Ìpàdé Commonwealth; Ọbabìnrin fẹ́ kí àrẹ̀mọ rẹ̀ gba àsẹ

Aworan awọn adari ajọ Commonwealth

Oríṣun àwòrán, EPA

Àkọlé àwòrán, Awọn adari mẹtalelaadorin naa parapọ si Aafin Burkingham lati jiroro

Ọbabìnrin Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ti késí awọn adarí àjọ Commonwealth lati yan ọmọ oun, Ọbakunrin Charles lati jẹ oye adari lẹhin oun.

Ọbabinrin Elizabeth sọ ero ọkan rẹ ọ̀hún ni ilu London, nigba to n ṣi ipade àwọn adari orilẹede to wa l'ajọ Commonwealth.

Awọn adari mẹtalelaadorin naa parapọ si ààfin Burkingham lati leè jiroro lori ẹni ti yoo di ipo adari ajọ Commonwealth mú lẹyin Ọbabinrin Elizabeth ni ọjọ Ẹti.

Amin iyasọtọ kan

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Amin iyasọtọ kan

Amọ, ipò adari naa kii ṣe oye idile ti wọn ma n gbe fun ẹni ti oye idile kan, iyẹn Ọmọọba Ilẹ Wales, lẹyin iku Ọbabinrin naa.