Sunday Igboho: Gani Adams ní wọn kò fìgbà kankan fi ìwọ́de October 1 tó òun létí
Ọ̀rọ̀ Oduduwa Republic gbọgbọ́n, kìí ṣe ọ́rọ̀ Igboho nìkan - Gani Adams
Iba Gani Adams,Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba ti tu kẹkẹ ọrọ nipa idi ti ko fi kopa ninu iwọde Oduduwa Republic, ti Sunday Igboho lewaju rẹ.
Ninu ifọrọwanilẹnuwo to ṣe pẹlu BBC Yoruba, Adams ni ori ayelujara ni Sunday Igboho ti n kesi oun lati wa kopa ninu iwọde, ko kan si oun nile.
''Ṣe bi ti o ba fẹ pe mi ki n wa dara pọ mọ yin, wa a wa ba mi ni ile, gẹgẹ bi aarẹ? Wa a wa ni aarẹ o, mo wa ba yin nile. Mo fẹ ki ẹ wa lewaju wa ninu iwọde nilu Ibadan''
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Fídíò rèé lórí bí Sunday Igboho ṣe korò ojú sí ìwà ọ̀dàlẹ̀ nílẹ̀ Yorùbá
- Irọ́ ni o! Ìyàwó Ọ̀ọ̀ni Ogunwusi kò bímọ tuntun
- Ẹ̀yin tẹ́ ń jà fún ẹ̀yà Hausa, Igbo àti Yorùbá, ara yín lẹ̀ ń jà fún - Lamido Sanusi
- Donald Trump àti ìyàwó rẹ́ ti lùgbàdì àrùn CoronaVirus
- Ìfẹ́ Yorùbá ló mú mi fi ẹ̀mí wéwu láti kojú ajínigbé ní Kishi - Sunday Igboho
- Buhari, ayẹyẹ kí là ń ṣe gan, ṣé ti ìpànìyàn àbí ìjínigbé? - Aráàlú ń bèèrè
Aarẹ Adams ni lootọ ni oun ko lodi si igbiyanju Sunday Igboho ṣugbọn ''ọrọ ajijagbara kọja ọrọ Ibadan tabi Igboho nikan''
- Ohun tójú àwọn èèyàn tún rí tí wọ́n figbé ENDSARS bọnu
- Àwọn olùpolongo ìdìbò Aketi àti Jegede ń forígbárí l'Ondo, bí wọ́n ṣe n yìnbọn ni wọn n sun táyà
- Adìyẹ́ jẹ̀fun ara wọn! Ẹ̀ṣọ́ NSCDC ṣèèṣì yìnbọ̀n pa ọlọ́pàá ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ DSS l'Osun
- Pásítọ̀ CAC àti afurasí 'Yahoo boy' Olawale tó lu Hayatou ní jìbìtì N12.7m kó sí páńpẹ́ EFCC
O ni koda, lẹyin ti Sunday Igboho pari iwọde, ko pe oun lori aago lati sọ pe awọn ti ṣetan, to si ni gbigba orilẹede Oduduwa kọja ọrọ ẹnu lori ayelujara lasan.
Adams ni ti eeyan yoo ba ko ero jọ̀ fun iwọde, iru ẹni bẹẹ yoo ni ẹgbẹ to kojọ, ti wọn yoo maa tẹle lẹyin lati se iwọde, to si n beere pe ki ni orukọ ẹgbẹ ti Igboho da silẹ.
Nigba ti BBC Yoruba beere lọwọ rẹ boya o wa lara awọn agbagba Yoruba ti Sunday Igboho naka abuku si pe wọn gba owo ẹyin, ni wọn ko fi darapọ mọ iwọde, Aarẹ Gani Adams faraya, to si ni ọrọ ko ri bẹẹ.
''Iru ibeere wo lo n bi mi yẹn? O o lọ beere pe ta lo ni OPU to wa ninu Yoruba One Voice? Ni ijọ ti iwọ ti n ṣe akọroyin, nijọ wo lo gbọ pe Gani Adams gba abọde ri?''
Gani Adams ṣalaye siwaju pe, ọna ti Sunday Igboho n gba tabuku awọn agbaagba Yoruba ko bojumu.
O ni lọpọ igba Sunday Igboho kan maa n gbe kamẹra lẹyin, ki awọn eeyan baa le sọ pe o n ja fun ẹtọ Yoruba ni.
O mu apejuwe wa pe oun, Gani Adams, lo kọkọ ke gbajare lori ọrọ awọn ọdaran to n ji awọn eeyan gbe ni Oke Ogun, ki Sunday Igboho to ko awọn ayaworan lẹyin lọ si inu igbo.
''Ti eeyan ba fẹ koju awọn ọdaran, ṣe o maa n gbe kamẹra lọwọ? Ṣebi ti wọn baa ti mu wọn tan lo yẹ ko wa ṣalaye faraye gbọ?''
Ni akotan ọrọ rẹ, o wa gba Sunday Igboho nimọran lati fi pẹlẹ ṣe ijijagbara rẹ, nitori kii ṣe oun nikan lo le gba ominira tawọn Yoruba n beere yii.
''Gbogbo wa naa kọ ni a o jade sita fun iwọde. Ati pe, ti ko ba di pe o di dandan, olori kii kan sọrọ jaujau. Bi o ba ni ọrọ lati sọ, awọn ọmọ lẹyin rẹ lo yẹ ki wọn sọrọ''
Bi a ko ba gbagbe, Sunday Igboho, to jẹ ọkan lara awọn to n lọgun Oduduwa Republic ati awọn agbarijọpọ ẹgbẹ Yoruba mii ṣe iwọde lọjọ Kini oṣu Kẹwa, lati tako bi ilu ko ṣe rọgbọ.
Nigba ti Igboho n ba awọn eeyan sọrọ, o ni awọn olori Yoruba ti awọn jijọ fẹ ṣe iwọde yii yiṣẹ pada, nitori pe wọn ti gba owo lọdọ ijọba.


















