Commonwealth: Ànfàní wo ni Nàìjíríà rí?

Oríṣun àwòrán, Twitter/Nigerian Presidency
Laipẹ yii ni ilẹ Gẹẹsi gba alejo awọn olori ajọ commonwealth ninu ipade kan to waye ni London.
Ọpọ ijiroro waye nibi ipade naa.
Sugbọn oun ti awọn ọmọ Naijiria n bere ni anfaani to mu wa.
Ẹ jẹ ki a se agbeyẹwo diẹ lara anfani to mu wa fun orileede Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Twitter /Nigerian Presidency
Ikunpa fun ọrọ aje laarin Naijiriaati ilẹ Gẹẹsi
Awọn onimọ nipa eto ọrọ aje ti tẹnumo pataki ṣiṣe ikunpa fun ọrọ aje laarin Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi.
Nibi ipade Commonwealth to pari laipẹ yii, anfani idokowo ogoje miliọnu poun jẹ yọ fun Naijiria ati orilẹede Pakistan.
Saaju àsìkò yii ni awọn ile iṣẹ ilẹ Gẹẹsi ti dokowo biliọnu marun poun sí Naijiria ti idokowo laarin Naijiria ati ilẹ Gẹẹsi lọdọọdun si le ni biliọnu mẹta poun.

Oríṣun àwòrán, Twitter/ FMPRng
Nibi ipade naa, ile iṣẹ Royal Dutch Shell ati aarẹ Buhari se ipade eleyii to bi ikede idokowo biliọnu mẹẹdogun dollar ni Naijiria.
Ipenija aarun iba
Ipade Commonwealth naa tun mu anfani ijiroro ati ijẹjẹ ọwọ iranwo lati koju aarun iba nilẹ Afrika.

Oríṣun àwòrán, TWITTER/NIGERIAN PRESIDENCY
Bill Gates to je eni to lowo ju lagbaye kesi awọn olori orilẹede Commonwealth lati fi kun iye owo ti won ya soto lati koju aarun iba.
Anfaani nla ni ẹjẹ owo biliọnu meji poun naa jẹ́ ti awọn olori orilẹede fun Naijiria, ọkan lara awọn orilẹede ti o n koju ipenija aarun iba.
Pẹ̀lu gbogbo anfani wọ̀nyii, o si ni awọn kan paapa julọ ninu ẹgbẹ alatako to ni awọn ko ri anfaani kankan ninu irinajo Buhari lọ si ipade naa.












