Canada yóò bẹ̀rẹ̀ àyẹ̀wò f'áwọn ọmọ Nàìjíríà tó fẹ́ wọ Amẹrika

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Canada ti n ṣiṣẹ pọ pẹlu orilẹ ede Amẹrika bayi, lati dẹkun iye awọm ọmọ Naijiria to n sa wọ Canada nigba ti wọn ba ti de Amerika, The Canada Press lo sọ bẹ .
A gbọ pe lati ibẹrẹ ọdun yii, awọn ọmọ Naijiria ti o gba iwe irinna lọ si Amerika laipẹ yii lo pọ ju ninu awọn ti o n sa wọ Canada.
Hursh Jaswal ti o jẹ agbẹnusọ fun minisita to wa fun iwọle-wọde ni Canada, Ahmed Hussen ni, "Iru awọn wọnyi, bi wọn ba ṣe de orilẹ ede Amerika, ti wọn duro diẹ bayi ni wọn ma maa sabọ si Canada.
Idi ni yi ti Canada ṣe n ṣiṣẹ pọ pẹlu Amerika lori ọrọ yii, lati fi opin si bi awọn ọmọ Naijiria ṣe n fi iwe irinna Amerika wọn wọ Canada."

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Wọn ni awọn yoo maa wo awọn ti o ba fẹ gba iwe irinna Amerika fínífíní lati mọ boya iru eniyan ti o le fẹ sa wọ Canada ni wọn.








