Iyabo Ojo: Ìjà òṣèré tíàtà nìkan kọ́ nìkọlù South Africa, ti gbogbo wa ni

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyaboojofespris

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Yoruba ni itẹlẹ idi ẹni kii ri ni ti, asọ to ba si kangun si eegun ni wọn n pe ni Jẹpẹ, ko si si ẹni to lee sọrọ nipa awọn osere tiata, bi kii ba se ẹni to jẹ ara wọn.

Gbajugbaja osere tiata lobinrin, Iyabọ Ojo ti bọ soju opo Instagram rẹ lati gbarata lori ohun ti ọpọ osere tiata n la kọja, to fi mọ ohun gan alara funra rẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Osere tiata naa sọrọ yii nigba to n fesi lori bi eeyan kan to n gbe loke okun, se n bu ẹnu atẹ lu awọn osere tiata ati awọn gbajumọ lawujọ lapapọ pe, ọpọ wọn gbẹnu dani lai koro oju si ọpọ ikọlu tawọn ọmọ orilẹede South Africa n se si awọn ọmọ Naijiria.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

Ninu ọrọ rẹ, Iyabọ ni "mo wa lorilẹede Naijiria, mo si n sisẹ tọsan-toru, mo n tiraka lati bọ ọpọ eeyan. Ọmọde meje, agbalagba mẹrin ni mo n gbọ, ti mo si ni osisẹ mẹtalelogun to n ba mi sisẹ."

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyaboojofespris

Iyabọ Ojo ni lọpọ igba ni oun maa n rẹwẹsi ninu ọkan, ti ọkan oun si maa n yapa, bẹẹ si pẹlu gbogbo wahala oun yii, oun ko ko ere jọ fun ara oun tabi ni akoko lati sinmi rara.

O fikun pe koda ti oun ba rinrinajo lọ si oke okun, isẹ ni oun tun maa n se bii aago, ti oun yoo si maa ra orisirisi eroja ti oun fẹ wa ta lorilẹede yii nitori ọna kan ko wọja.

Osere tiata naa tun gbarata pe bi o tilẹ jẹ pe ilumọọka osere ni oun, sibẹ, oun n sisẹ kara laisinmi ni, to fi mọ ọpọ akẹẹgbẹ oun, tawọn si n ko okoowo meji, mẹta papọ ki awọn baa lee ri ọwọ mu lọ sẹnu.

"N jẹ ẹ mọ bi eyi se lagbara to bi nigba miran, to si tun maa n gba akoko ẹni...igbakuugba ti mo ba si fẹ rẹwẹsi pe n ko se mọ, ti mo ba ranti awọn osisẹ mẹtalelogun ti wọn n sisẹ labẹ mi, ti wọn yoo padanu isẹ wọn, ma tun joko jẹẹ."

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyaboojofespris

Iyabọ Ojo salaye pe oun ko kuku lee se awawi lori igbe aye oun yii, nitori aye oun kuku san ju tawọn eeyan miran lọ, ti eeyan ba si mọ inu ro, yoo mọ ọpẹ du, oun sa n ri nkan pawọda, ti oun si n bọ ẹnu awọn eeyan diẹ, tori naa, oun dupẹ lọwọ Ọlọrun fun eyi.

Lẹyin idupẹ yii lo wa bẹrẹ si ni sọ oko ọrọ si ẹni to n bu awọn osere tiata naa, to si ni sebi oke okun ni onitọun fidi kalẹ si, to ti n ri owo na, o wa gba nimọran pe ko lee mọ oun ti ọmọ Naijiria kọọkan n koju lati jẹun ayafi to ba wa gbe ni Naijiria.

O ni yoo dara ki onitọun maa bu ọwọ to tọ fun awọn ilumọọka nitori ko mọ ohun ti awọn n la kọja, ọpọ nkan si lo wa lori ero awọn, idi si ree ti esi aọn si isẹlẹ kọọkan fi n yapa nigba miran.

"O ko mọ irora mi, o ko mọ boya a n jẹrora lọwọ aisan kan abi a ni isoro ninu ẹbi wa abi pe wahala jijẹ gbajumọ n pa wa ku lọ, ta kan n tiraka lati bo isoro wa mọlẹ fun araye."

Iyabo Ojo

Oríṣun àwòrán, Instagram/iyaboojofespris

Iyabọ ni to ba jẹ pe ijọba wa n gba imọran awọn gbajumọ ni, ko ba ti gba imọran Fẹla, ko to jade laye ati tawọn ilumọọka miran sugbọn ọpọ eeyan maa n yara tete di ẹbi fun ẹlomiran, to si gbagbe pe ika ko dọgba.

O ni "o ti su wa ni Naijiria, ta si n sisẹ laagun lati jẹ eeyan, ọpọ ninu awa gbajumọ si lo jẹ mẹkunnu ti ko ni owo lọwọ, bẹẹ ni inu wa ko dun rara, ẹ ma si jẹ ki ohun meremere tẹ n ri lori ayelujara nipa wa tan yin jẹ."

Iyabọ Ojo wa kadi ọrọ rẹ nilẹ pe gbigbe ija ara wa kii se isẹ awọn gbajumọ nikan, gbogbo wa lo kan,to ba si jẹ pe ikọlu to n waye lorilẹ ede South Africa ka onitọun lara, yoo dara ko kuku maa bọ pada wa sile, ki gbogbo wa dijọ pawọpọ mu ayipada rere ba orilẹede yii.