Iyabo Ojo: Wọ́n gba N51,950 lọ́wọ́ mi ní pápákọ̀ òfurufú láì ṣe àyẹ̀wò Coronavirus fún mi

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyaboojofespris

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Gbajumọ osere tiata lobinrin, Iyabo Ojo ti figbe ta lori iwa gbajuẹ tijọba Naijiria n hu lori ayẹwo arun Coronavirus.

Iyabo Ojo, lo sẹsẹ gunlẹ si papakọ ofurufu Muritala Muhammed nilu Eko lati Ilẹ Turkey ni aarọ ọjọ Aje.

Iyabọ ni iwa irẹnijẹ nijọba n se fawọn arinrinajo silẹ okeere tabi to de lati ilẹ okeere nidi ayẹwo arun Coronavirus.

Iyabọ ni aarọ ọjọ Aiku ana si ni oun se ayẹwo arun Coronavirus, ki oun to kuro ni papakọ ofurufu Instabul, lorilẹede Turkey.

Ayẹwo naa si lo ni o jẹ ki wọn gba oun laaye lati wọ ọkọ ofurufu wa sorilẹede yii ni ana.

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Koda, o ni oun tun paarọ tikẹti oun ati akoko ti oun yoo rinrin ajo, ki oun le gba esi ayẹwo covid 19 naa, eyi ti yoo jẹ ki wsn jẹ ki oun wọ baalu wa sile.

Iyabo Ojo tẹsiwaju pe laarọ ọjọ Aje oni ni oun wọle silẹ Naijiria pẹlu esi ayẹwo coronavirus naa, ti wọn ko tiẹ yẹ iwe naa wo lai naani wahala ti oun se lorilẹede Turkey.

Amọ fun iyalẹnu oun, se ni wọn tun n beere owo mii, tii se gbẹrun mejilelaadọta naira o din diẹ, N51, 950.00 lọwọ oun fun ayẹwo Covid 19.

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyaboojofespris

"Wọn ko tiẹ se ayẹwo kankan fun mi, wọn kan gba owo lọwọ mi ni, ti wọn si fi ẹrọ yẹ ara mi wo bo se n gbona si.

Lẹyin eyi ni wọn fun mi ni iwe kan lati tun lọ se ayẹwo Coronavirus ni adugbo Lekki.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bẹẹ ni mo n beere pe ki lo sẹlẹ si ayẹwo Coronavirus ti mo se lana, se ẹbu ni?

Haa, iwa alọni lọwọ gba ati irẹnijẹ gbaa ni eleyi." Iyabo Ojo pariwo.

Osere tiata naa wa n beere pe ki lo de tijọba Naijiria ko maa se ayẹwo arun Covid 19 fawọn arinrinajo to gunlẹ ni papakọ ofurufu gẹgẹ bi wọn ti n se nilẹ Turkey?

Àkọlé fídíò, SS3 ní mo wà báyìí, mo sì ti gba àmì ẹ̀yẹ̀ púpò nílé-lóko gẹ́gẹ́ bí onílù - Ayansike

O fikun pe ọtalerugba o din mẹwa 250TL owo Turkey ni oun san lati fi se ayẹwo Coronavirus ọhun, eyi to to ẹgbẹrun mẹẹdogun naira wa ni Naijiria.

Bẹẹ ni oun si gba esi ayẹwo naa laarin wakati mẹfa pereninu papakọ ofurufu ti oun ti se ayẹwo ọhun.

Eyi si lo mu ko maa kọminu pe ki lo de ti wọn gba owo oun ni papakọ ofurufu nilu Eko, ti wọn si fun oun ni iwe lati lọ se ayẹwo arun Coronavirus ni adugbo Lekki?

"Haa, iya ma jẹ mi o. Afi bii ẹni pe eyi ko tun to, se ni awọn osisẹ asọbode naa tun fikun iya naa. Se bi iya nla ba gbe ni sanlẹ, ke ke ke mii tun maa n gori rẹ ni."

Àkọlé fídíò, Toyin Atoyebi mechanic: Ẹ wo Toyin, ọmọbinrin ọdún 16 tó ń tún skadà àti gẹnẹrátọ̀ ṣe ní

Iyabo fikun pe awọn osisẹ asọbode tun fẹ gba owo lọwọ oun si lori awijare pe awọn ẹru to ba kọja ẹgbẹrun lọna aadọta naira, oun yoo sanwo itanran fun.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

"Ọmọ, mo wọ mọ wọn lọwọ ni o, emi to jẹ pe wọn ti kan mi ni eewo tẹlẹ, ti wọn ti ja mi kulẹ, fine kọ, fanta ni."

Iyabo Ojo wa n fi ika hanu pe "ki lo de ti orilẹede Naijiria ko mọ ju owo lọ, a si ku imura ajọdun ominira ọgọta ọdun Naijiria o."