Sunday Igboho: N kò gba kọ́bọ̀ lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti wá ọ̀daràn jáde nínú igbó Kishi

Oríṣun àwòrán, Sunday Adeyemo
Ọjọ nla ati manigbagbe ni ọjọ ti ilumọọka ajafẹtọ ẹni kan, Oloye Sunday Adeyemo, ti ọpọ eeyan n pe ni Sunday Igboho yabo igbo Kishi.
Ilu Kishi ni iroyin tan kalẹ pe awọn afurasi agbesunmọmi ati afẹjẹwẹ ti n huwa laabi ninu igbo igbafẹ Old Oyo National Park to wa nilu naa.
Koda, wọn n ji awọn eeyan gbe lagbegbe naa, wọn n fi tipa ba awọn obinrin lopọ, ti wọn si tun n gba oko lọwọ awọn agbẹ.
Ọpọ eeyan ni awọn adunkooko mọ ni yii ti pa nilu Kishi to wa nijọba ibilẹ Irepo nipinlẹ Oyo, ti wọn si ti sọ awọn miran di alaabọ ara.
Awọn iwa ibi yii lo ta Sunday Igboho nidi kan nirọlẹ ọjọ Isẹgun, ọjọ kejilelogun osu Kẹsan ọdun 2020, ti oun ati ọmọlẹyin rẹ fi gba ilu Kishi lọ lati bawọn afurasi afẹjẹwẹ naa fija pẹẹta ninu igbo Old Oyo National Park.
Amọ niwọn igba to jẹ pe a kii ri ẹni sagbara, ọwọọwọ si ni ọmọ ejo n rin, Sunday Igboho ko da nikan lọ silu igbo naa.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ẹ gbà mí o! Bí mo ṣe ń dàgbà ni ǹkan ọmọkùnrin mi ń tóbi síi àmọ́ obìnrin ni mi'
- €10,000, ara owó tí wọn fi ra Ighalo pòórá, Ilé aṣòfin Osun bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
- Ìwádìí BBC rèé lórí ẹ̀sùn gbájuẹ̀ $120,000 tí wọ́n fí kàn igbákejì olórí òṣìṣẹ́ ìjọba l‘Osun
- PDP àti APC fi ìbọn dárà l'Ondo, ọ̀pọ̀ èèyan farapa, àìmọye dúkìá ṣòfò
- "Dípò ìnákúnàá lórí ìgbéyàwó ọmọ mi, mo lò owó fún ìgbéyàwó ọmọ òrukàn mẹ́tàlá"
- Àwàdà kẹríkẹrì nígbà táwọn olùdíje ààrẹ́ Amerika méjì kọjú ìjà síra wọn
- Ìjọba àpàpọ̀, jọ̀ọ́ máṣe yẹ̀ lórí àdéhùn rẹ fẹ́gbẹ́ òṣìṣẹ́ - Ile aṣojú-ṣòfin
- Ọgọ́rin arìnrìnàjò tó padà wá sí Nàìjíríà ló ní Coronavirus - PTF
Lara awọn to kọwọ rin pẹlu Igboho ni awọn ọmọ ologun ti Area C, awọn osisẹ aabo ara ẹni laabo ilu ati awọn ẹsọ oju ni alakan fi n sọri, taa mọ si fijilante.

Oríṣun àwòrán, Sunday Adeyemo
Irọlẹ si ni wọn wọ igbo naa titi di owurọ ọjọ keji, ti wọn n wa awọn afurasi ọdaran naa kiri inu igbo to fẹ naa.
Ni kete to gunlẹ si ilu Kishi ati awọn ikọ rẹ, aafin Iba tilu Kishi ni Igboho kọkọ morile, nibi to ti lọ se ago laafin si ori ade naa, ajeji kii sa wọ ilu, ki onilẹ ma mọ.
Nigba to n sọrọ lori idi to fi gbe igbesẹ naa, Sunday Igboho salaye pe oju ko gbọdọ ti ilẹ Yoruba lo mu ki oun fi ẹmi ara oun lelẹ lati lọ koju awọn afurasi apamọ lẹkun jaye naa.

Oríṣun àwòrán, Sunday Adeyemo
"N ko gba kọbọ lọwọ ẹnikẹni ki n to gbe igbesẹ yii, ifẹ iran Yoruba ti mo ni si lo mu mi se bẹẹ. Mo mọọmọ fi ẹmi ara mi lelẹ, fun isọkan ati alaafia Yoruba ni, ti Ọlọrun si lo awọn eeyan lati ti mi lẹyin."
Sunday Igboho wa se sadankata si ileesẹ ologun ilẹ wa atawọn ileesẹ agbofinro yoku to tii lẹyin lati gbogun ti iwa ọdaran lagbegbe Oke Ogun.
Bakan naa lo ki awọn ẹsẹ fijilante nijọba ibilẹ Irepo, Olorunsogo ati Oorelope fun isẹ takuntakun ti wọn n se ninu Igbo ọhun lati sẹ eegun ẹyin awọn agbesunmọmi yii ati ifẹ ilẹ baba wọn ti wọn ni.

Igboho tun gbosuba fun gomina Seyi Makinde ati Iba tilu Kishi fun aayan wọ̀n lati fi ẹsẹ eto aabo mulẹ lagbagbe naa.
O wa tun gbara ta lori bi awọn agbẹ to jẹ iran Yoruba se n fi oko wọn silẹ fun awọn afurasi ọdaran to n ba wọn lalejo, ti wọn si n sa asala fun ẹmi wọn.
O ni ilẹ baba wa niyi, awọn agbẹ naa kii si se ajeji, nitori naa, ko si ohunkohun to yẹ ko maa dun mahuru mahuru mọ wọn lori ilẹ baba wọn.
Lara awọn ẹru ti wọn ri ni ibuba awọn afurasi ajinigbe lasiko abẹwo wọn naa ni ibọn AK 47 mẹrin, ibọn AK 49 kan, ọpọ ọta ibọn, awọn ẹrọ foonu alagbeka ati owo beba pupọ.
Lẹyin aayan wọn ọhun, alukoro ileesẹ ọlọpaa nipnilẹ Oyo, Olugbenga Fadeyi ni ọwọ tẹ awọn afurasi ajinigbe mẹta to n sisẹ laabi ni agbegbe ijsba ibilẹ Irẹpọdun.














