PTF Covid-19: Ọ̀pọ̀ arìnrìnàjò mú ẹ̀rí àyẹ̀wò moyege lọ́wọ́ láti òkè òkun àmọ́ wọ́n ní Coronavirus

Ayẹwo ni papakọ ofurufu

Awọn arinrinajo ọgọrin to n de sorileede Naijira lati ilẹ́ okeere, ni ayẹwo fi han pe wọn ti lugbadi arun Coronavirus.

Igbimọ amuṣẹya ti ijọba apapọ gbe kalẹ lori akoso arun Coronavirus, lo fidi ọrọ yi mulẹ pe awọn arinrinajo naa foju arun yii han, lẹyin ọjọ meje ti wọn pada de.

Oludari igbimọ naa, Dokita Sani Aliyu to n ba awọn akọroyin sọrọ ni, ninu ayẹwo tawọn ṣe fun eeyan ẹgbẹrun meji ati irinwo le mẹta arinrin ajo si Naijiria, ọgọrin ninu wọn lo ko Covid-19.

O ni awọn ṣawari ọgọrin eeyan naa, bi o tilẹ jẹ pe pupọ ninu wọn mu iwe ẹri ayẹwo ti wọn se wa, eyi to ni wọn ko ni arun Coronavirus lara, lọwọ nigba ti wọn dari si Naijiria.

Aworan arinrinajo Naijiria

Oríṣun àwòrán, Twitter/NigerianCAA

Dokita Aliyu ṣalaye pe, awọn ko ba maa tun ayẹwo ṣe fun awọn arinrinajo yii, ka ni Naijiria ni eto iyasọtọ arinrinajo to munadoko ni.

O wa kilọ fawọn arinrinajo lati san owo fun awọn ile iwosan ayẹwo ti ijọba buwọlu nikan.

Lori ọrọ ayẹwo yii, awọn arinrinajo ti n bẹnu atẹ lu eto ti ijọba gbe kalẹ nipa owo gọbọi tawọn n san ṣugbọn ti ayẹwo naa ko munadoko.

Aworan arinrinajo Naijiria

Oríṣun àwòrán, Twitter/NigerianCAA

Ni awọn ibudo ayẹwo kokoro arun ti ijọba faṣẹ si ni ipinlẹ Kano, nnkan bi ẹgbẹrun marundinlogoji naira le diẹ ni owo ayẹwo arun Coronavirus nibẹ.

Ni ilu Eko, ọtalenirinwo o din mẹwa naira lowo tawọn arinrinajo n san fun ayẹwo Covid-19.

Coronavirus bí èso rere nílẹ̀ Adúláwọ̀, wo díẹ̀ lára èso náà...

Coronavirus in Africa: Wo àwọn ẹ̀rọ mẹ́wàá tí àwọn onímọ̀ ẹ̀rọ ṣe nítorí àrùn Covid-19

Ni bayii ti arun Covid-19 ti kọlu miliọnu kan eeyan le diẹ nilẹ Afrika, ọpọ awọn onimọ ẹrọ lo ti bẹrẹ si n ṣe awọn ẹrọ igbalode ni idahun si ajakalẹ arun naa.

Rọbọọti "Doctor car"

Oríṣun àwòrán, ECOLE SUPÉRIEURE POLYTECHNIQUE DAKAR

Diẹ lara awọn ẹrọ ti awọn onimọ ti gbe kalẹ nilẹ Afrika ree:1.Rọbọọti "Doctor car":

Awọn onimọ ẹrọ nile iwe gbogboniṣe kan ni orilẹ-ede Senegal lo ṣe rọbọọti naa lati ṣadinku bi awọn oṣiṣẹ eto ilera ṣe n ko arun Covid-19 lara awọn ti wọn n tọju.

Rọbọọti ọhun ni ẹrọ ayaworan lara, o si maa n lọ si yara itọju awọn alaarun Covid-19,

Koda, o maa n fun wọn ni ounjẹ ati oogun pẹlu ti awọn oṣiṣẹ eto ilera ko sin ni yọju rara.

Àkọlé fídíò, Akomolede ati asa Yoruba: Ẹ wá kọ́ nípa àpòtí ìṣura èdè wa lórí BBC Yorùbá

2.Ẹrọ to maa n fọ ọwọ

Ọmọ ọdun mẹsan an kan, Stephen Wamukota, lo fi igi ṣe ẹrọ ọhun ni Kenya lati ṣadinku itankalẹ arun naa nilẹ ọhun.

Ẹnikẹni to ba fẹ fọ ọwọ yoo lo ẹsẹ rẹ lati fi tẹ omi ati ọṣẹ jade ninu ẹrọ onaa lai fọwọ kan an. Oṣu Kẹfa ọdun 2020 ni Aarẹ ilẹ naa fun ọmọde ọhun ni ami ẹyẹ fun iṣẹ ọpọlọ to ṣe.

Ọmọ ọdun mẹsan an kan, Stephen Wamukota

Oríṣun àwòrán, JAMES WAMUKOTA

3.Fẹntilatọ to n da ṣiṣẹ funra rẹ:

Ẹni ogun ọdun kan ni Naijiria, Usman Dalhatu lo ṣe fẹntilatọ kekere naa lati ran awọn to ṣoro fun lati mi funra wọn latari arun ọhun.

Fẹntilatọ to n da ṣiṣẹ funra rẹ

Oríṣun àwòrán, INSTAGRAM / USMAN DALHATU

4.Ẹrọ ayaworan 3D to n ṣe ibomu:

Onimọ ẹrọ Natalie Raphil lo ṣe ẹrọ naa ni South Africa, ẹrọ ọhun si lagbara lati pese ọgọrun un ibomu lojumọ.

Ọpọ awọn alaarun Covid-19 lo si ti n lo ibomu ti ẹrọ naa n pese nile iwosan to wa ni Johannesburg.

5.Awo ti wọn n fọwọ si to n lo oorun:

Richard Kwarteng to n ṣe bata ni Ghana ati ibatan rẹ lo ṣe awo lọna ati gba awọn eeyan orilẹ-ede naa niyanju lati maa fọ ọwọ wọn ni igba de igba gẹgẹ bi ilana eto ilera.

Ti eeyan ba ti sun mọ ẹrọ naa, yoo yọ omi ati ọṣẹ jade ti eeyan yoo fi fọwọ rẹ fun iṣẹju marundinlọgbọn gẹgẹ bi ilana ti ajọ WHO gbe kalẹ.

Ẹrọ ayaworan inu lori ayelujara

Oríṣun àwòrán, Getty Images

6.Ẹrọ ayaworan inu lori ayelujara

Awọn onimọ ẹrọ kan ni Tunisia lo korajọ lati da oju opo kan silẹ lori ayelujara eyii to lagbara lati ya aworan inu ẹdọforo eeyan, ti yoo mọ boya iru ẹni bẹẹ wa ninu ewu Covid-19.

7.Rọbọọti to n ṣọ igboro:

Orile¬̣-ede Tunisia kan naa ni wọn ti ṣe rọbọọti to n ṣọ igboro loṣu Kẹrin, ọdun 2020.

Iṣẹ rọbọọti naa ni lati mu ki awọn eeyan tẹlẹ ofin konile-o-gbele ti ijọba ilẹ gbe kalẹ.

Rọbọọti ọhun maa n bere iwe idanimọ awọn eeyan to ba n rin gberegbere ni igboro lasiko igbele lati mọ idi ti wọn fi wa ni igboro lasiko igbele.

Rọbọọti to n ṣọ igboro

Oríṣun àwòrán, EPA

8.Sanitaisa to n fọ owo mọ:

Ọkunrin kan to n ṣiṣẹ ifoworanṣẹ ni Kenya, Danson Wanjohi lo ṣe ẹrọ onigi to maa n fọ owo mọ lati ṣadinkun arun Covid-19.

O gbe ẹrọ naa kalẹ latari bi owo ṣe n ti ọwọ ẹnikan bọ sọwọ ẹlomiran.

Ẹrọ ayaworan 3D to n ṣe ibomu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

9.Irinṣẹ ayẹwo Covid-19 laarin wakati kan:

O maa n to aarin ọjọ mẹta ki esi ayẹwo Covid-19 to jade ki Daniel Ndima ati Dineo Lioma to ṣagbekalẹ irinṣẹ to le e sọ esi ayẹwo naa laarin wakati kan ati iṣẹju marun un.

Kiki ki ijọba ilẹ ọhun fọwọ si ẹrọ ọhun lo ku ki wọn to gbe jade.

Ile gẹri-gẹri itaketesiraẹni

10. Ile gẹri-gẹri itaketesiraẹni:

Lẹyin ti Covid-19 gbode ni awọn gẹri-gẹri kan ni Ethiopia kọ ṣọọbu ti wọn ti le e maa gẹrun fun awọn onibara wọn lai fara kanra.