Kogi PDP Primaries: Wada fẹ̀yìn Dino gbálẹ̀ nínú ìbò abẹ́lé PDP fún ìpò gómìnà ní Kogi

Oríṣun àwòrán, Twitter/Dino Melaye
Amoju ẹro Musa Wada la Sẹnẹtọ Dino Melaye mọ lẹ ninu ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP fun ibo gomina ipinlẹ Kogi oṣi kọkanla.
Amoju ẹrọ Wada jawe olubori ninu eto idibo ọhun pẹlu ibo aadọta le ni ẹẹdẹgbẹrin o din meji.
Ọgbẹni Ibrahim Abubakar lo ṣe ipo keji pẹlu mẹwaa le ni ẹẹdẹgbẹrin.
- APC ní yóò jáwe olúbori ni Bayelsa ati Kogi- Tinubu
- Òní nilé ẹjọ́ tó ga jùlọ yóò gbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ayédèrú sabuké tí wọ́n fi kan Buhari
- Ìfẹ̀hónúhàn l'Abuja lórí ìdájọ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tó gbẹ́sẹ̀ lé $9.6bn ohun ìní Nàìjíríà
- ShopRite Ibadan gbé ìlẹ̀kùn tìpa torí ìkọlù àwọn tó ń fẹ̀hónú hàn
- OPC, Miyetti Allah, agbófinró yóò wà nínú ìgbìmọ̀ aláàbò nílẹ̀ Yorùbá
- Wike kìí ṣe dọ́là tí Ganduje leè kó sápò- Agbẹ́nuso ìjọba ìpínlẹ Rivers
Nibayii, Wada ni yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu PDP ninu ibo gomina ti yoo waye lọjọ kẹriundinlogun oṣu kọkanla ọdun 2019.
Wada yoo ta kaungbọn pẹlu Gomina Yahaya Bello to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC atawọn oludigbe ẹgbẹ oṣelu miiran ninu ibo ọhun.
Àwọn èèyàn Yahaya Bello ló da ìbò abẹ́nú wa ní Kogi rú- PDP
Awọn eeyan Gomina Yahaya Bello lo wa fibọn da eto ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu PDP niluu Lokoja ru.
Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Kola Ọlọgbọndiyan to ba BBC Yoruba sọrọ, ṣalaye pe ayẹwo ibo lawọn n ṣe lọwọ nigba ti awọn janduku ọhun yabo gbọngan idibo naa ti wọn si bẹrẹ si ni yinbọn pẹrẹpẹ.

Oríṣun àwòrán, Other
Ọgbẹni Ọlọgbọdiyan ni ọpọ eeyan lo farapa nigba tawọn mii si dero ile iwosan ninu iṣẹlẹ ọhun lolu ilu ipinlẹ Kogi ti eto idibo naa ti waye.
O ṣalaye siwaju si pe oun ko le sọ bi Gomina Ahmadu Fintri ipinlẹ Adamawa to jẹ alaga eto idibo abẹnu naa ṣe mo ri bọ nigba tawọn agbebọn dabọn bo lẹ.
Amọ, o fikun ọrọ rẹ pe atundi ibo ko ni waye nitori eto idibo naa si n tẹsiwaju lonii, koda o sọ pe igbimọ eto idibo abẹnu yoo kede ẹni to ba bori ninu idibo abẹnu naa l'Ọjọru.
O ni ohun kan to ku ni lati kede orukọ ẹni to jawe olubori ninu ibo ki wọn to ko ibọn wọ le.

Oríṣun àwòrán, Other
Ọgbẹni Ọlọgbọndiyan sọ pe ni gbogbo igba ti Gomina Bello ipinlẹ Kogi ba ti ri wi pe ẹgbẹ mii fẹ fa eeyan ka lẹ lati koju òun ninu ibo lo maa n da iru eto bẹẹ ru.
Ẹwẹ, ẹgbẹ oṣelu PDP tun kilọ fun Gomina Yahaya Bello ati ẹgbẹ APC pe iwa jagidijagan ko le gba wọn ninu idibo gomina to n bọ ninu oṣu kọkanla.
Ọlọgbọndiyan ninu atẹjade to fi sita lorukọ ẹgbẹ PDP sọ pe mimi kan ko le mi ẹgbẹ naa ohun to wu ki ẹgbẹ APC ṣe.












