Wọ́n yìn'bọn lu mínísítà abẹ́lé ni Pakistan

Oríṣun àwòrán, Reuters
Agbébọn kan ni a gbọ pe o ti yan'bọn lu Minisista fun ọrọ abẹle ni Pakistan Ahsan Iqbal nigba ti o wa ni agbegbe rẹ ni ilu Narowal.
Iroyin fi to wa l'eti wipe Iqbal ṣẹṣẹ kuro ni ibi ipejọ kan ni Punjab ni agbebọn naa ṣe akọlu sii ti o si yin n'ibọn ni apa. Oju ẹsẹ ni wọn gbe lọ ile iwosan nibi ti o ti n gba itọju bayi lẹyin ti wọn ṣe iṣẹ abẹ fun.
Awọn ọlọpaa ni ẹsẹkẹsẹ ni awọn mu agbebọn naa ti o jẹ ẹni ogun ọdun le diẹ lati fi ọrọ waa lẹnu wo.
Iqbal ni o jẹ ọkan gbòógi ninu Pakistan Muslim League (Nawaz) ti o n ṣ'elu ni orilẹede naa.
Orilẹede Pakistan, Shahid Khaqan Abbasi ti bẹnu atẹ lu akọlu naa.








