Muhammadu Buhari: Iléẹjọ́ tó ga jùlọ bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ayédèrú sabuké Buhari

Muhammadu Buhari

Oríṣun àwòrán, Twitter/Presidency

Àkọlé àwòrán, Muhammadu Buhari: Iléẹjọ́ tó ga jùlọ bẹ̀rẹ̀ ìgbẹ́jọ́ ẹ̀sùn ayédèrú sabuké Buhari

Lẹyin ti wọn ti lọ ilẹ ẹjọ giga tẹlẹ, ẹjọ Buhari n bẹrẹ nile ẹjọ giga julọ ni Naijiria.

Lonii ọjọ Aje, ọjọ keji, oṣu kẹsan an ni ileẹjọ to ga julọ ni Naijiria yoo gbẹjọ kotẹmilọrun tawọn kan pe wi pe Aarẹ Muhammadu Buhari ko koju oṣuwọn to lati dije ninu ibo aarẹ oṣu keji, ọdun 2019.

Ẹjọ naa da lori ẹsun ti wọn fi kan Buhari pe o parọ lori awọn iwe ẹri rẹ to fi ṣọwọ si ajọ eleto idibo, INEC ṣaaju idibo gbogboogbo to lọ.

Ọgbẹni Kalu Kalu Agu, Labaran Ismail ati Hassy Jyari El-Kunis lo gbẹjọ naa lọ siwaju ileẹjọ to ga julọ, lẹyin ti ileẹjọ kotẹmilọrun fi ontẹ lu bi Buhari ti jawe olubori ninu idibo aarẹ ọjọ kẹtalelogun, oṣu keji.

Oludije fun ipo aarẹ fẹgbẹ oṣelu PDP, Alhaji Atiku Abubakar naa sọrọ nipa iwe ẹri Aarẹ Buhari ninu ẹsun to fi kan an niwaju igbimọ igbẹjọ to n ri si awuyewuye lori eto idibo gbogboogbo ọdun 2019.

Ṣugbọn awọn eeyan mẹta yii ti gbe Buhari lọ si ileẹjọ giga l'Abuja lati ọdun 2018 ninu eyi ti wọn ti sọ pe aarẹ Buhari ko ni awọn sabuke to sọ fun ajọ INEC pe oun ni.

Amọ, Adajọ Ahmed Mohammed ti ile ẹjọ giga l'Abuja tu ẹjọ naa ka lọjọ keji, oṣu karun un, ọdun 2019 lẹyin to sọ pe ko lẹsẹ nlẹ.

Igbimọ ile ẹjọ kotẹmilọrun ti adajọ Tinuade Akomolafe-Wilson dari wọn naa tu ẹjọ kotẹmilọrun ti wọn pe ka lọjọ kejila, oṣu keje.

Lọjọ kẹrinlelogun, oṣu keje ni agbẹjọro awọn mẹta to pe Buhari ọhun, Ukpai Ukairo gbe ọrọ naa lọ siwaju ile ẹjọ to ga julọ.

Àkọlé fídíò, VAT: Kò sí àǹfàní kankan tí ìjọba ti ṣe fún mi sẹ́yìn