Texas Shootings: Wọ́n ti pa ẹni to yìnbọn pa àwọn ará Texas márùn ún -ọlọ́pàá

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ẹni marun un lo ti jẹ Olọrun nipe ninu iṣẹlẹ naa bayii - ọlọpaa.
Iṣẹlẹ awọn agbebọn ti wọn a kan deede maa pa awọn ero lorilẹ-ede Amerika ti n gba ẹbọ bayiiẸ̀sùn apànìyàn ni wọ́n fi kan Robert Bowers'.
Okunrin kan ni wọn ni o n wa mọto rẹ lọ lati agbegbe Midland si Odessa ni ipinlẹ Texas ni orilẹ-ede Amerika.
Lo ba deede yinbọn pa agbofinro to kọkọ da ọkọ rẹ duro ko too tun kọju ibọn sawọn ero atawọn awakọ nibẹ.
Iroyin ni kete to yinbọn fawọn ero tan lo fi ọkọ ara rẹ silẹ to ji ọkọ awọn to n gbe lẹta tó si salọ.
Nigba to maa fi de Cinema Complex lo ko oni tiẹ nigba ti ọlọpaa miran gbebọn fun un.
Titi di isinyi, ko si ẹni to mọ idi to fi yinbọn pa ọlọpaa to da ọkọ rẹ duro ati awọn ero to wa nibẹ.
O le ni eniyan mọkanlelogun ti wọn farapa ninu iṣẹlẹ buruku naa ti ọlọpaa mẹta ṣi wa lara wọn.

Oríṣun àwòrán, Google
Awọn ọlọpaa ni gbogbo wọn kọ ni ibọn ba lara tori gilaasi mọto lo ṣe awọn miran leṣe nibẹ.
Okunrin naa ni awọn agbofinro ṣapejuwe ni oyinbo alawọ funfun ti ọjọ ori rẹ wa laarin ọgbọn si ogoji.
Ileewosan Odessa Medical Center ti wọn ko ninu wọn lọ ni awọn meje ni ti wọn le ju ti wọn n du ẹmi wọn nigba ti ọmọ kekere ọdun meji kan wa lara wọn.
Awọn agbofinro ni nkan bii agogo 15:00 ti Texas ni iṣẹlẹ yii bẹrẹ nigba ti awọn ọlọpaa ẹṣọ aabo oju popo meji da ọkọ ọkunrin naa duro ni marosẹ Midland.

Oríṣun àwòrán, AFP
wọn ni bi wọn ṣe daa duro lo ṣina bolẹ fun wọn ko to salọ to si n yinbọn si gbogbo ọkọ to n pade lọ.
Ken Praxton to jẹ adajọ agba fun Texas sọ ninu atẹjade to fi sita pe o bani ninujẹ lati ri iru iṣẹlẹ bayii.
Gomina Greg Abbott to n tukọ ipinlẹ Texas ni: A ko ni faaye gba awọn ẹlẹtanu ati oni ikorira ni Lone Star State ti a wa yii, irẹpọ ati iṣọkan ni a maa fi bori iṣẹlẹ yii ni Texas.
Aarẹ ilẹ Amerika, Donald Trump ti fi sita loju opo twitter rẹ pe gbogob nkan to n ṣẹlẹ ni wọn fi n to oun leti bo ṣe n lọ ni Texas.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Lẹyin eyi ni igbakeji aarẹ Trump, Mike Pence ni: ijọba Trump ṣetan lati ṣiṣẹ papọ pẹlu awọn agbaagba ẹgbé mejeeji nile igbimọ aṣofin lati gbe igbesẹ to yẹ lati wa ojutuu si iṣoro aṣiyin ibọn to n koju orilẹ-ede wa.












