Herdmen-Farmers Clash: Fatai Owoseni ní àwọn ọlọ́lá ló jẹ́ baba ìsàlẹ̀ fáwọn agbégbọn darandaran

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Yoruba ni ẹyinkule ni ọta wa, inu ile lawọn aseni n gbe, bẹẹ si ni bi ko ba si ole ile, ti ita ko le wa ja.
Bi ọrọ se ri ree lori bi awọn ajeji darandaran se n ya wọ ilẹ Yoruba eyi to n se akoba fun eto aabo wa.
Oludamọran si gomina ipinlẹ Oyo lori eto aabo, to tun jẹ Kọmisana ọlọpaa tẹlẹ, Fatai Owoseni ti wa salaye idi to fi rọrun fun awọn ajeji naa lati raye wọle si aarin wa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Mo ti ní ìyàwó àfẹ́sọ́nà, ayẹyẹ ìgbeyàwó mi ń bọ̀ láìpẹ́ - Lateef Adedimeji
- Dókítà 66 síṣẹ́ abẹ fún ìbejì tó lẹ̀pọ̀ nílé ìwòsàn fasiti Ilorin
- Ẹ ṣọ́ra o, ayédèrú abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19 gbòde ní Nàìjíríà, NAFDAC pariwo síta
- Wo àwọn ààrẹ Amẹ́ríkà mẹ́rin tí wọn rọ̀ lóyè àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn
- Wo ẹ̀kọ́ mẹ́rin tí Naijiria kùnà láti kọ́ lára ogun abẹ́lé
Owoseni, ẹni to koro oju si ipo ti eto aabo naa wa, wa sisọ loju rẹ pe awọn agbẹyinbẹbọjẹ kan nilẹ Yoruba lo wa nidi isẹlẹ yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oludamọran fun gomina salaye ọrọ yii ninu ọrọ apilẹkọ rẹ nibi ipade apero fawọn osisẹ alaabo adayeba nilẹ Yoruba, akọkọ iru ẹ, to waye nilu Ibadan.
Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn ọmọ bibi ilẹ Yoruba, YWA si lo se agbatẹru ipade eto aabo naa.
Owoseni ninu ọrọ rẹ ni omi n bẹ lamu fun ilẹ Yoruba lori eto aabo nitori ofin ilẹ wa lo laa kalẹ pe ọmọ orilẹede yii kọọkan le yan lati gbe nibikibi to ba wu amọ kii se bi ti ọdaran.
"To ba wa jẹ pe maalu se iyebiye sawọn darandaran yii bi ọmọ, o yẹ kawọn naa ranti pe ire oko tawọn agbẹ gbin sinu oko wọn naa dabi ọmọ lara wọn.
Ti emi ko ba si se ijamba fun maalu rẹ, ki lo de to fi yẹ ki iwọ ba awọn ire oko mi jẹ."
Onimọ nipa eto aabo naa wa salaye pe maalu mẹjọ ninu mẹwa ti darandaran kan ba n da, awọn eeyan wa lo ni wọn, paapaa awọn ọlọla wa.
O ni lọpọ igba ti ọwọ sinkun ọlọpa ba tẹ awọn ọdaran yii, awọn olowo ni yoo maa bẹbẹ pe ki wọn tu wọn silẹ, ki awọn maalu wọn ma baa jiya.
"Awọn asaaju awujọ wa ti ebi n pa gan wa, ni kete ti wọn ba ni inawo kan lati se, wọn yoo maa tọrọ maalu lọwọ awọn darandaran yii, ti wọn yoo si fi ọpọ eeka ilẹ wọn jirọ fun maalu kan.

Oríṣun àwòrán, OYSG
Bi darandaran ba si ti ri pe ilẹ naa dara, ko ni fẹ kuro nibẹ mọ, tawọn asaaju awujọ gan si maa n gbe ilẹ wọn fun darandaran lai bun awọn mọlẹbi wọn gbọ."
Owoseni wa gba awọn ọmọ Yoruba nimọran lati mase maa pe maalu ni buọda, tori pe wọn fẹ jẹran, tabi fi ohun ti wọn fẹ jẹ loni ba ọjọ ọla wọn jẹ.
Àwọn agbébọn tó ń gba ojúgbó wọlé máa ń tó 1000 lẹ́ẹ̀kan náà - Amotekun

Oríṣun àwòrán, @Worldstagegroup
Adari ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹyinti Olayanju ti salaye lẹkunrẹrẹ nipa awọn ajeji agbebọn to ma n gba inu igbo ya wọ ilẹ Yoruba lati agbegbe Oke Ogun nipinlẹ Oyo.
Olayanju, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ lori isẹlẹ naa fikun pe awọ̀n ajeji agbegbọn naa maa n to ẹgbẹrun kan nigba mii.
Alaga ajọ eleto aabo Amọtẹkun nipinlẹ Ọyọ, Ajagunfẹhinti Kunle Togun lo ti kọkọ ti ke gbajare saaju l‘Ọjọbọ pe, awọn Fulani daran-daran ti kii ṣe ọmọ Naijiria, to si dihamọra ogun n wọle si ipinlẹ naa.
- Ẹ má ṣùn àṣùnpiyè o! Àwọn àjèjì darandaran ń wọ ìpínlẹ̀ Oyo àti Ogun lọ́gọ́ọ̀rọ̀ - Amotekun
- Sunday Igboho kàn ń gbé ‘Camera’ lẹ́yìn kiri, kí wọ̀n lè rò pé ó ń jà fún Yorùbá - Gani Adams
- Àgbáríjọpọ ẹgbẹ OPC, fijiláńté VGC, Agbẹkọyà ti bẹrẹ ètò aàbò ní ilẹ Yorùbá
- Àṣẹ àwọn gómìnà là ń retí, àwa ti ṣetán láti dáàbò bo ilè Yorùbá- Gani Adams
O ni ijọba ibilẹ Saki east, Saki West ati Atisbo, ni wọn n gba wọle.
O sọ ọrọ yii ninu iwe to kọ si Ẹgbẹ ọmọ Yoruba l'agbaye, to ṣe agbatẹru ipade apero akọkọ lori eto aabo nilẹ Yoruba.
Ileeṣẹ ijọba ipinlẹ Oyo to wa nilu Ibadan, ni ipade naa ti waye.
Toogun ni lara awọn akiyesi ajọ Amọtẹkun ni pe, wọn ma n ni oriṣiriṣi nkan oloro bi ibọn, ida, ọbẹ ati bẹẹbẹẹ lọ.
Yatọ si eyi, o fikun pe ọkunrin ni gbogbo wọn ma n jẹ, eyi to fi han pe kii ṣe pe wọn fẹ ẹ tẹdo si ipinlẹ Ọyọ gẹgẹ bi arinrinajo ni.
O ni ajoji ti ko ni iwe irinna, tabi iwe idanimọ kankan ni wọn.

Oríṣun àwòrán, Oyo amotekun
Igba akọkọ kọ niyii ti ikọ Amotekun naa ti ke gbajare.
Bakan naa ni Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba, Gani Adams naa ti kede bẹ ẹ laimọye igba pe, awọn agbebọn ti n wọle si ilẹ Yoruba.
Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC Yoruba lori isẹlẹ yii, agbẹnusọ fun gomina ipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Taiwo Adisa sọ pe lootọ ni ijọba ko ṣẹṣẹ ma a gbọ iru iroyin bẹ ẹ.
Amọ, kii se nkan ti ijọba ipinlẹ Ọyọ nikan le mojuto. O kan n gbiyanju ni, paapaa nipa idasilẹ ajọ Amọtẹkun.
O ni iṣẹ ijọba apapọ ni lati ri i pe ẹnu ibode ilu wa daadaa.



















