miran bẹẹ bẹẹ lọ ni ijọba ti ko pamọ, ti a ko ba ri awọn iwe wọnyii, awọn ọmọ aye ode oni ko le kẹkọọ nipa ogun naa."
Olukọ ọhun sọ pe, eyi ti mu ko ṣoro fun ọpọ ọmọ Naijiria lati mọ pe, kii ṣe gbogbo ede aiyede ni rogbodiyan le yanju.

Oríṣun àwòrán, Sabah
Ọmọwe naa tẹsiwaju pe, ẹkọ miran ti Naijiria kuna lati kọ lara ogun abẹlẹ naa ni pe, awọn eeyan ti kuna lati maa kọ awọn ọmọ wọn nipa itan orilẹ-ede Naijiria.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Àwọn agbébọn tó ń gba ojúgbó wọlé máa ń tó 1000 lẹ́ẹ̀kan náà - Amotekun
- Wo ìṣẹ̀lẹ̀ márùn-ún míì tí kò bá ti sọ Nàíjíríà sínú ogun abẹ́lé kejì
- Ọlọ́pàá kò fẹ́ yìnbọn, kó má ba à ba aráàlú, l‘àwọn afurasí olóògùn olóró ba sá mọ́ wọn lọ́wọ́
- Ẹ má ṣùn àṣùnpiyè o! Àwọn àjèjì darandaran ń wọ ìpínlẹ̀ Oyo àti Ogun lọ́gọ́ọ̀rọ̀ - Amotekun
- Covid-19 pa Ọlọ́lá Akin Olugbade, ẹ wo dúkìá jaburata tó fisílẹ̀
- NCDC àti NYSC bẹ̀rẹ̀ ìpàdé lórí ṣíṣí ìpàgọ́ àwọn àgùnbánirọ̀
- Ìjọba ìpińlẹ̀ Kwara dá owó tí àwọn obìrin 25 fi kọ́ ilé Ẹ̀kọ́ fún àwọn ọmọ wọ́n pada
- Ìjọba àpapọ̀ pàṣẹ kí ilé-ẹ̀kọ́ wọlé ní ọjọ́ 18, oṣù kíní ọdún.
Ehiabhi ni, "to ba jẹ pe a n kọ awọn ọmọ wa nipa itan orilẹ-ede wọn ni, a ti maa kọ wọn nipa irẹpọ laarin oniruru ẹya ati pe iyatọ to wa laarin awọn ẹya naa kii ṣe ohun to buru, ṣugbọn yoo tun bọ jẹ ki a lagbara si ni."
Ọmọwe Ehiabhi tun sọ siwaju si pe bi ijọba Naijiria ṣe n ta ẹya igbo nu ṣegbẹ kan lẹyin ogun abẹlẹ naa ko bojumu to nitori awọn eeyan n ri bii igba ti ibadọrẹ wa laarin ẹya Hausa ati Yoruba, ṣugbọn wọn yọ Igbo sẹyin.
Ehiabhi pari ọrọ rẹ pe, Naijiria ko ni ijọba ṣugbọn awọn alagbara kan lo kan n ṣe ijọba orilẹ-ede naa bo ṣe wọn, fun anfani ara awọn atawọn ẹbi wọn.
Lẹyin naa lo ni ọna kan gboogi ti itẹsiwaju fi le de ba Naijiria ni atunto ni kiakia.

















