Lagos State: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní irọ́ ni àjọ EIU ń pa pé ìlú Eko ló léwu jùlọ láti gbé lágbàáyé

Ilu Eko
Àkọlé àwòrán, Lagos State: Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ní irọ́ ni àjọ EIU ń pa pé ìlú Eko ló léwu jùlọ láti gbé lágbàáyé

Ilu Eko kọ lo lewu julọ lati gbe lagbaye, koda ilu Eko wa lara awọn ilu ti eeyan le gbe pẹlu ifọkanbalẹ nilẹ Afirika.

Kọmiṣọna fun eto iroyin, Gbenga Omotosho ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku ṣapejuwe iroyin kan ninu eyi ti ajọ Economist Intelligence Unit (EIU) fi lede pe ilu Eko lo lewu julọ lati gbe lagbaye gẹgẹ bi aimọkan.

Ajọ naa ṣe agbeyẹwo ọgọta ilu lagbaye pẹlu lilo odiwọn ti wọn pe ni Safe Cities Index lori ọrọ eto aabo, ilera ati ohun amayedẹrun.

Kọmiṣọna Omotosho ṣalaye pe iwa ọdaran ti dinku nipinlẹ Eko lati igba ti ijọba ti da ajọ pataki kan silẹ.

O ni ajọ eleto aabo Lagos State Security Trust Fund (LSSTF), to n ri si eto aabo ẹmi ati dukia awọn eniyan nipinlẹ Eko yii n ṣiṣẹ bo ti yẹ.

Ọgbẹni Omotosho ni idi ni yii tawọn oludokowo ati awọn arinrinajo fi n ṣafẹri ilu Eko.

Kọmiṣọna fikun ọrọ rẹ pe ''ilu Eko jẹ ilu kan tawọn alejo fẹran lati maa wa nitori awọn eti okun to rẹwa atawọn oriṣiiriṣii iṣẹ to wa l'Eko.''

Bakan naa lo sọ pe ibugbe idokowo nla l'Eko jẹ fawọn gbajugbaja oniṣowo papaa julọ pẹlu ọpọ eeyan to n gbe niluu Eko.

Ọgbẹni Omotosho ni ti ilu Eko ba jẹ ilu to lewu julọ lati gbe lootọ, awọn eeyan bi aarẹ ilẹ Faranse, Emmanuel Macron ati abẹṣẹ-ku-ojo Anthony kò ba tíi ṣe abẹwo wa silu Eko laipẹ.

Eko Aromisa lẹgbẹlẹgbẹ, Eko Akete, Eko ilu ọgbọn jẹ diẹ lara oriki ilu Eko.

Àkọlé fídíò, VAT: Kò sí àǹfàní kankan tí ìjọba ti ṣe fún mi sẹ́yìn